Àwọn Ìlànà àti àwọn Ìkéde
Ìkéde Ẹbí Náà


Ẹbí

Ìkéde Kan sí Àgbáyé

Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Ìgbìmọ̀ Àwọn Àpóstélì Méjìlá ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

Àwa, Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Ìgbìmọ̀ Àwọn Àpóstélì Méjìlá ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kéde pé ìgbéyàwó láàrin ọkùnrin kan àti obìnrin kan jẹ́ yíyàn láti ọwọ́ Ọlọ́run àti pé ẹbí jẹ́ àringbùngbun sí ètò Ẹlẹ́da fún àyànmọ́ ayérayé ti àwọn ọmọ Rẹ̀.

Gbogbo àwọn ènìyàn—ọkùnrin àti obìnrin—ni a dá ní àwòrán Ọlọ́run. Ẹnìkọ̀ọ̀kan jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ ẹ̀mí lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti àwọn òbí ọ̀run, àti pé, nípa bẹ́ẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní àdánidá àti àyànmọ́ àtọ̀runwá. Ẹ̀yà lákọ-lábo jẹ́ kókó ìṣesí ìdánimọ̀ àti èredi ti olukúlùkù ṣaájú ayé-íkú, ní ayé-ikú, àti ní ayérayé.

Nínú ìjọba ṣaájú ayé-ikú, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí mọ̀, wọ́n sì sìn Ọlọ́run bíi Baba wọn Ayérayé, àti pé wọ́n gba ètò Rẹ̀ nípa èyítí àwọn ọmọ Rẹ̀ le gba àgọ́ ti-ara kí wọn ó sì jèrè ìrírí ayé láti tẹ̀síwájú ní jíjẹ́ pípé àti ní ìgbẹ̀hìn kí wọn ó le mọ àyànmọ́ àtọ̀runwá wọn bíi àwọn ajogún iyè ayérayé. Ètò ìdùnnú ti àtọ̀runwá nfún àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí ní agbára láti tẹ̀síwájú kọjá ibojì. Àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n wà nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ mú kí ó ṣeéṣe fún olukúlùkù láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti fún àwọn ẹbí láti wà ní sísọdọ̀kan titi ayérayé.

Òfin ìkínní tí Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà dá lórí agbára wọn láti jẹ́ òbí bíi ọkọ àti aya. A kéde pé òfin Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ láti bí síi kí wọn ó sì gbilẹ̀ ayé ṣì wà ní lílò. A kéde síwájú síi pé Ọlọ́run ti pàṣẹ pé àwọn agbára mímọ́ ti ìṣẹ̀dá ni a gbọdọ̀ mú siṣẹ́ láàrin ọkùnrin àti obìnrin nìkan, tí a ṣe ìgbeyàwó fún pẹ̀lú òfin bíi ọkọ àti aya.

A kéde ọ̀nà nípa èyítí a ṣe ẹ̀dá ayé-íkú pé ó jẹ́ yíyàn látọ̀runwá. A tẹnumọ́ jíjẹ́ mímọ́ ẹ̀mí àti ti síṣe pàtàkì rẹ̀ nínú ètò ayérayé ti Ọlọ́run.

Ọkọ àti aya ní ojúṣe ọ̀wọ̀ kan láti fẹ́ràn kí wọn ó sì ṣe ìtọ́jú fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. “Àwọn ọmọ ni ìní Olúwa” (Orin Dafidi 127:3). Àwọn òbí ní ojúṣe mímọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ìfẹ́ àti òdodo, láti pèsè fún àwọn àìní wọn ní ti-ara àti ti-ẹ̀mí, àti láti kọ́ wọn láti nifẹ àti láti sin ara wọn, láti kíyèsí àwọn òfin Ọlọ́run, kí wọn ó sì jẹ́ ará ìlú olùpa-òfin-mọ́ ní ibikíbi tí wọ́n bá ngbé. Àwọn ọkọ àti àwọn aya—àwọn ìyá àti àwọn baba—ni a ó mú jíhìn níwájú Ọlọ́run fún síṣe àwọn ojúṣe wọ̀nyí.

Ẹbí jẹ́ yíyàn láti ọwọ́ Ọlọ́run. Ìgbéyàwó láàrin ọkùnrin àti obìnrin ṣe pàtàkì sí ètò ayérayé Rẹ̀. Àwọn ọmọ ní ẹ̀tọ́ sí ìbí nínú àwọn àsopọ̀ ìgbéyàwó, àti láti jẹ́ títọ́jú nípasẹ̀ baba kan àti ìyá kan àwọn ẹnití wọ́n bú ọlá fún àwọn ìbúra ìgbéyàwó pẹ̀lú ìfọkàntán pátápátá. Ìdùnnú nínú ìgbé ayé ẹbí ṣeéṣe jùlọ láti ṣe àṣeyọrí rẹ̀ nígbàtí a bá fi lélẹ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ ti Olúwa Jésù Krístì. Àwọn ìgbéyàwó àti àwọn ẹbí tí ó yege ní a gbékalẹ̀ tí a sì múdúró lóri àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ti ìgbàgbọ́, àdúrà, ìrònúpìwàdà, ìdáríjì, ìtẹ̀ríba, ìfẹ́, àànú, iṣẹ́, àti àwọn eré ìdárayá tí ó ṣànfàní. Nípa ètò àtọ̀runwá, àwọn baba nílati ṣe àkóso lórí ẹbí wọn nínú ìfẹ́ àti òdodo àti pé wọ́n ní ojúṣe láti pèsè àwọn ohun àìgbọdọ̀-máni ní ìgbé ayé àti ààbò fún àwọn ebí wọn. Àwọn ìyá ní àkọ́bẹ̀rẹ̀ ojúṣe fún títọ́ àwọn ọmọ wọn. Nínú àwọn ojúṣe mímọ́ wọ̀nyí, ó jẹ́ dandan fún àwọn baba àti àwọn ìyá láti ran ara wọn lọ́wọ́ bíi àwọn alábaṣepọ̀ dídọ́gba. Ìpèníjà ara, ikú, tàbí àwọn ipò míràn le fa àtúndá olukúlùkù. Àwọn ẹbí ati ibátan níláti ṣe àtilẹ́hìn nígbàtí ìníló bá wà.

A kìlọ̀ pé olukúlùkù àwọn ẹnití wọ́n bá tàpá sí àwọn májẹmu ti ìpa-ara-ẹni-mọ́, ẹnití ó bá lo alábaṣepọ̀ tàbí ọmọ ní ìlòkulò, tàbí ẹnití ó kùnà láti mú àwọn ojúṣe ẹbí ṣe yío dúró ní ọjọ́ kan láti jíhìn níwájú Ọlọ́run. Síwájú síi, a kìlọ̀ pé ìtúká ẹbí yío mú àwọn ìdààmú tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní wá sí orí àwọn olúkúlùkù, àwọn àdúgbò, àti àwọn orílẹ̀ èdè.

A pe àwọn ará ilú àti àwọn òṣìṣẹ́ ti ìjọba níbigbogbo lati ṣe ìgbésókè àwọn òsùnwọ̀n wọnnì tí a ti pèrò láti ṣe ìmúdúró àti láti mú ẹbí lókun bíi kókó ẹyọ kan ní àwùjọ.