2017
Bí Mo Ṣe Fẹ́ràn Yín
OṢù Èrèlè 2017


Ọ̀RỌ̀ÀJỌÀÀRẸKÍNNÍ, GBOGBOGBÒÒ, Oṣù Kejì Ọdún 2017

“Bí Mo Ṣe Fẹ́ràn Yín”

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn ọ̀rẹ́ kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Louis sọ àkọsílẹ̀ ìrọ̀rùn kan nípa ìyá rẹ̀ ẹni jẹ́jẹ́, ọlọ́rọ̀ tútú lẹ́nu. Nígbàtí ó kú, kò fi ohun àmúsọrọ̀ kankan bí owó sílẹ̀ fún àwọn ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin rẹ̀ ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ìní ọrọ̀ nínú àpẹrẹ, nínú ìrúbọ̀, nínú ìgbọràn.

Lẹ́hìn sísọ àwọn ọ̀rọ̀ oríyìn ìsìnkú àti tí rírìn ìrìn ìbànújẹ́ lọ sí ibi ìtẹ́ tí jẹ́ ṣíṣe, àwọn tí wọ́n ti dàgbà nínú ẹbí fi ara balẹ̀ yanjú àwọn ohun ìní tí kò tó nkan tí ìyá fi sílẹ̀. Ní àárín wọn, Louis rí àkọsílẹ̀ kan àti kọ́kọ́rọ́ kan. Àkọsílẹ̀ náà ṣe àlàyé pé: “Ní igun yàrá ibùsùn, ní ìsàlẹ̀ inú àpótí ara tábìlì ìmúra mi, ni kóló kékeré kan wà. Ó ní ìṣura ọkàn mi nínú. Kọ́kọ́rọ́ yí yíò ṣí kóló náà.”

Ó ya gbogbo wọn lẹ́nu ohun tí ìyá wọn ní tí ó níyelórí tóbẹ́ẹ̀ láti gbé sí ábẹ̀ ìtìmọ́lé pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́.

Wọ́n gbé àpótí náà kúrò níbi ìsimi rẹ̀ wọ́n fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣíi pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ kọ́kọ́rọ́. Bí Louis àti àwọn míràn ṣe nyẹ ohun tó wà nínú àpótí náà wò, wọ́n rí fọ́tò ọmọ kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orúkọ ọmọ náà àti ọjọ́ ìbí. Nígbà náà Louis fa valẹntínì àfọwọ́ṣe kan jáde. Pẹ̀lú, onkòwé àfọwọ́dá tí ó dàbí ti ọmọdé, èyí tí òun dámọ̀ bíi ti ara rẹ̀, ó ka àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti kọ ní ọgọ́ta ọdún ṣíwájú: “Ìyá Ọ̀wọ́n, Mo ní ìfẹ́ rẹ.”

Ọkàn rẹ̀ wálẹ̀, ohùn fẹ́lẹ́, ojú ṣomi. Ìṣura ìyá ni ẹbí ayérayé rẹ̀. Okun rẹ̀ dúró lé òkúta ìpìlẹ̀ ti “Mo ní ìfẹ́ rẹ.”

Ní ayé òní, kò sí ibi kankan tí a ti nílò òkúta ìpìlẹ̀ ìfẹ́ ju inú ilé lọ. Kò sì sí ibi tí ayé ti gbọ́dọ̀ rí àpẹrẹ dídáraju ti ìpìlẹ̀ náà ju ilé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn lọ tí wọ́n ti fi ìfẹ́ ṣe ọkàn ìgbé ayé ẹbí wọn.

Sí àwa wọnnì tí a ti jẹ́wọ́ pé a jẹ́ ọmọlẹ́hìn Olùgbàlà Jésù Krístì, Ó fúnni ní àṣẹ tó lámì yí:

“Òfin titun kan ni mo fi fún yín, Pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín gẹ́gẹ́bí èmi ti fẹ́ràn yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín bákannáà.

“Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”1

Bí awa ó bá pa òfin láti fẹ́ràn ara wa mọ́, a gbọ́dọ̀ tọ́jú ara wa pẹ̀lú inúrere ati ìtẹríba. Ìfẹ́ nfúnni ní ọ̀rọ̀ rere, ìfèsì sùúrù, ìṣe àìmọtaraẹni nìkan, etí tí ó ngbọ́ àgbọ́yé, àti ọkàn tí ó ndáríjì. Nínú gbogbo ìbálòpọ̀ wa, ìwọ̀nyí àti awọn ìwà míràn bíi wọn yíò ṣèrànwọ́ láti fi ìfẹ́ hàn ní ọkàn wa.

Ààrẹ Gordon B. Hinckley (1910–2008) ṣe àkíyèsí: “Ìfẹ́ … ni ìkòkò wúrà ní òpin òṣùmàrè. Síbẹ̀síbẹ̀ o ju òpin oṣùmàrè lọ. Ìfẹ́ wà ní ìbẹ̀rẹ̀ bákannáà, àti pé láti inú rẹ̀ ni ẹwà nsun jáde tí ó wà káàkiri ojú ọ̀run ní ọjọ́ ìjì. Ìfẹ́ ni ààbò èyí tí àwọn ọmọ nsọkún fún, ìtara ọ̀dọ́, àlẹ̀mọ́ tí ó so ìgbeyàwó pọ̀, àti òróró tó ndáwọ́ ibi dúró nínú ilé; ó jẹ́ àláfíà ọjọ́ ogbó, ìmọ́lẹ̀ ìrètí tó ntàn la ikú já. Báwo ni ọrọ̀ àwọn wọnnì ti pọ̀ tó tí wọ́n ngbádùn rẹ̀ nínú ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú ẹbí, ọ̀rẹ́, ìjọ, àti aládùúgbò.”2

Ifẹ́ ni àkojá ìhìnrere, ìwà akọni ti ẹ̀mí ènìyàn. Ìfẹ́ ni àtúnṣe fún àìlera àwọn ẹbí , àwọn àdúgbò tí ó nṣe àìsàn, àti àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ní àrùn. Ìfẹ́ ni ẹ̀rín músẹ́, ìjúwọ́ síni, ìsọ̀rọ̀ rere, àti ìfúnni ní ìwúrí. Ìfẹ́ ni ìrúbọ, iṣẹ́ ìsìn, àti àìmọtaraẹni nìkan.

Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn wọn aya yín. Ẹ tọ́jú wọn pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìmọrírì. Ẹ̀yin arábìnrin, ẹ fẹ́ràn àwọn ọkọ yín. Ẹ tọ́jú wọn pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìgbani níyànjú.

Ẹ̀yin òbí, ẹ fẹ́ràn àwọn ọmọ yín. Ẹ gbàdúrà fún wọn, ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì jẹ́ ẹ̀rí sí wọn. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ fẹ́ràn àwọn òbí yín. Ẹ fi ọ̀wọ̀ hàn wọ́n, ìmoore, àti ìgbọràn.

Láìsí ìfẹ́ àìlẽrí ti Krístì, Mọ́mọ́nì gbàni nímọ̀ràn, “[a] kò já mọ́ nkankan.”3 Àdúrà mi ni pé kí a lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn ti Mọ́mọ́nì lati “gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo okun ọkàn, kí [a] lè kún fún ìfẹ́ rẹ̀yìí tí ó ti fi fún gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì; kí [a] lè di ọmọ Ọlọ́run; pé nígbàtí yíò bá farahàn a ó dàbí rẹ̀.”4

Ìkọ́ni láti inú Ọrọ Yí

Ààrẹ Monson kọ́ wa ní kókó ṣíṣe àfihàn ìfẹ́ tòótọ́ bíiti Krístì, pàtàkì jùlọ nínú ilé. Gbèrò bíbèèrè lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí ẹ̀ nbẹ̀wò láti kórapọ̀ bí ẹbí kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè fi ìfẹ́ hàn fún ara wọn síi. Ẹ lè gbà wọ́n níyànjú láti yan ọ̀kan lára àwọn èrò wọnnì kí wọn ó sì ṣe ètò láti ṣe àṣeyege rẹ̀ bí ẹbí. Fún àpẹrẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí lè lépa láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ní àṣírí sí mọ̀lẹ́bí míràn ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ lẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ wọn láti ronú lẹ́hìnwá lórí bí titiraka láti dé ìfojúsùn wọn ṣe nmú ìfẹ́ pọ̀si nínú ilé wọn.