2018
Orúkọ Títọ́ Ìjọ
November 2018


Orúkọ Títọ́ Ìjọ

Jésù Krístì darí wa láti pe Ìjọ ní orúkọ Rẹ̀ nítorí Ìjọ Rẹ̀ ni, ó sì kún fún agbára Rẹ̀.

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ní Ọjọ́-ìsinmi dídára yí a láyọ̀ papọ̀ nínú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún wa látọ̀dọ̀ Olúwa. A fi ìmoore hàn fún àwọn ẹ̀rí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì yín, fún àwọn ọrẹ-ẹbọ tí ẹ ti ṣe láti dùró lórí tàbí padà sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀, àti fún iṣẹ́ ìsìn iyàsọ́tọ̀ yín nínú Ìjọ Rẹ̀.

Loni mo ní ìmọ̀lára tipátipá láti ba yín sọ̀rọ̀ pàtàkì nlá. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́hìn, mo fi ẹ̀là ọ̀rọ̀ kan ṣọwọ́ síta nípa àtúnkọ sí orúkọ Ìjọ.1 Mo ṣe èyí nítorí Olúwa tẹ pàtàkì orúkọ tí Òun ti paláṣẹ fún Ìjọ Rẹ̀ mọ́ mi nínú, àní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn.2

Bí ẹ ṣe rò, ìfèsì sí ìsọ̀rọ̀ yí àti sí àtúnṣe irú ìtọ́nisọ́nà3 náà ti wọ́pọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ìjọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tún orúkọ Ìjọ kọ lórí búlọ́ọ̀gù wọn àti ojú-ewé ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn. Àwọn míràn ndá idì rẹ̀ rò, pe pẹ̀lú gbogbo ohun tó nlọ láyé, ó dára láti tẹnumọ́ ohun kan tí kò “pọndandan”. Àwọn kan sọpé kò ṣeéṣe, nítorínáà kínìdí ìtiraka? Ẹ jẹ́ kí nṣàlàyé ìdí tí a fi nítara tó jinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yí. Ṣugbọ́n lakọkọ ẹ jẹ́ kí nsọ ohun tí ìlàkàkà yí ko kà kún:

  • Kì í ṣe ìyípadà orúkọ.

  • Kì í ṣe àtúnṣe.

  • Kì í ṣe ìkúnra.

  • Kì í ṣe àròfọ̀.

  • Kì í sì ṣe àìtọ́.

Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ títúnṣe. Ó jẹ́ àṣẹ Olúwa. Joseph Smith kò fún Ìjọ lórúkọ nípasẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ná ni Mọ́rmọ́nì. Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ ni ó sọ wipe, “Nítorí báyìí ni a ó pe orúkọ ìjọ mi ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, àní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.”4

Àní ṣíwájú, ní AD mẹ́rìnlélọ́gbọ́n(lẹ́hìn iku Kristi), Olúwa olùjíìnde wa fi irú àṣẹ kannáà fún àwọn ọmọ Ìjọ Rẹ̀ nígbàtí ó bẹ̀ wọ́n wò ní àwọn Amẹ́ríkà. Ní ìgbà náà O wípé:

“Ẹ̀yin ó pe ìjọ nã ní orúkọ mi. …

Báwo ni yíò sì ṣe jẹ́ ìjọ mi bí a kò bá pẽ ní orúkọ mi? Nítorípé bí a bá pe ìjọ kan ní orúkọ Mósè, ìjọ Mósè ni íṣe nígbànã; tàbí bí a bá pẽ ní orúkọ ẹnìkan, ìjọ ẹnìkan ni íṣe nígbànã; ṣùgbọ́n bí a bá pẽ ní orúkọ mi, ìjọ mi ni íṣe nígbànã.”5

Báyìí, orúkọ Ìjọ kò gba ìdúnádúrà. Nígbàtí Olùgbàlà sọ kedere inkan ti orukọ ìjọ Rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ àní síwaju ìkéde Rẹ pé, Bayi ni a o pe ìjọ mi,” Ó ṣe pataki. Ati pé bi a ba gba ìnagijẹ láàyè ni lilo ati gbigba tabi ani onígbọ̀wọ́ inagijẹ wọnnì funra wa, O bínú.

