2016
Ìdùnnú fún Àwọn Wọnnì tí A Fẹ́ràn
OṢù ṢẸ́rẹ́ 2016


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Kínní, Oṣù Kínní 2016

Ìdùnnú fún Àwọn Wọnnì tí a fẹ́ràn

Gbogbo wa nfẹ́ ìdùnnú fún àwọn wọ̃nnì tí a fẹ́ràn, a sì nfẹ́ kí ìrora wọn kéré jọjọ bí ó bá ṣeéṣe. Bí a ṣe nka àwọn àkọsílẹ̀ ti ìdùnnú—àti ti ìrora—nínú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì, ọkàn wa rú sókè bí a ṣe nronú nípa àwọn tí a fẹ́ràn. Èyí ni àkọsílẹ̀ òtítọ́ kan nípa ìgbà ìdùnnú kan:

O sì ṣe tí kò sì sí asọ ní ilẹ̀ náà, nitori ifẹ Ọlọrun èyítí o ngbé inu ọkàn àwọn ènìyàn náà.

Ko sì sí ìlara, tabi ìjà, tabi ìrúkèrúdò, tàbí ìwà àgbèrè, tabi irọ pípa, tabi ìpànìyàn, tabi irúkírú ìwà ìfẹkúfẹ, dájúdájú kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ jù wọn láàrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti ọwọ Ọlọrun dá.

Nígbà náà a kà pé:

Báwo sì ní a tí bùkún wọn to Nítorítí Olúwa nbùkún wọn nínú ohun gbogbo tí wọn nṣe; bẹni àní Olúwa bùkún wọn o sì mú wọn ṣe rere titi ọgọrun ọdun o le mẹwa ti kọjá lọ àti ti ìran èkíní lẹhìn wíwá Krístì tí kọjá lọ; kò sì sí ìjà ní gbogbo ilẹ nã (4 Nífáì 1:15–16, 18).

Àwọn olùfẹ́ni ọmọ ẹ̀hìn Krístì máa ngbàdúrà wọ́n sì máa nṣiṣẹ́ fún irú ìbùkún yìí fún àwọn ẹlòmíràn àti fúnara wọn. Láti inú àwọn àkọsílẹ̀ inú Ìwé ti Mọ́rmọ́nì àti, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa, láti inú àwọn ìrírí ti ara wa, a mọ̀ pé ẹ̀bùn ìdùnnú ṣeé gbà. A mọ̀ pé ipa ọ̀nà sí ìdùnnú ti ní àmì dáadáa. Bákannáà a mọ̀ pé ṣíṣe ìtọ́jú ìdùnnú kò rọrùn àyàfi, bíi ti àwọn ará Nífáì lẹ́hìn ìbẹ̀wò Olùgbàlà, bí ìfẹ́ Ọlọ́run bá ngbé nínú ọkàn wa.

Ìfẹ́ náà wà nínú ọkàn àwọn ará Nífáì nítorí wọ́n pa àṣẹ tí ó jẹ́ kí ó ṣeéṣe mọ́. Àkékúrú àṣẹ náà ni a rí nínú àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá sí ólùfẹ́ni Bàbá Ọ̀run. A gbàdúrà pẹ̀lú ọkàn tí ó kún fún ìgbàgbọ́ nínú, àti pẹ̀lú ìfẹ́ jíjìnlẹ̀ fún, Olùgbàlà ti ara wa. A ní ojúṣe pẹ̀lú èrò òdodo láti gbé orúkọ̀ Rẹ̀ lé orí wa, láti rantí Rẹ̀, àti láti pa gbogbo òfin Rẹ̀ mọ́. Níkẹhìn, à nlo ìgbàgbọ́ pé kí Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ̀kẹ́ta ọmọ ẹgbẹ́ Olórí Ọ̀run, lè wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo, láti jẹ́rí sí ọkàn wa nípa Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀. (Wo D&C 20:77, 79.)

Pẹ̀lú jíjẹ́ ojúgbà ti Ẹ̀mí Mímọ́, ọkàn wa lè yípadà kí a lè fẹ́ kí a sì kí ìfẹ́ Bàbá wa Ọ̀run àti ti Olúwa Jésù Krístì káàbọ̀. Ọ̀nà láti gba ìfẹ́ Ọlọ́run sínú ọkàn wa rọrùn, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀nà láti ju ìmọ̀ara ti ìfẹ́ náà nù nínú ọkàn wa. Fún àpẹrẹ, ẹnìkan lè yàn láti dín iye ìgbà tí ó ngbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run kù tàbí kọ̀ láti san ìdámẹ́wàá pé tàbí dáwọ́dúró ní jíjíròrò lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí láti ṣe àìnáání àwọn òtòṣì àti aláìní.

Èyíkéyìí áṣàyàn tí kò ní jẹ́ kí á pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ lè mú kí Ẹ̀mí fàsẹ́hìn kúrò nínú ọkàn wa. Pẹ̀lú àdánù náà, ìdùnnú ńdínkù.

Ìdúnnú náà tí à ńfẹ́ fún àwọn wọ̃nnì tí a fẹ́ràn ndá lórí àwọn àṣàyàn wọn. Bí ó ti wù kí a ṣe fẹ́ràn ọmọ kan, olùwádìí, tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wa, a kò lè mú wọn nípá láti pa àwọn òfin mọ́ kí wọ́n lè yege fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi ọwọ́ kàn wọ́n àti láti yí ọkàn wọn padà.

Nítorínáà ìrànlọ́wọ́ tí ó dára jù tí a lè fúnni ni ohunkóhun tí ìbá lè darí àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn láti ṣe ìtọ́jú àwọn àṣàyàn ti ara wọn. Álmà ṣeé pẹ̀lú ìfipè kan tí ìwọ náà lè fúnni:

Kí ẹyin rẹ ara yín sílẹ níwájú Olúwa, kí ẹyin sì pe orúkọ rẹ mímọ kí ẹ máa ṣọnà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí a má bã dán yín wò ju agbára yín lọ, ati pé báyìí kí a lè darí yín nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ, kí ẹyin lè jẹ́ onírẹlẹ, oníwà-pẹlẹ, onítẹríba, onísùúrù, tí ó kún fún ìfẹ tí ó sì nfarada ohun gbogbo.

Kí ẹ ní ìgbàgbọ nínú Olúwa; kí ẹyin ó ní ìrètí pé ẹyin yíò gba ìyè ayérayé; kí ẹyin ó sì ní ìfẹ Ọlọrun ní gbogbo ìgbà nínú ọkàn yín, kí a lè gbé yín sókè ní ọjọ ìkẹhìn kí ẹyin sì wọ ínú ìsinmi rẹ̀ (Alma 13:28–29).

Mo gbàdúrà pé kí àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn lè gba ìfipè ìmísí kan láti yan ipá ọ̀nà sí ìdúnnú pípẹ́.

Ẹkọ láti inú Ọrọ Yí

Ààrẹ Eyring kọ́ni pé ìdùnnú tí a nní ìmọ̀lára rẹ nínú ayé dá lé orí àwọn ìpinnu tí à nṣe. Bí ẹ ṣe nṣe àjọsọ ọ̀rọ̀ yí, ẹ gbèrò títẹjúmọ́ àwọn ohun tí Ààrẹ Eyring mẹ́nubà pé a lè yàn láti ṣe (bí irú àdúrà gbígbà, síṣe ìṣẹ́, lílo ìgbàgbọ́, àti títẹramọ́ ara wa pẹ̀lú èrò òtítọ́) láti darí wa lọ sí ipá ọ̀nà ìdùnnú. Ẹ lè pe àwọn wọ̃nnì tí ẹ nkọ́ láti kọ àwọn ìṣe méjì tàbí mẹ́ta sílẹ̀ tí wọ́n lè fẹ́ràn láti ṣe tí yíò túbọ̀ darí wọn dáradára sí ipá ọ̀nà sí ìdùnnú pípẹ́.