2013
Kíkọ́ni ní àti Kíkẹ́kọ́ ti Ìhìnrere
July 2013


Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kéje Ọdún 2013

Kíkọ́ni àti Kíkẹ́kọ́ ti Ìhìnrere

Fi àdúrà ṣàṣàrò lórí ohun yìí àti, bí ó bá ṣe bójú mu, ṣe àjọsọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò ó mbẹ̀ wò. Lo àwọn ìbéèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìfúnlókun àwọn arábìnrin rẹ àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá tí ó láapọn nínú ayé rẹ. Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ́, Ìdílé, Ìrànlọ́wọ́

Jésù Krístì jẹ́ ọ̀gá olùkọ́ni. Ó dá àpẹrẹ fún wa bí Ó ti ń “kọ́ àwọn obìnrin nínú àwọn èrò àti ní ìkọ̀ ọ̀kan, lórí títì àti lẹ́bá òkun, níbi kànga àti nínú ilé wọn. Ó fojúrere àánú hàn sí wọn àti pé Ó wo àwọn àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn sàn.”1

Ó kọ́ Martha àti Màríà àti pé Ó “pè wọ́n kí wọn di ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ kí wọ́n sì ṣalábápin ìgbàlà, ‘apá rere nì’ [Luku 10:42] tí a kì yíó gbà lọ́wọ́ wọn láe.”2

Nínú àwọn ìwé mímọ́ wa ti ọjọ́ ìkẹhìn, Olúwa pàṣẹ fún wa láti “kọ́ ara wa ní ẹ̀kọ́ ti ìjọba náà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:77). Ní kíkọ́ni àti kíkọ́ ẹ̀kọ́, Cheryl A. Esplin, olùdámọ̀ràn kejì nínú àjọ olùdarí gbogbogbòò ti Akọ́bẹ̀rẹ̀, wípé “Kíkọ́ láti ní òye kíkún nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere jẹ́ ètò ẹsẹsẹ ìgbà ayé àti pé ó nwá ní ‘ìlà lórí ìlà, ẹ̀kọ́ lórí ẹ̀kọ́, díẹ̀ níbí àti díẹ̀ lọ́hún’ (2 Nífáì 28:30).3

Bí a ṣe é nkẹ́kọ́, ṣàṣàrò, àti gbàdúrà, a ó kọ́ní pẹ̀lú agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, tí yíò gbé iṣẹ́ wa “sí àwọn ọkàn ti àwọn ọmọ ènìyàn [àti àwọn obìnrin]” (2 Nífáì 33:1).

Láti Àwọn ìwé Mímọ́

Álmà 17:2–3; 31:5; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:12–13; 84:85

Láti Ìtàn Wa

Àwọn wòlíì wa tẹ́lẹ̀ ti rán wa létí pé gẹ́gẹ́bí obìnrin a ní ojúṣe pàtàkì gẹ́gẹ́bí olùkọ́ni nínú ilé àti ìjọ. Ní Oṣù kẹ́sán ọdún 1979, Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895–1985) ní kí a di “amọ̀wé ìwé mímọ́ arábìnrin.” Ó wípé, “”Di àwọn ọ̀mọ̀wé ti àwọn ìwé mímọ́—kìí ṣe láti fa àwọn míràn sílẹ̀, ṣùgbọ́n láti gbe wọn sókè! Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, tani ó nílò jùlọ láti “tọ́jú bíi ìṣúra” àwọn òtítọ́ ìhìnrere (lórí èyí tí wọ́n lè képè ní àkókò àìní wọn) ju àwọn obìnrin àti àwọn ìyá tí ó má ń ṣe ọ̀pọ̀ ìtọ́jú àti kíkọ́ni?”4

Gbogbo wa ní olùkọ́ni àti akẹ́kọ́. Nígbà tí a bá kọ́ni láti àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alàyè wa, a lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì. Nígbà ti a bá kópá nínú ètò ẹsẹsẹ ti kíkẹ́kọ́ nípa bíbèrè àwọn ìbéèrè onítumọ̀ àti fífetísílẹ̀, nígbànáà a lè rí àwọn ìdáhùn tí ó bójúmu sí àwọn àìní ara wa.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Daughters in My Kingdom: The History and Work of Relief Society (Ọdún 2011), 3.

  2. Daughters in My Kingdom, 4.

  3. Cheryl A. Esplin, “Teaching Our Children to Understand,” Liahona àti Ensign, Oṣù Kárun Ọdún 2012, 12.

  4. Spencer W. Kimball, in Daughters in My Kingdom, 50.