2021
Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì
Oṣù Kárún 2021


“Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì,” Fún Òkún àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù karun 2021.

Abala Àárọ̀ Sátidé

Mo Fẹ́ láti Rí Tẹ́mpìlì

Àwọn àyọsọ

Àwòrán
tẹ́mpìlì

Mo mọ̀ pé àwọn tẹ́mpìlì Olúwa jẹ́ ibi mímọ́. Èrèdí mi loni ní sísọ̀rọ̀ nípa àwọn tẹ́mpìlì ni láti mú ìfẹ́ yín àti ti tèmi pọ̀ si láti jẹ́ yíyẹ kí a sì ṣetán fún àwọn àlékún ànfàní fún àwọn ìrírí tẹ́mpìlì tí ó n bọwá fún wa. …

Bí ẹ̀yin tàbí èmi bá lọ sí tẹ́mpìlì tí kò mọ́ tó, a kò ní lè ri, nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́, ìkọ́ni ti-ẹ̀mí nípa Olùgbàlà tí a lè gbà nínú tẹ́mpìlì.

Nígbàtí a bá yẹ láti gba irú ìkọ́ni bẹ́ẹ̀, níbẹ̀ ni ìdàgbà nípasẹ̀ ìrírí ìrètí, ayọ̀, àti ìgbàgbọ́ fún rere tẹ́mpìlì wa ní gbogbo ìgbé ayé wa. Ìrètí, ayọ̀, àti ìgbàgbọ́ fún rere náà wà nìkan nípasẹ̀ ìtẹ́wọ́gbà àwọn ìlànà tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì mímọ́. Inú tẹ́mpìlì ni a ti lè gba ìdánilójú àwọn ìsopọ̀ ìfẹ́ni ẹbí tí yíò tẹ̀síwájú lẹ́hìn ikú àti títí di àìlópin. …

… A sì mọ̀ pé ìdùnnú ayérayé wa dá lórí ṣíṣe dáradára wa jùlọ láti ní irú ìdùnnú pípẹ́ kannáà sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbátàn wa bí a ti lè ṣe.

Mo ní ìmọ̀lára irú ìfẹ́ kannáà láti yege ní pípe àwọn ọmọ ẹbí láti nifẹ láti di yíyẹ láti gbà àti láti bu-ọlá fún àwọn ìlànà èdidì ti tẹ́mpìlì. Ìyẹn ni ara ìlérí ìkórajọ Ísráẹ́lì ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ méjì ìbòjú.

Àwòrán
Àtunṣe Tẹ́mpìlì Salt Lake