2023
Ṣíṣe àbápín Ìhinrere Jésù Krístì.
Oṣù Keje 2023


“Ṣíṣe àbápín Ìhinrere Jésù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kéje 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kéje 2023

Ṣíṣe àbápín Ìhinrere Jésù Krístì.

Àwòrán
ọ̀dọ́mọbìnrin pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ ní ṣíṣí lórí ẹsẹ̀

Nígbàtí a bá ronú nípa àwọn ìbùkún tí a gbà nítorípé a jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a nfẹ́ láti ṣe àbápín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn tí a fẹ́ràn. A lè ṣe àbápín àwọn ẹ̀rí wa nípa òtítọ́ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wa àti àpẹrẹ wa. A lè gbàdúrà fún ìmísí láti mọ ẹnití a ó ṣe àbápin pẹ̀lú àti ohun tí a ó sọ.

Àwòrán
Jésù nawọ́ jáde sí ọkùnrin aláìlera kan

Fẹ́ràn Àwọn Ẹlòmíràn

Apákan pàtàkì ti síṣe àbápín ìhìnrere ni fífẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn. Nígbàtí a bá fi ìfẹ́ wa sí àwọn ẹlòmíràn hàn nípasẹ̀ àwọn ìṣe bíi ti Krístì, à nṣe àbápín ìhìnrere ti Jésù Krístì—nígbàmíràn láì sọ ọ̀rọ̀ kan. Nígbàtí àwọn míràn bá sì mọ pé a nṣe àníyàn nípa wọn ní tòótọ́, wọ́n lè ní ìfaramọ́ sí gbígbọ́ àwọn èrò wa síi nípa ìhìnrere. (Wo Gary E. Stevenson, “Fẹ́ràn, Ṣe Àbápín, Pè,” Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 84–87.)

Ṣe Àbápín ní àwọn Ọ̀nà Déédé àti Àdánidá

A lè ṣe àbápín ohun tí a fẹ́ràn nípa ìhìnrere. Nígbàtí a bá ṣe èyí bí ara àwọn ìgbé ayé wa ojojúmọ́, kò ní lòdì tàbí jẹ́ àìrọrùn. Fún ápẹrẹ, a lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ wa nípa ohun tí à nṣe ní Ọjọ́-ìsinmi. Tàbí a lè sọ fún wọn nípa ìdùnnú tí a nmọ̀lára nígbàtí a bá sin àwọn ẹlòmíràn. (Wo Dieter F. Uchtdorf, “Íṣẹ́ Ìránṣẹ́-ìhìnrere: Ṣíṣe àbápín Ohun Tí Ó Wà Lọ́kàn Yín,” Làìhónà,, Oṣù Karun, 2019, 15–18.

Ẹ Pe Àwọn Ẹlòmíràn láti Darapọ̀ mọ́ Wa

A lè pe àwọn ẹlòmíràn láti kẹkọ síi nípa ìhìnrere. Fún àpẹrẹ, a lè pè wọ́n láti wá sí ìpàdé Ìjọ tàbí ìṣe ìdárayá kan, ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, wo fídíò Ìjọ kan, tàbí ṣe ìbẹ̀wò pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ̀-ìhìnrere. Àwọn ìrírí wọ̀nyí lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí kí wọ́n sì fẹ́ láti kọ́ ẹkọ síi.

Àwòrán
àwọn obìnrin agbà méjì jókó wọ́n sì nsọ̀rọ̀

Bèèrè nípa Ìrírí Wọn

Lẹ́hìn tí àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí bá ti wá sí ilé-ìjọsìn tàbí ní ẹ̀kọ́ kan pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere, a lè bèèrè lọ́wọ́ wọn nípa ìrírí wọn. Àwọn ìkọ́ni ìhìnrere díẹ̀ lè jẹ́ titun sí wọn, nítorínáà a lè dáhùn àwọn ìbèèrè tí wọ́n bá ní. A lè fi ìfẹ́ àti àtìlẹhìn wa hàn fún àwọn ìtiraka wọn láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì.

Fi Kún àwọn Ìgbàgbọ́ Wọn

A nmọ rírí a sì nfi ọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ ti àwọn ẹlòmíràn, a sì ngbìyànjú láti fi kún ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀. Fún àpẹrẹ, ọ̀rẹ́ kan tí ó ti rí ìtùnú nínú àwọn ìwé-mímọ́ Bíbélì lè rí ìtùnú bákannáà nínú àwọn ìkọ́ni tí a ṣe àbápín láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Àwòrán
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin nran obìnrin àgbà kan lọ́wọ́ láti sọdá òpópónà kan.

Ran Àwọn Ọmọ Ìjọ Titun Lọ́wọ́

Nígbàtí àwọn ènìyàn bá darapọ̀ mọ́ Ìjọ, a lè ṣèránwọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. A lè jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn, dáhùn àwọn ìbèèrè wọn, àti kí a tì wọ́n lẹhìn nígbàtí wọ́n bá gba àwọn ìpè. A lè gbà wọ́n níyànjú láti tẹ̀síwájú ní títẹ̀lé Jésù Krístì àti kíkọ́ nípa ìhìnrere Rẹ̀.

Àwòrán
àwọn alàgbà ìránṣẹ́-ìhìnrere méjì àti ọkùnrin kan jọ nwo fóònù kan papọ̀

Sin Míṣọ̀n Ìgbà-Kíkún kan

Ní àfikún sí síṣe àbápín ìhìnrere nínú àwọn ìgbé ayé wa ojojúmọ, àwọn ọmọ Ìjọ ni a lè pè láti sìn bí àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere ìgbà-kíkún. Bí wọ́n bá múrasílẹ̀, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lè tètè sìn ní bí ẹni ọjọ́ orí ọdún méjìdínlógún. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin àti àwọn àgbà àgbàlagbà bákannáà lè sìn. Ẹ lè rí àlàyé si ní ChurchofJesusChrist.org/callings/missionary.