2016
Àwọn ìṣe Tí Ó Ndarí sí Ìdùnnú
OṢù ṢẸ́rẹ́ 2016


Ọ̀dọ́

Àwọn ÌṣeTí Ó Ndarí sí Ìdùnnú

Ààrẹ Eyring kọ́ni pé ìdùnnú tí a nfẹ́ fún àwọn olùfẹ́ wa dá lé orí àwọn ohun tí wọ́n bá yàn.

Ẹ lè kà nípa àbájáde tí àwọn àṣàyàn lè ní láti inú àwọn àpẹrẹ ti Nífàì, Lámánì, àti Lẹ́múẹ́lì. Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì ráhùn wọn kò sì fẹ́ láti pa àwọn òfin mọ́ (wo 1 Nephi 2:12). Gẹ́gẹ́bí àyọrísí, àwọn àti àtẹ̀lé wọn gba ẹ̀gún a sì ké wọn kúrò ní iwájú Olúwa (wo 2 Nephi 5:20–24). Nífáì yàn láti gbọ́ran sí àwọn òfin (wo 1 Nephi 3:7), àti pé nítorí èyí, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbé ìgbé ayé irú ìdùnnú náà (2 Nephi 5:27

Ẹ lè yàn láti jẹ́ olódodo kí ẹ sì dunnú. Ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí àwọn ènìyàn ní àyíká yín ó ṣe àwọn àṣàyàn tí kò dára tí ó darí sí ìbànújẹ́ àti àìnítùnú. Nígbàtí àwọn ìpinnu wọ̃nnì jẹ́ tiwọn láti ṣe, àpẹrẹ yín lè ní ipá lórí àwọn àṣàyàn wọn fún rere. Báwo ni àwọn àṣàyàn yín ṣe lè mú ìdùnnú wá fún àwọn ẹlòmíràn? Ẹ sọ̀rọ̀ pẹ́lú ẹbí yín nípa onírúurú àwọn ọ̀nà tí ẹ fi lè ní ipa lórí àwọn wọ̃nnì tí wọ́n wà ní àyíka yín, kí ẹ sì rànwọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìdùnnú.