2013
Àwọn Májẹ̀mú Tẹ́mpìlì
April 2013


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, oṣù Kẹ́rin ọdún 2013

Àwọn Májẹ̀mú

Fi tàdúràtàdúrà kọ́ ohun èlò yí àti pé, bí ó bá ṣe rẹ́gí, sọọ́ kíníkíní pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò ńbẹ̀wò. Lo àwọn ìbèèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ fún àwọn arábìnrin rẹ lókun àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá ti ayé ara rẹ tó láápọn. Fún ìwífúnni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Àwòrán
Àmì Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́

Ìgbàgbọ́, Ẹbí, Ìranilọ́wọ́

“Àwọn ìlànà ìgbàlà tí a gbà nínú tẹ́mpìlì tí ó gbà wá láàyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run níjọ́ kan nínú ìbálòpọ̀ ẹbí ayérayé àti láti gba ẹ̀bùn pẹ̀lú àwọn ìbùkún àti agbára láti òkè ti yẹ fún gbogbo ìrúbọ àti gbogbo ìgbìyànjú,”1 ni Olùdarí Thomas S. Monson sọ. Tí o kò bá tíì dé tẹ̀mpìlì síbẹ̀síbẹ̀, o lè múràsílẹ̀ láti gba àwọn ìlànà mímọ́ tẹ́mpìlì nípa:

  • Gbígbàgbọ́ nínú Bàbá Ọ̀run, Jésù Krístì, àti Ẹ̀mí Mímọ́ náà.

  • Títọ́ ẹ̀rí kan nípa ti Ètùtù ti Jésù Krístì àti ìpadàbọ̀sípò ìhìnrere náà.

  • Ìmúdúró àti títẹ̀lé wòlíì alààyè náà.

  • Yíyege fún ìwé ìkaniyẹ kan nípa sísan ìdámẹ́wá, wíwà nínú ìwà àìléérí, wíwà ní òótọ́, pípa Ọ̀rọ̀ ti Ọgbọ́n mọ́, àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ti ìjọ náà.

  • Fífúnni ní àsìkò, ẹ̀bùn, àti àwọn ààyè láti ṣèrànlọ́wọ́ kíkọ́ ìjọba ti Olúwa.

  • Kíkópa nínú iṣẹ́ ìwé ìtàn ẹbí.2

Olùdarí Monson kọ́ síwájú pé, Bí a ṣe ńrántí àwọn májẹ̀mú náà tí à ńṣe nínú [tẹ́mpìlì náà], a ó lè gba gbogbo àdánwò mọ́ra àti láti borí ìdánwò kọ̀ọ̀kan.”3

Látinú Àwọn Ìwé Mímọ́

Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 14:7; 25:13; 109:22

Látinú Ìwé Ìtàn Wa

“Àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó pọ̀ ju ẹgbẹ̀rún gbárajọ ní Tẹ́mpìlì Nauvoo lẹ́hìn ìyàsímímọ́ rẹ̀. …

“Okun náà, agbára, àti àwọn ìbùkún ti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì [ṣèmúdúró] àwọn ènìyàn mímọ́ ìgbà ìkẹhìn ní àsìkò ìrìnàjò wọn sí [ìwọ̀ oòrùn], nígbàtí wọ́n [jìyà] òtútù, ooru, ebi, òṣì, àìsàn, àwọn ìjàmbá, àti ikú.”4

Bíi ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́, Sarah Rich sìn bíi òṣìṣẹ́ tẹ́mpìlì kan. Ó sọ nípa ìrírí rẹ̀: “Tí kò bá jẹ́ fún ti ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí wọ́n fi lé wa lórí ní tẹ́mpìlì náà nípa …. Ẹ̀mí ti Olúwa, ìrìnàjò wa ìbá ti dàbí ẹnìkan tí ó ńbẹ́ nínú òkùnkùn. … Ṣùgbọ́n a ní ìgbàgbọ́ nínú Bàbá wa Ọ̀run, … níní ìmọ̀lára pé a jẹ́ ènìyàn Rẹ̀ tí a yàn … , àti pé dípò ti ìbànújẹ́, a ní ìmọ̀lára láti dunnú pé ọjọ́ ìràpadà wa ti dé.”5

Ìjádelọ náà kìí ṣe “bíbẹ́ kan nínú òkùnkùn” fún àwọn olóótọ́ obìnrin ènìyàn Mímọ́ ìgbà ìkẹhìn. Àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wọn ni ó ṣèmúdúró fún wọn.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Thomas S. Monson, “Tẹ́mpìlì Mímọ́ Náà—Ìsádí kan sí Ayé,” Liahona, May 2011, 92.

  2. Àwọn Ọmọbìnrin ní Ìjọba Mi: Ìwé Ìtàn àti Iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ (2011), 21.

  3. Thomas S. Monson, Liahona, May 2011, 93

  4. Àwọn Ọmọbìnrin ní Ìjọba Mi, 29–30

  5. Sarah Rich, ní Àwọn Ọmọbìnrin ní Ìjọba Mi 30