2017
Mo ti Pinnu Tẹ́lẹ̀
March 2017


Ọdọ

Mo ti Pinnu Tẹ́lẹ̀

Olùkọ̀wé náà ńgbé ní Utah, USA

Nígbàkan mo ti gba ẹ̀kọ́ iyebíye kan nínú kíláàsì àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin lórí ìbálòpọ̀ mímọ́—àkọlé kan tí ó mú púpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ súnrakì lórí ìjòkó wọn. Èmi kò rántí gbogbo ohun tí mo kọ́ ní ọjọ́ náà, ṣùgbọ́n mo rántí pé olórí mi sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára òṣùwọn ti araẹni rẹ̀—láti dúró ní mímọ́ sí ìbálòpọ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dúró pẹ̀lú mi, nígbànáà mo sì pinnu ìmọ̀sínú láti gbàá mọ́ra bí ọ̀kan lára àwọn iyì araẹni tèmi.

Ní ọjọ́ kan bí mo ṣe nlọ sílé nínú ọkọ̀ èrò láti ibi ìṣẹ̀lẹ̀ eré ìdárayá kan, ẹnìkan nínú ọkọ̀ èrò náà bẹ̀rẹ̀ eré síṣe kan nípa òtítọ́ tàbi ìdánwò. Ní dídá-lágara, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọdé míràn àti èmi darapọ̀ mọ́ wọn. Nígbàtí ó yí kàn èmi, mo ní àdánwò láti ṣe ohun kan tí mo mọ̀ pé kò tọ́. Èyí ìbá ti jé ìpinnu líle kan fún mi láti ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ olórí ọ̀dọ́mọbìnrin mi wá sí orí mi, àṣàyàn mi sì rọrùn. Mo kọ̀ kíákíá. Mo ti mu ọkàn mi le nípa ohun tí èmí ó ṣe nínú ipò náà.

Mo mọ̀ pé nígbàtí a bá lọ ilé ìjọsìn tí a sì fi àyè gba àwọn ohun tí wọ́n kọ́wa níbẹ̀, a ó gba ìbùkún pẹ̀lú okun ti ẹ̀mí àti ìdáàbòbò tí ó tóbi síi lọ́wọ́ àwọn àdánwò ayé.