2017
Wíwá Krístì ní Kérésìmesì
December 2017


Ọ̀rọ̀ Àjọ Kínní Oṣù Kejìlá 2017

Wíwá Krístì ní Kérésìmesì

Sí gbogbo ẹni tí ó nfẹ láti ní òye ẹni tí a jẹ́ bií ọmọ íjọ Jésù Krísti ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ-Ikẹhìn, mo fẹ́ fún yín ní àmì ìbẹ̀rẹ̀ tí ó ní ìtumọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta wọ̀nyí: A nwá Krístì.

À nwá láti kọ́ nípa Rẹ̀. Láti tèlé E. Láti dàbíi Tirẹ̀ síi.

Ojoojúmọ́ jákèjádò ọdún, à nwá A. Ṣùgbọ́n ní pàtàkì ní àsìkò ọdún Kérésìmesì—yí, nígbàtí a nṣe ayẹyẹ ìbí àyànfẹ́ Olùgbàlà wa—ọkàn wa nfà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ síi títíláé.

Bíi apákan ìmúrasílẹ̀ wa fún ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì, ẹ jẹ́ kí a gbèrò bí àwọn wọnnì tí wọ́n gbé ní mìllẹ́níà méjì sẹ́hìn ti múrasílẹ̀ láti tẹ́wọ́gba dídé Olùgbàlà.

Àwọn Olùṣọ́-àgùtàn

A kò mọ púpọ̀ nípa àwọn olùṣọ́-àgùtàn, kìkì pé wọ́n “ngbé nínú pápá, wọ́n nṣọ́ agbo àgùtàn wọn ní alẹ́.”1 Àwọn olùṣọ́-àgùtàn ju àwọn ènìyàn kan lásán lọ, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí yíyẹ fún ìyẹ́sí tí wọ́n nṣe iṣẹ́ owó ojúmọ́ wọn.

Wọ́n lè ṣe aṣojú àwọn ẹni ti, ní ìgbà kan, wọ́n lè má tilẹ̀ jẹ́ aláápọn ní wíwá Krístì, ṣùgbọ́n tí ọkàn wọn yípadà nígbàtí àwọn ọ̀run ṣí tí a sì kéde Krístì sí wọn.

Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹni ti, lẹ́hìn tí wọ́n ti gbọ́ ohun ti àwọn ìránṣẹ́ ọ̀run, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n lọ sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù ní fífẹ́ lati ríi.2

Àwọn Ọlọ́gbọ́n Ọkùnrin

Àwọn Ọlọ́gbọ́n Ọkùnrin jẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ti ṣe àṣàrò nípa bíbọ̀ Mèssíàh, Ọmọ Ọlọ́run. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkọ́ wọn, wọ́n dá àwọn àmì tí ó tọ́ka sí ìbí Rẹ̀ mọ̀. Nígbàtí wọ́n dá wọn mọ̀, wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀ wọ́n sì rin ìrìnàjò lọ sí Jérúsálẹ́mù, wọ́n nbèèrè, “Níbo ni ẹni tí a bí wà Ọba àwọn Júù?”3

Ìmọ̀ wọn nípa Krístì kò dúró sórí ẹ̀kọ́ nìkan. Nígbàtí wọ́n ti rí àwọn àmì ìbí Rẹ̀, wọ́n gbé ìgbésẹ̀. Wọ́n jáde láti wá Krístì.

Àwọn ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà lè dúró fún àwọn wọnnì tí wọ́n nwa Krístì nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti ṣíṣe àṣàrò ẹ̀kọ́. Ìfọkànsìn wọn sí òtítọ́ ní ìkẹhìn ndarí wọn láti wáKrístì kí wọ́n sì sìn Ín gẹ́gẹ́bí Ọba àwọn Ọba, Olùgbàlà aráyé.4

Simeon àti Anna

Simeon àti Anna lè dúró fún àwọn wọnnì tí wọ́n nwá Krístì nípasẹ̀ Ẹ̀mí. Àwọn ẹ̀mí ìyanu wọ̀nyí fi ìfọkànsìn ṣe ẹ̀sìn àti pé, nípasẹ̀ àwẹ̀ àti àdúrà àti nípa dídarí ìgbé ayé ìfọkànsìn àti ìgbọràn, wọ́n dúró pẹ̀lú ìtara láti rí ọjọ́ bíbọ́ Ọmọ Ọlọ́run.

