2022
Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì
Oṣù Kẹ́jọ 2022


“Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2022

“Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì”

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́jọ 2022

Ìwé-orin Dáfídì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì

Àwòrán
Dáfídì pẹ̀lú fère kan

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Àwọn Ìwé-orin Dáfídì jẹ́ àwọn orin mímọ́. Àwọn ènìyàn inú Bíbélì kọ àwọn ìwé-orin làti yin Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ìwé-orin Dáfídì kọ́ni nípa Jésù Krístì. Nihin ni àwọn ohun tí díẹ̀ lára àwọn ìwé-orin Dáfídì látinú Bíbélì kọ́ni.

Àwòrán
Jésù Krístì Dúrò lórí àpáta kan

Mo fẹ́ràn Olúwa. Òun ni àpàta àti okun mi. Èmi yíò gbẹ́kẹ̀lé E. Èmi yíò yìn Ín.

Àwòrán
Jésù Krístì di àgùntàn kan mú

Olúwa Ni Olùṣọ́-àgùntàn Mi. Ó ndarí mi lọ síbi àwọn ọdán aláwọ̀-ewé. Ó ndarí mi lọ síbi omi jẹ́jẹ́. Èmi kò ní bẹ̀rù.

Àwòrán
Jésù Krístì di fìtílà kan mú

Olúwa Ni Ìmọ́lẹ̀ Mi Èmi kì yíò bẹ̀rù. Èmi ó ní ìgboyà. Òun yíò mú ọkàn mi le.

Àwòrán
àwọn ènìyàn ni ilé ìjọsìn

Mo fẹ́ràn Jésù Krístì, Óun sì fẹ́ràn mi. Èmi lè yìn Ín nígbàtí mò nkọ́ tí mo sì nkọrin nípa Rẹ̀.

Kíkùn Ojú-ewé

Olúwa Ni Olùsọ́-àgùtàn Mi

Àwòrán
Jésù Krístì gbé ọ̀dọ́-àgùtàn kan

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Báwo ni ẹ ṣe nní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti Jésù?