Kíni ó wà nínú orúkọ, tàbí nínú ọ̀ràn yí, ìnagijẹ̀ kan? Nígbàtí ó bá di ti àwọn ìnagijẹ ti Ìjọ, irù bí “Ìjọ LDS” “Ìjọ Mọ́rmọ́nì,” tàbí “Ìjọ àwọn Èníyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,” ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn orúkọ náà ni àìsí orúkọ Olùgbàlà. Láti mú orúkọ Olúwa kúrò nínú Ìjọ Olúwa ni kòkò ìṣẹ́gun fún Sátánì. Nígbàtí a bá sọ orúkọ Olùgbàlà nù, à nfi ọgbọọgbọ́n ṣe àìkàsí gbogbo ohun tí Jésù ṣe fún wa—àní Ètùtù Rẹ̀.

Gbèrò èyì nínú ìwò Tirẹ̀: Ní ayé àìkú Òun ni Jehófà, Ọlọ́run Májẹ̀mú Láéláé. Lábẹ́ ìdarí Bàbá Rẹ̀, Òun ni Aṣẹ̀dá èyí àti àwọn ayé míràn.6 Ó yàn láti fi ara sílẹ̀ fún ìfẹ́ Bàbá Rẹ̀ Ó sì ṣe ohunkan fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ẹnìkankan kò lè ṣe! Rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wá sílẹ̀ ayé bí Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo ti Bàbá nínú ẹran-ara, Wọn fi ṣẹ̀gàn rírorò, ṣẹ̀sín, tutọ́ si lórí, àti adé-ẹ̀gún. Nínú ọgbà Gethsemane, Olùgbàlà wa gbé gbogbo ìrora, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, àti gbogbo ìpalára àti ìjìyà tí ẹ̀yin àti èmi àti nípasẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó ti gbé rí tàbí yíò gbé kò ní ìrírí rẹ̀ rí ever Lábẹ́ àjàgà ẹ̀rù àìlesọ, Ó ṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara.7 Gbogbo ìjìyà yí le si bí wọ́n ṣe fi tìkanra-tíkanra kàn Án mọ́ àgbélébù.

Nípasẹ̀ àwọn ìrírí àilèsọ wọ̀nyí—Ètútú àìlópin Rẹ̀—Ó fi ayé àìkú fún gbogbo ènìyàn, ó sì ràwápadà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan látinú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀, lórí ipò ìronúpìwàdà wa.

Títẹ̀lé Àjíìnde Olùgbàlà àti ikú àwọn Àpọ́stélì Rẹ̀, ayé wọnú òkùnkùn àwọn díkédì. Nígbànáà ní ọdún 1820, Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, farahan Wòlíì Joseph Smith láti fi ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Olúwa lélẹ̀.

Lẹ́hìn gbogbo ohun tí Ó ti farada—lẹ́hìn gbogbo ohun tó ṣe fún aráyé, mo mọ̀ pẹ̀lú àbámọ̀ tó jinlẹ̀ pé a ti fi àìmọ̀ gba pípé Ìjọ Olúwa ní àwọn orúkọ míràn mọ́ra, ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí tí ó mú orúkọ mímọ́ Jésù Krístì kúrò!

Ọjọọjọ́ Ìsinmi bí a ṣe nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ, à nṣe ìlérí mímọ́ ní ọ̀tun sí Bàbá wa Ọ̀run pé à nfẹ́ láti gbé orúkọ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì lé orí ara wa.8 A ṣèlérí láti tẹ̀lé E, ronúpìwàdà, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, kí a si rańtí Rẹ̀ nígbàgbogbo

Nígbàtí a bá fo orúkọ Rẹ̀ kúró nínú Ìjọ Rẹ, à nfi ìfaramọ́ mú U kúrò bí ọ̀gangan ìdojúkọ ìgbé ayé wa.

