2023
Àwọn Ìbùkún Oyèàlùfáà
Oṣù Kẹ́ta 2023


“Àwọn Ìbùkún Oyèàlùfáà,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́ta 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣoòṣù Làìhónà , Oṣù Kẹta 2023

Àwọn Ìbùkún Oyèàlùfáà

Àwòrán
Krístì yan àwọn Àpóstélì Méjìlá

Jésù Nyan àwọn Àpóstélì Méjìlá, nípasẹ̀ Harry Anderson

Ìbùkún oyèàlùfáà ni a nfúnni nípasẹ̀ ìmísí nípa olùdìmú Oyè Àlùfáà Melkísédékì. Àwọn ìbùkún oyèàlùfáà jẹ́kí ó ṣeéṣe fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láti gba agbára, ìwòsàn, ìtùnú, àti ìtọ́nisọ́nà Rẹ̀.

Oyèàlùfáà

Oyèàlùfáà jẹ́ agbára àti àṣẹ Ọlọ́run. Àwọn ọkùnrin yíyẹ tí wọ́n di OyèÀlùfáà Melkísédékì mú nṣe ìṣe ní orúkọ Jésù Krístì nígbàtí wọ́n bá nfúnni ní àwọn ìbùkún oyèàlùfáà. Bí wọ́n ti nfúnni ní àwọn ìbùkún wọ̀nyí, wọ́n ntẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà ti bíbùkún àwọn ẹlòmíràn.

Àwòrán
àwọn ọwọ́ dùbúlẹ̀ lé òkè orí kan

Àwòrán láti ọwọ́ David Winters

Bí A Ti Nfúnni Ní Àwọn Ìbùkún

Àwọn ìbùkún oyèàlùfáà ni à nfúnni nípa gbígbé ọwọ́ lé. Olùdìmú Oyè Àlùfáà Melkísédékì kan ó gbé àwọn ọwọ́ rẹ̀ le orí ẹni tì ó ngba ìbùkún. Nígbànáà òun ó fúnni ní ìbùkún bí Ẹ̀mí ti darí. Àwọn tí wọ́n nfúnni ní àwọn ìbùkún àti àwọn tí wọ́n ngbà wọ́n nlo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ìgbẹ́kẹ̀lé nìnù ìfẹ́ àti àkokò Rẹ̀.

Ìsọmọlórúkọ àti Ìbùkún àwọn Ọmọdé

Lẹ́hìn tí a bá bí ọmọ, olùdìmú oyèàlùfáà ó fún ọkùnrin tàbí obìnrin ní orúkọ àti ìbùkún (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:70). Èyí máa nṣẹlẹ̀ nígbàkugbà nínú ìpàdé àwẹ̀ ati ẹ̀rí. A ó kọ́kọ́ fún ọmọ ní orúkọ. Lẹ́hìnnáà olùdìmú oyèàlùfáà ó fún ọmọ náà ní ìbùkún.

Àwòrán
Ọmọdékùnrin tí ó nṣàárẹ̀ ngbá ìbùkún oyèàlùfáà.

Àwòrán láti ọwọ́ Welden C. Andersen

Àwọn Ìbùkún fún Aláárẹ̀

Àwọn Olùdìmú Oyè-alùfáà Melkísédékì lè fi ìbùkún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n nṣàárẹ̀. Irú ìbùkún yí ní ọ̀nà méjì: àmì òróró pẹ̀lú òróró àti èdidì àmi òróró. Àkọ́kọ́, olùdìmú oyèàlùfáà ó tà òróró ólífì tí a ti yàsọ̀tọ̀, tàbí bùkún, lé orí ẹni náà yíò sì fun ni àdúrà kúkurú. Lẹ́hìnnáà olùdìmú oyèàlùfáà míràn ó fi èdidì àmì òróró dìí yíò sì fún ẹni náà ní ìbùkún bí ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

Àwọn Ìbùkún Ìtùnú àti Àmọ̀ràn

Àwọn olùdìmú Oyèalùfáà Melkísédékì lè fi àwọn ìbùkún ìtùnú àti àmọ̀ràn fún àwọn ọmọ-ìjọ àti àwọn ẹlẹomíràn tí wọ́n bá bèèrè fún wọn. Baba kan tí ó di Oyèalùfáà Melkísédékì mú lè fi àwọn ìbùkún ti baba fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwọ̀nyí lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ pàápàá nígbàtí àwọn ọmọ bá ndojúkọ àwọn ìpèníjà pàtàkì.

Yíyà Sọ́tọ àwọn Ọmọ Ìjọ láti Sìn nínú àwọn Ìpè

Nígbàtí àwọn ọmọ Ìjọ bá gba àwọn ìpè, a máa nfún wọn ní ìbùkún nígbàtí a bá yà wọ́n sọ́tọ̀ láti sin. Olórí oyèàlùfáà kan ó bùkún wọn pẹ̀lú àṣẹ láti ṣe ìṣe nínú ìpè náà. Bákannáà olórí oyèàlùfáà ó fún wọn ní ìbùkún láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn wọn.

Àwòrán
obìnrin nka ìbùkún ti pátríákì rẹ̀

Àwòrán nípasẹ̀ Shauna Stephenson

Àwọn Ìbùkún ti Pátríákì

Gbogbo ọmọ Ìjọ yíyẹ lè gba ìbùkún ti pátríákì. Ìbùkún yí nfúnni ní àmọ̀ràn ara-ẹni láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ó lè pèsè ìtọ́nisọ́nà àti ìtùnú ní gbogbo ayé ti ẹnìkan. Bákannáà ó nsọ ìran ẹni náà nínú ilé Ísráẹ́lì. Pátríákì tí a yàn níkan ni ó lè fúnni ní irú ìbùkún yí.