2013
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti ara rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run
April 2013


Ọ̀dọ́

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti ara rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run

Olùdarí Eyríng ti kọ́ pé bí a ṣe ńfetísílẹ̀ sí àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa, a lè ní ìmọ̀lára bíí pé à ńní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti ara kan pẹ̀lú Ọlọ́run. Olùdarí Eyring ńro ti àwọn ọ̀nà mẹ́ta tó tẹ̀lée. Gbèrò kíkọ àwọn ìbèèrè wọ̀nyí nínú ìwé ìròhìn rẹ, kí o sì ṣàṣàrò wọn ní ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan lóṣù yí. Bí o ṣe ńṣàṣàrò àti gba awọn ìtẹ̀mọ́ látọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, o lè kọ nípa ìwọ̀nyí bákannáà nínú ìwé ìròhìn rẹ.

  • Kíní mo ti ṣe tí ó ti mú inú Ọlọ́run dùn.

  • Kíni mo nílò láti ronúpìwàdà lé lórí tàbí bèèrè ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún?

  • Tani Ọlọ́run yíò fẹ́ kí nsìn.