2018
Ìkópa àwọn Arábìnrin nínú Ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì
November 2018


Ọ̀rọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Oṣù Kọkànlá 2018

Ìkópa àwọn Arábìnrin nínú Ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì

Mo nawọ́ ẹ̀bẹ̀ ti wòlíì síi yín, ẹ̀yin obìnrin Ìjọ, láti tun ọjọ́-ọ̀la ṣe nípa ṣíṣerànwọ́ láti kó àwọn Ísráẹ́lì tí a fọ́nká jọ.

Ó jẹ́ ìyàlẹ́nú láti wà pẹ̀lú yín, ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n. Bóyá ìrírí kan láìpẹ́ yíò mú yín rí díẹ̀ lára bí mo ṣe nímọ̀lára nipa yín àti àwọn agbára títóbijùlọ pẹ̀lú èyí tí a fifún yín.

Níjọ́ kan nígbàtí a nbá gbogbo ìjọ sọ̀rọ̀ ní Gúsù Amẹ̀ríkà, mo ní inú dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀ nípa kókó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ mi, àti pé ní àkokò pàtàkì kan, mo wípé, “Bí ìyá àwọn ọmọ mẹwa, mo lè wí fún un yín pé …” nígbànáà mo lọ láti parí ọ̀rọ̀ mi.

Èmi kò mọ̀ pé mo ti sọ ọ̀rọ̀ náà ìyá. Olùtumọ̀ mi, tó rò pé mo ti ṣi ọ̀rọ̀ sọ, yí ọ̀rọ̀ náà padà láti ìyábàbá, nítorínáà gbogbo ìjọ kò mọ̀ rárá pé mò ntọ́ka sí ara mi bí ìyá. Ṣùgbọ́n aya mi Wendy gbọ́ọ, ó sì dunnú fún àsọjáde ìjìnlẹ̀-ìfẹ́ mi.

Ní àkokò náà, ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ ọkàn mi láti mú ìyàtọ̀ wá sínú ayé—bí ìyá nìkan ṣe nṣe—hó sókè látinú ọkàn mi. Ní àkokò náà, ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ ọkàn mi láti mú ìyàtọ̀ wá sínú ayé—bí ìyá nìkan ṣe nṣe—hó sókè látinú ọkàn mi. Ní gbogbo ọdún, nígbàkúgbà tí a bá bá bèèrè ìdí tí mo fi yàn láti jẹ́ dókítà oníṣègùn, ìdáhùn mi nígbàgbogbo jẹ́ bákannáà: “Nítorí èmi kò lè yan láti jẹ́ alábiyamọ.”

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsi pé nígbàkugbà tí mo bá lo ọ̀rọ̀ náà ìyá, èmi kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin tí ó ti bímọ tàbí gba àwọn ọmọ tọ́ nínú ayé yí. Èmi nsọ̀rọ̀ nípa gbogbo àwọn ọmọbìnrin àgbà ti àwọn Òbí Ọ̀run ni. Olúkúlùkù obìnrin ni ìyá nípa ìwàrere ẹ̀dá ọ̀run rẹ̀.

Nítorínáà lálẹ́yìí, bíi bàbá àwọn ọmọ mẹwa—àwọn ọmọbìnrin mẹsan àti ọmọkùnrin kan—àti pé bí Ààrẹ Ìjọ, mo gbàdúrà pé ẹ ó mọ̀ bí mo ṣe fẹ́ràn yín jinlẹ̀ tó—nípa ẹni tí ẹ jẹ́ àti gbogbo ire tí ẹ̀ lè ṣe. Kò sí ẹnìkankan tí ó lè ṣe ohun tí olódodo obìnrin lè ṣe. Kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe àtúndá agbára ìyá.

