2022
Àwọn Ìlérí Ezekiel Wá Sí Ìmúṣẹ
Oṣù Kẹ́wàá (Ọ̀wàwà) 2022


“Àwọn Ìlérí Ezekiel Wá Sí Ìmúṣẹ,” Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹwa 2022

“Àwọn Ìlérí Ezekiel Wá Sí Ìmúṣẹ”

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹwa 2022

Àwọn Ìlérí Ezekiel Wá Sí Ìmúṣẹ

Àwòrán
Ezekiel nkọ̀wé

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ezekiel jẹ́ wòlíì kan. Ọlọ́run fi àwọn ohun pùpọ̀ ọjọ́ ọ̀la hàn án tí kò tíì ṣẹlẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀. Ezekiel kọ wọ́n sílẹ̀.

Àwòrán
Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Ezekiel kọ̀wé nípa àwọn ìwé méjì tí á ó tẹ̀jáde nì ọjọ́-kan. Ìwé kan ni Bíbélì. Ìwé míràn ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Àwòrán
Títẹ Bíbélì jáde ní orí ilé-iṣẹ́ àtẹ̀jáde àkọ́kọ́

Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́hìnnáà, Bíbélì di títẹ̀ jáde.

Àwòrán
Joseph Smith nṣe ìyírọ̀padà Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú Emma gẹ́gẹ́bí akọ̀wé

Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún si, Joseph Smith ṣe ìyírọ̀padà Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìran Ezekiel Wá Sí Ìmúṣẹ!

Àwòrán
Jésù Krístì

Ní òní a lè ka Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Wọ́n nṣiṣẹ́ papọ̀ láti kọ́ni nípa Jésù Krístì.

Àwòrán
ẹbí nka àwọn Ìwé-mímọ́

Nígbàtí mo bá ka àwọn ìwé mímọ́, èmi nkọ́ nípa Jésù Krístì.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo Lè Ka àwọn Ìwe-mímọ́

Àwòrán
Àwọn ọmọdé àti àwọn olùkọ́ nínú Alakọbẹrẹ

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ìtàn ìwé-mímọ́ wo ni ẹ fẹ́ràn jùlọ?