Nípasẹ̀ ìṣòtítọ́, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìgbàgbọ́, wọ́n nfi sùúrù wo bíbọ́ Olùgbàlà.

Níkẹhìn, òdodo wọn ní èrè bí Màríà àti Jósẹ́fù ṣe gbé ọmọ ọwọ́ náà fún wọn ẹnití yíò gbé ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lé orí ara Rẹ̀ ní ọjọ́ kan.5

Àwọn onígbàgbọ́ ní àárín àwọn ará Nífáì àti Lámánì

Ìtàn tí ó wọni lọ́kàn nípa bí àwọn onígbàgbọ́ ní Ayé Titun ti nwo fún àwọn àmì ìbí Olùgbàlà tí a rí nínú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì.

Ẹ rántí pé àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì ni wọ́n tàbùkù tí wọ́n sì ṣe inúnibini si. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ọjọ́ náà fi ẹ̀sùn kan àwọn onígbàgbọ́ nípa rírọ̀mọ́ àwọn ìsìn èké òmùgọ̀. Ní tóótọ́, àwọn aláìgbàgbọ́ gbé ohùn sókè gidi nínú ṣíṣe ẹlẹ́yà wọn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fa “ìrúkèrúdò nlá” ní ilẹ̀ náà(3 Nephi 1:7) Wọ́n kẹ́gàn àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ pé a ó bí Olùgbàlà.

Ìbínú àti ìrunú wọn pọ̀ dé bi pé wọ́n fé kí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Olùgbàlà ó wà ní ìdákẹ́rọ́rọ́ lẹ́ẹ̀kannáà. Ìwé ti Mọ́rmọ́nì kọ àkọsílẹ̀ ìpinnu kíákíá náà.6

Àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n gbé ní àsìkò yí le dúró fún àwọn wọnnì tí wọ́n nwá Krísti àní nígbàtí àwọn ẹlòmíràn nrẹrin, nkẹgàn, tí wọ́n sì nṣe ẹ̀sín. Wọ́n nwá Krístì àní nígbàtí àwọn míràn ngbìyànjú láti fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà bí aláìdáa, aláìgbọ́fáàrí, tàbí òmùgọ̀.

Ṣùgbọ́n àìkàsí àwọn ẹlòmíràn kò lé mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn onígbàgbọ́ tòótọ́ ní wíwá Krístì.

A Nwá Krístì

Jákèjádò ọdún, àti boyá nípàtàkì ní àsìkò Kérésìmesì yí, yíó jẹ́ èrè fúnwa láti bèèrè ìbéèrè náà lẹ́ẹ̀kan si “Báwo ni èmi ṣe nwá Krístì?”

Ní àsikò líle kan ní ìgbé ayé rẹ̀, Dáfídì Ọbá nlá kọ pé, “Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi; ní kùtùkùtù ni èmi ó ma wá ọ: òùngbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran ara mi nfà sí ọ.”7

Bóyá ìwà wíwá Ọlọ́run yí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èrèdí tí wọ́n fi ṣe àpèjúwe Dáfídì gẹ́gẹ́bí ẹni bí ọkàn Ọlọ́run.8

Ní ìgbà Kérésìmesì yìi àti ní jákèjádò gbogbo inú ọdún, njẹ́ kí a lè wá Olùgbàlà wa ọ̀wọ́n pẹ̀lú ọkàn wa àti ẹ̀mí wa, Ọba Àláfíà, Ẹni Mímọ́ Ísáẹ́lì. Nítorí ìfẹ́ yí, nínú èyí tí ó jùlọ, ṣe àpèjúwe, kìi ṣe ẹni tí a jẹ́ bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn nìkan, ṣùgbọ́n àní síwájú síi ẹni tí a jẹ́ ní tòótọ́ gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́hìn Krístì.