Àwọn ọkùnrin lè àti pé lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n nbánisọ̀rọ̀ ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà sí àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n àwọn obìnrin ní ẹ̀bùn pàtàkì fun un—ìfúnni lẹ́bùn tọ̀run. Ẹ ní agbára láti ní òye ohun tí ẹnìkan nílò—àti ìgbàtí ọkùnrin tàbí obìnrin nílò rẹ̀. Ẹ lè nawọ́ jade, tùnínú, kọ́ni, àti kí ẹ fún ẹnìkan lókun ní àkokò àìní gan ọkùnrin tàbí obìnrin náà.

Àwọn obìnrin nrí àwọn nkan lóríṣiríṣi ọ̀nà ju àwọn ọkùnrin lọ, àti pé ah, bí a ṣe nílò ìrò yín! Ìwà-ẹ̀dá yín ndarí yín láti ronú nípa àwọn ẹlòmíràn lákọ́kọ́, láti gbèrò àbájáde ohun tí ìwàkiwà lè ní lórí ẹlòmíràn.

Bí Ààrẹ Eyring ṣe sọọ́ jáde, Ìyá wa Éfà ológo ni—pẹ̀lú ìran gíga ti ètò Bàbá Ọ̀run—ẹnití ó ṣe ohun tí a pè ní “Ìṣubú náà.” Àṣàyàn ọlọgbọ́n àti ìgboyà rẹ̀ àti àtìlẹhìn ìpinnu Ádámù mú kí ètò ìdùnnú Ọlọ́run tẹ̀síwájú. Wọ́n mú kí o ṣeéṣe fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti wá sílẹ̀ ayé, láti gba ara, àti láti fi hàn pé a ó yàn láti dúró fún Jésù Krístì nísisìyí, gẹ́gẹ́bí a ti ṣe ní ayé ìṣíwájú.

Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ ní àwọn ẹ̀bùn pàtàkì ti ẹ̀mí àti àwọn ìtẹ̀sí. Tonight I urge you, with all the hope of my heart, to pray to understand your spiritual gifts—to cultivate, use, and expand them, even more than you ever have. Ẹ ó yí ayé padà bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀.

Bí àwọn obìnrin, ẹ̀ nfún àwọn míràn ní ìmísí ẹ sì ngbé òṣùwọ̀n tó yẹ fún àfarawé sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí nfún yín ní àtilẹ̀wá kékeré kan lórí àwọn kókó ìfilọ̀ méjì tí a ṣe ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tó kọjá. Ẹyin, arábìnrin mi ọ̀wọ́n, jẹ́ pàtàkì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Àkọ́kọ́, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Òṣùwọ̀n títóbi jùlọ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Káàkiri, àwọn obìnrin ni, wọ́n sì ti, súnmọ́ òṣùwọ̀n náà ju àwọn okùnrin lọ. Nígbàtí ẹ bá nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nítòótọ́, ẹ̀ ntẹ̀lé àwọn ìmọ̀lára yín láti ran ẹnìkan lọ́wọ́ láti ní ìrírí síi nípa ìfẹ́ Olùgbàlà. Fífẹ́ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ àbímọ́ nínú àwọn obìnrin olódodo. Mo mọ àwọn obìnrin tí wọ́n ngbàdúrà lójoojúmọ́, “Tani ẹni tí Ẹ̀yin ó fẹ́ kí nrànlọ́wọ́ loni?”

Ṣíwájú ìfilọ̀ Oṣù Kẹrin (Igbe) 2018 nípa ọ̀nà gíga àti mímọ́ jùlọ ti ṣíṣe ìtọ́jú fún àwọn ẹlòmíràn, ìfẹ́ àwọn ọkùnrin kan ni láti fi àmì sí ìfúnni-níṣẹ́ ṣe ìkọ́ni nílé wọn bí “a ti ṣé” kí wọn sì tẹ̀síwájú fún iṣẹ́ tó kàn.

But when you sensed that a sister you visit taught needed help, you responded immediately and then throughout the month. Nísisìyí, ẹ bá ṣe ṣe ìbẹ̀wò ìkọ́ni ni yíò fún ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ wa ní ìmísí ìgbéga.