Gbígbé orúkọ Olùgbàlà lé orí wa pẹ̀lú kíkéde àti jíjẹ́ẹ̀rí sí àwọn ẹlòmíràn—nípa ìṣe àti àwọn ọ̀rọ̀ wa—pé Jésù ni Krístì. Ṣe a ti níbẹ̀rù gidi láti ṣe àṣìṣe sí ẹnìkan tí ó pè wá ní “Mọ́rmọ́nì” tí a kùnà láti gbèjà Olùgbàlà Fúnrarẹ̀, láti díde sókè fún Un àní nínú orúkọ èyítí à npe Ìjọ?

Tí àwà bí ènìyàn kan àti bí ẹnìkọ̀ọ̀kan bá ní ààyè sí agbára Ètùtù jésù Krístì—láti wẹ̀ àti láti wò wá sàn, láti gbéga àti láti fún wa ni ókun, àti nígbẹ̀hìn láti mú wa yege—a gbọ́dọ̀ dá A mọ̀ dáadáa bí orisun agbára náà. A lè bẹ̀rẹ̀ nípa pipe Ìjọ Rẹ̀ nípa orúkọ̀ tí Òun ti pàṣẹ.

Fún ọ̀pọ̀ àwọn aráyé, Ìjọ Olúwa lọ́wọ́lọ́wọ́ nfarapamọ́ bi “Ìjọ Mọ́rmọ́nì.” Ṣùgbọ́n àwa bí ọmọ-ìjọ, Ìjọ Olúwa mọ ẹni tí ó dúro ní orí rẹ̀: Jésù Krístì Fúnrarẹ̀. Láìlóríre, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà Mọ́rmọ́nì lè rò pé à nsin Mọ́rmọ́nì. Kò rí bẹ́ẹ̀! À nbu ọlá àti ọ̀wọ̀ fún wòlíì àtijọ́ Amẹ́ríkà náà ni.9 Ṣùgbọ́n a kìí ṣe ọmọẹ̀hìn Mọ́rmọnì. Olùgbọ̀wọ́ Ti Olúwa Ni a jẹ́

Ní àwọn ọjọ́ ìṣíwájú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ, wọ́n sọ irú ọ̀rọ̀ bíi Ìjọ Mọ́rmọ́nì àti Àwọn Mọ́rmọ́nì10 ni wọ́n nlò bí ìtàbùkù—bí àwọn ọ̀rọ̀ ìkà, àwọn ọ̀rọ̀ ìbúni—tí wọ́n ṣe láti pa ọwọ́ Ọlọ́run rẹ́ ní mímú Ìjọ Jésù.11

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àwọn ìjiyàn ayé púpọ̀ wa lórí mímú orúkọ tòótọ́ ti Ìjọ padàbọ̀sípò. Nítorí ayé ìgbàlódé nínú èyí tí à ngbé, àti pẹ̀lú ẹ̀rọ ìwákiri ohunrere tí ó nràn gbogbo wa lọ́wọ́ láti rí ìwífúnni tí a nílò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀—pẹ̀lú ìwífúnni nípa Ìjọ Olúwa—àwọn ọlọfintoto sọ pé àtúnkọ ní àkokò yí kò mọ́gbọ́n wá. Àwọn ẹlòmíràn rò pé nítorí wọ́n ti mọ̀ wá káàkiri bí “Mọ́rmọ́nì” àti bí “Ìjọ Mọ́rmọ́nì,” a gbọ́dọ̀ lòó dáradára.