Ìkejì, nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tó kẹ́hìn, bákannáà a ṣe àtúntò sí àwọn iyejú Oyè-àlùfáà Mẹlkisẹ́dẹ́kì. Nígbàtí a tiraka pẹ̀lú bí a ó ti ran àwọn ọkùnrin Ìjọ lọ́wọ́ láti láápọn si nínú ojúṣe wọn, a fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gbèrò àpẹrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́.

Nínú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, àwọn obínrin ní onírurú ọjọ́ orí àti ipò ayé nṣe ìpàdé papọ̀. Ọdún mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ayé nmu àwọn ìpènijà tó yàtọ̀ wá, àti pé síbẹ̀síbẹ̀, ibẹ̀ ìwọ wà, ọ̀sẹ̀ lẹ́hìn ọ̀sẹ̀, dídarapọ̀ mọ́, dídàgbàsókè àti ìkọ́ni ìhìnrere papọ̀, àti mímú ìyàtọ̀ òdodo wá nínú ayé.

Nísisìyí, títẹ̀lé àpẹrẹ yín, àwọn olóyè Oyè-àlùfáà Mẹ́lkisédẹ́kì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ iyejú àwọn alàgbà. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wà ní ọjọ́ orí ọdún méjìdínlógún sí mejìdín lọ́gọ́ọ̀rún (tàbí jù bẹ́ẹ̀), pẹ̀lú onírurú oyè-àlùfáà bákannáà àti àwọn ìrírí Ìjọ. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí lè dá ìsopọ̀ ẹgbẹ́ tó lágbára jùlọ, kẹ́kọ̀ọ́ papọ̀, àtibùnkún àwọn ẹlòmíràn lọ́nà dídára jùlọ.

Ẹ rántí pé ní Oṣù Kẹfà (Òkudù) tó kọjá, Arábìnrin Nelson àti èmi bá àwọn ọ̀dọ́ Ìjọ sọ̀rọ̀. A pè wọ́n láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀dọ́ ti Olúwa láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ọ̀nà méjèèjì ìbòjú. Ìkójọpọ̀ yí ni “ìpènijà títóbi jùlọ, èrò, títóbi jùlọ àti iṣẹ́ orí ilẹ̀ ayé títóbi jùlọ lónì!”!1

Èrò tí ó nílò àwọn obìnrin kíkankíkan ni, nítorí àwọn obìnrin ló ntú ojọ́ ọ̀la ṣe. Nítorínáà lalẹyi mo nawọ́ ẹ̀bẹ̀ ti ìsọtẹ́lẹ̀ wòlíì sí yín, ẹ̀yin obìnrin Ìjọ, láti tún ọjọ́ ọ̀la ṣe nípa ṣíṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì tí fọ́n ká jọ.

Níbo ni ẹ ti lè bẹ̀rẹ̀?

Njẹ́ kí nfi ìpè mẹ́rin sílẹ̀:

Àkọ́kọ́, mo pè yín láti kópa nínú àwẹ̀ ọlọ́jọ́ mẹwa kúró nínú ìbákẹ́gbẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti nínú àwọn ọ̀nà ìfohùnránṣẹ́ tó nmú àìdáa àti àwọn èrò àìmọ́ wá sínú yín. Gbàdúrà láti mọ irú agbára èyí tí ẹ o yọ kúrò nígbà àwẹ. Àbájáde àwẹ̀ ọlọ́jọ́ mẹwa yín lè yà yín lẹ́nu. Kíni àkíyèsí ohun tí ẹ ṣe lẹ́hìn tí ẹ ti kúró nínú àwọn ìrò ayé tí ó npá ẹ̀mí yín lára? Ṣé ìyípadà wà níbi tí ẹ ti fẹ́ lo àsìkò àti okun yín nísisìyí Njẹ́ àwọn ìdáwọ́lé yín ti yípo—àní ní díẹ̀ kékeré? Mo rọ̀ yín láti kọsílẹ̀ kí ẹ sì tẹ̀lé ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtẹ̀mọ́ra.

Ìkejì, mo pè yín láti ka Ìwé Mọ́rmọ́nì nísisìyí títí di ìparí ọdún. Bí ó tilẹ ṣòro pẹ̀lú gbogbo ìtiraka ìgbé ayé yín, tí ẹ o bá tẹ́wọ́gba ìpè yí pẹ̀lú gbogbo èrò ọkàn kíkún, Olúwa yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ṣé àṣeyọrí. Àti pé, bí ẹ ti nfi tàdúrà-tàdúrà ṣàṣàrò, mo ṣèlérí pé ọ̀run yíò ṣí fún yín. Olúwa yíò bùkún yín pẹ̀lú àníkún ìmísí àti ìfihàn.

Bí ẹ ṣe nkàá, mo gbà yín níyànjú láti fi àmi sí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan tí ó sọ̀rọ̀ tàbí tọ́ka sí Olùgbàlà. Nígbànáà, mọ̀ọ́mọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Krístì, yọ̀ nínú Krístì, àti pé kí ẹ wàásù nípa Krístì pẹ̀lú ẹbí yín àti àwọn ọ̀rẹ́ yín.2 Ẹ̀yin àti àwọn yíò fà súnmọ́ Olùgbàlà nípa ẹ̀tò yí. Àti pé àwọn ìyípadà, àní àwọn iṣẹ́-ìyanu, yíò bẹ̀rẹ̀ síí ṣẹlẹ̀.

Ní àárọ̀ yí a ṣe ìfilọ̀ nípa èto titun ti Ọjọ́-ìsinmi àti èyí tí ó dá lórí ilé, èto ẹ̀kọ́ tí ó ní àtìlẹ́hìn Ìjọ. Ẹ̀yin, arábìnrin mi ọ̀wọ́n, jẹ́ kókó àṣeyege, ìtiraka ìbádọ́gba ìkọ́ni-ìhìnrere titun yí. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kọ́ àwọn tí ẹ fẹ́ràn ní àwọn nkan tí ẹ́ nkọ́ nínú àwọn ìwé mímọ́. Ẹ kọ́ wọn lọ́nà láti yípadà sí Olùgbàlà fún ìwòsàn àti agbára ìwẹ̀nùmọ́ Rẹ̀ nígbatí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀. Kí ẹ sì kọ́ wọn láti fa agbára ìfúnnilókun Rẹ̀ sórí ìgbé ayé wọn lójoojúmọ́.

Ìkẹ́ta, gbé àwòkọ́ṣe lílọ sí tẹ́mpìlì déédé kalẹ̀. Èyí lè béèrè fún ìyọnda díẹ̀ si nínú ayé yín. Lílo àkokò síi déédé nínú tẹ́mpìlì yíò fàyè gbà Olúwa láti kọ́ọ yín ọ̀nà láti fa agbára oyè-àlùfáà Rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí a fifún yín ní tẹ́mpìlì Rẹ̀ sórí yín. Fún àwọn tí kò gbé nítòsí tẹ́mpìlì, mo pè yín láti ṣe àṣàrò tàdúrà-tàdúrà nípa àwọn tẹ́mpìlì nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nínú àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì alààyè. Wá láti mọ̀ọ́ si, láti ní òye si, láti nímọ̀lára síi nípa àwọn tẹ́mpìlì ju bí ẹ ṣe ní rí.

Nínú ìjọ́sìn àgbáyé àwọn ọ̀dọ́ wa ní Oṣù Kẹfà (Òkudù), mo sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹnití ìgbé ayé rẹ̀ yípadà nígbàtí´ àwọn òbí rẹ̀ yí fóònu-àtẹ̀ká rẹ̀ sí fóònù-ṣíṣí. Ìyá ọ̀dọ́mọkùnrin yí jẹ́ onígboyà àti onígbàgbọ́ obìnrin. Ó ri pé ọmọ òun nlọ sọ́nà àwọn àṣàyàn tí ó lè dènà rẹ̀ láti sìn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ó mú ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ lọ sí tẹ́mpìlì láti mọ ọ̀nà tó dàara jùlọ láti ran ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́hìnnáà ó tẹ̀lé gbogbo ìtẹramọ́ tó gba tímọ́tímọ́.