Tí èyí bá jẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ nípa títún ìṣètò àtọwádá kan ṣe, àwọn ijiyàn wọnnì lè dúró. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn pàtàkì yí, à nwò Ó ẹnití Ìjọ yí nṣe tirẹ̀ a sì damọ̀ pé àwọn ọ̀nà Olúwa kìí ṣe, kò sì ni jẹ́, ọ̀nà ènìyàn láéláé. Tí a ó bá fi sùúrù sa ipá wa dáradára, Olúwa yíò darí wa nípa iṣẹ́ pàtàkì yí. Bẹ́ẹ̀náà, a mọ̀ pé Olúwa nṣèrànwọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n nwá láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, gẹ́gẹ́bí Ó ti ran Nífáì lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí iṣẹ́ kíkọ́ ọkọ̀ ojú omi láti dá òkun kọjá.12

A ó fẹ́ láti níwàrere àti sùúrù nínú ìtiraka wa láti tún àwọn àṣìṣe wọ̀nyí ṣe. Awọn oníròhìn to wúlò yíò níkẹdùn ní fífèsì sí ìbèèrè wa.

Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tẹ́lẹ̀, Alàgbà Benjamín De Hoyos sọ̀rọ̀ nípa irú ìṣẹ̀lẹ̀ kannáà. Ó sọ:

Ọdún díẹ̀ sẹ́hìn nígbàtí mò nsìn ní ibi iṣẹ́ àwọn ètò gbàngbà Ijọ ní Mexico, wọn pe [ojúgbà kan àti èmi] wá láti kópa nínú eré ọ̀rọ̀ asọ̀rọ̀mágbèsì . … [Ọ̀kan lára àwọn olùdarí ètò náà] bèèrè lọ́wọ́ [wa], ‘Kínìdí tí Ìjọ fi ní orúkọ gígùn bẹ́ẹ̀? …

“Ojúgbà mi àti èmi rẹrin ní irú ìbèèrè gígajùlọ bẹ́ẹ̀ a sì tẹ̀síwájú nígbànáà láti ṣàlàyé pé kìí ṣe enìyàn ni ó yan orúkọ Ìjọ. Olùgbàlà ni ó fúnni. … Olùdarí ètò lọ́gán àtì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ fèsì, ‘Àwa ó tunsọ pẹ̀lú ìdùnnú.’”13

Ìròhìn náà pèsè àwoṣe kan. Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ìtiraka wa tó dárajùlọ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan yíò gba láti tún àwọn àṣìṣe wa ṣe tí ó tì wọlé ní ọ̀pọ̀ ọdún.14 Ìyókù aráyé lè tàbí lè má tẹ̀lé ìdarí wa ní pipe wa ní orúkọ tótọ́. Ṣùgbọ́n kò nítumọ̀ fún wa láti nídàmú tí púpọ̀jù nínú ayé bá npe Ìjọ àti àwọn ọmọ-ìjọ ní orúkọ̀ tí kòtọ́ tí àwa náà bá nṣe bẹ́ẹ̀.

Ètò ìtọ́nisọ́nà ìyípadà ṣèrànwọ́. Ó sọ wípé: “Nínú ìtọ́kasí àkọ́kọ́, orúkọ Ìjọ ní kíkún dára: ‘Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.’ Nígbàtí a nílò ìkàsí ìkékúrú [kejì], ọ̀rọ̀ náà ‘Ijọ’ tàbí ‘Ìjọ Jésù Krístì’ tọ́nà. Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Jésù Krístì bákannáà tọ́nà dáadáa.”15

Tí ẹnìkan bá bèèrè, “Ṣe Mọ́rmọ́nì ni ọ?” o lè dáhùn, “Tí o bá nbèèrè tí mo bá jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, bẹ́ẹ̀ni, mo jẹ́!?

Tí ẹnìkan bá bèèrè, “Ṣe Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni yín?”16 ẹ lè fèsì, “Bẹ́ẹ̀ni, mo je̩.”

Ẹ̀yin àyànfẹ́ arábìnrin àti arákùnrin mi, mo ṣèlérí fún yín pé tí a ó bá sa ipá wa láti mú orúkọ Ìjọ tòọ́tọ́ padàbọ̀sípò, ẹnití Ìjọ yí íṣe Tirẹ̀ yíò da agbára àti ìbùkún Rẹ̀ sílẹ̀ lé orí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn,17 the likes of which we have never seen.irú èyí tí a kò rírí. A ó ní ìmọ̀ àti agbára Ọlọ́run láti rànwálọ́wọ́ láti gba àwọn ìbùkún ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn àti láti múra ayé sílẹ̀ fún Ìpadabọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì.