Ó wípé: “Mo ní ìmọ̀lára ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí láti wo fóònù ọmọ mi ní àwọn àkokò kan pàtó láti rí àwọn nkan pàtó. Èmi kò mọ̀ bí wọ́n ṣe nwo fóònù-àtẹ̀ká, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí tọ́ mi sọ́nà ní gbogbo ìbákẹgbẹ́ ìròhìn tí èmi kìí lo rárá! Mo mọ pé Ẹ̀mí Mímọ́ nran àwọn òbí tí wọ́n nwá ìtọ́sọ́nà láti dá áábó bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. [Lakọkọ] ọmọ mi bínú sí mi. … Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́ta péré, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ mi! O ti rí ìyàtọ̀.”

Ìwà ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìṣesí rẹ̀ yípada lọ́gán. Ó di ẹnití nranilọ́wọ́ síi nínú ilé, ó nrẹrin si, ó sì nfetísílẹ si nílé ìjọsìn. Ó fẹ́ràn láti sìn fún ìgbà kan ní ibi-ìrìbọmi tẹ́mpìlì àti ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.

Ìpè mi kẹrin, fún ẹ̀yin tí ẹ ti dàgbà tó, ni láti kópa ní kíkún nínú Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́. Mo rọ̀ yín láti ṣàṣàrò èrò ìsọ̀rọ̀ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ti àkókò yìí. O ní ìmísí. Ó lè tọ́ yín sọ́nà ní mímú yín dàgbà si nínú èrò ìsọ̀rọ̀ fún ayé yín. Bákannáà mo bẹ̀ yín láti mú adùn òtítọ́ tí ó wà nínú àtẹ̀jádé ìkéde Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ tí a tẹ̀ jáde bíi ogún ọdún sẹ́hìn lò.3 Ẹ̀dà ìkéde yí wà lórí ìkọ́ lára ògiri níléṣẹ́ Ààrẹ Àjọ Ikínní. Mò nláyọ nígbogbo nígbà tí mo bá kàá Ó ṣàpèjúwe ẹni tí ẹ jẹ́ àti ẹni tí Olúwa nílò yín láti jẹ́ ni àsìkò yí gan an bí ẹ ti nsa ipá tiyín láti ṣèrànwọ́ ní ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì tí a fọ́nká

Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, a nílò yín! A “nílò your okun, yín ìyípadà ọkàn, yín agbára, yín láti darí ability to lead, ọgbọ́n yín, àti àwọn ohun yín.”4 A kò lè kó Ísráẹ́lì jọ pẹ̀lú ìrọ̀rùn láìsi yín níbẹ̀.

Mo nifẹ yín mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín mo si bùkún yín nísìsìyí pẹ̀lú agbára láti fi ayé sílẹ̀ lẹ́hìn yín bí ẹ ṣe nṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ pàtàkì ti ó gbọ́dọ̀ yá kíákíá yí. Lápapọ̀ a lè ṣe ohun gbogbo tí Bàbá Ọ̀run nílò wa láti ṣe láti múra aráyé sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.

Jésù ni Krístì. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Nípa Èyí ni mo jẹ́ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, Àmín.

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Russell M. Nelson, “Hope of Israel” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.lds.org.

  2. Wo 2 Nephi 25:26.

  3. Fún ìkéde Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, wo Mary Ellen Smoot, “Ọmọbìnrin Síónì, Ẹ yọ̀,” Liahona, Jan. 2000, 111–14.

  4. Russell M. Nelson, “Ẹ̀bẹ̀ Kan Sí Ẹ̀yin Arábìnrin Mi,” Liahona, Nov. 2015, 96; àtẹnumọ́ àfikún.