Nítorínáà, kíló wa nínú orúkọ? Nígbàtí ó bá di orúkọ Ìjọ Oluwa, ìdáhùn ni “Ohun gbogbo!” Jésù Krístì darí wa láti pe Ìjọ ní orúkọ Rẹ̀ nítorí Ìjọ Rẹ̀ ni, ó sì kún fún agbára Rẹ̀.

Mo mọ̀ pé Ọlọ́run wà láàyè. Jésù ni Krístì. Ó ndarí Ìjọ Rẹ̀ loni. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. “The Lord has impressed upon my mind the importance of the name He has revealed for His Church, even The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints. We have work before us to bring ourselves in harmony with His will. In recent weeks, various Church leaders and departments have initiated the necessary steps to do so. Additional information about this important matter will be made available in the coming months” (Russell M. Nelson, in “The Name of the Church” [official statement, Aug. 16, 2018], mormonnewsroom.org).

  2. Preceding Presidents of the Church have made similar requests. Fún àpẹrẹ, Ààrẹ George Albert Smith said: “Don’t let the Lord down by calling this the Mormon Church. He didn’t call it the Mormon Church” (in Conference Report, Apr. 1948, 160).

  3. Wo “Style Guide—The Name of the Church,” mormonnewsroom.org.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 115:4.

  5. 3 Nephi 27:7–8.

  6. Wo Moses 1:33.

  7. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:18.

  8. Wo Moroni 4:3; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:37, 77.

  9. Mormon was one of the four major writers of the Book of Mormon, the others being Nephi, Jacob, and Moroni. All were eyewitnesses of the Lord, as was its inspired translator, the Prophet Joseph Smith.

  10. Even the word Mormonites was among terms of derision that were employed (see History of the Church, 2:62–63, 126).

  11. Other epithets seem to have occurred in New Testament times. During the Apostle Paul’s trial before Felix, Paul was said to be “a ringleader of the sect of the Nazarenes” (Acts 24:5). Regarding the use of the phrase “of the Nazarenes,” one commentator wrote: “This was the name usually given to Christians by way of contempt. They were so called because Jesus was of Nazareth” (Albert Barnes, Notes, Explanatory and Practical, on the Acts of the Apostles [1937], 313).

    Similarly, another commentary states: “As our Lord was contemptuously called ‘The Nazarene’ (Matt. xxvi. 71), so the Jews designated his disciples ‘Nazarenes.’ They would not admit that they were Christians, i.e. disciples of the Messiah” (The Pulpit Commentary: The Acts of the Apostles, ed. H. D. M. Spence and Joseph S. Exell [1884], 2:231).

    In a related vein, Elder Neal A. Maxwell observed: “Throughout scriptural history, we see recurring efforts to demean prophets in order to dismiss them—to label them in order to diminish them. Mostly, however, they are simply ignored by their contemporaries and by secular history. After all, early Christians were merely called ‘the sect of the Nazarenes.’ (Acts 24:5.)” (“Out of Obscurity,” Ensign, Nov. 1984, 10).

  12. See 1 Nephi 18:1–2.

  13. Benjamín De Hoyos, “Called to Be Saints,” Liahona, May 2011, 106.

  14. While we have no control over what other people may call us, we are in complete control over how we refer to ourselves. How can we expect others to honor the correct name of the Church if we as its members fail to do so?

  15. Style Guide—The Name of the Church,” mormonnewsroom.org.

  16. The term saint is used often in the Holy Bible. In Paul’s Epistle to the Ephesians, for example, he used the word saint at least once in every chapter. A saint is a person who believes in Jesus Christ and strives to follow Him.

  17. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:41