2023
Àwọn Ohun-èlò fún Àwọn Ọ̀dọ́ àti àwọn Ọmọdé
Oṣù Kejì 2023


“Àwọn Ohun-èlò fún Àwọn Ọ̀dọ́ àti àwọn Ọmọdé,” Làìhónà, Oṣù Kejì 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kejì 2023

Àwọn Ohun-èlò fún Àwọn Ọ̀dọ́ àti àwọn Ọmọdé

Àwòrán
àwọn òbí nka àwọn ìwé-mímọ́ pẹ̀lú ọmọkùnrin

Àwọn òbí ní kókó ojúṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní àwọn ìṣètò, àwọn ètò, àti àwọn ohun-èlò láti ran àwọn òbí lọ́wọ́ nínú ìlàkàkà wọn. Lápapọ̀, àwọn òbí, àwọn olórí Ìjọ, àti àwọn ọ̀rẹ́ le ran gbogbo àwọn ọmọdé àti àwọn èwe lọ́wọ́ láti wá sọ́dọ̀ Krístì.

Àwòrán
Àwọn ọmọ àkọ́bẹ̀rẹ̀

Àwòrán láti ọwọ́ Ben Johnson

Àkọ́bẹ̀rẹ̀

Àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni ìṣètò Ìjọ fún àwọn ọmọdé ọjọ́ orí oṣù méjìdínlógún sí ọdún mọ́kànlá. Nínú Àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọdé nkọ́ nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́. Orin, àti àwọn ohun ṣíṣe. Àkọ́bẹ̀rẹ̀ lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún wọn.

Àwọn Iyejù Oyèàlùfáà Árọ́nì, àti Kíláàsì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin

Ní Oṣù Kínní ọdún tí àwọn ọmọdé bá pé ọdún méjìlá wọn á kúrò láti Àkọ́bẹ̀rẹ̀ lọ sí bóyá àwọn iyejù Oyèàlùfáà Árọ́nì (fún àwọn ọmọkùnrin) tàbí kíláàsì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin (fún àwọn ọmọbìnrin). Nínú àwọn iyejú àti kíláàsì wọn, àwọn ọ̀dọ́ ntẹ̀síwájú láti fún ẹ̀rí wọn láti sin àwọn ẹlòmíràn lókun.

Àwòrán
àwọn ọwọ́ nya àwòrán kan

Ètò àwọn Ọmọdé àti àwọn Ọ̀dọ́

Nígbà ọ̀dọ́ Rẹ, Jésù Krístì dàgbà “nínú ọgbọ́n àti ìnàsókè, àti nínú ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run àti ènìyàn” (Luku 2:52). Ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ nran àwọn ọ̀dọ́ ọmọ Ìjọ lọ́wọ́ láti tẹ̀lé àpẹrẹ Krístì. Wọ́n nkọ́ ẹ̀kọ́ wọ́n sì ndàgbà nínú gbogbo abala ìgbé ayé wọn—ní ti-ẹ̀mí, ní ti-ìbákẹ́gbẹ́, ní ti-ara, àti ní ti-òye.

Àwọn Ìwé Ìròhìn Ìjọ

Ìwé Ìròhìn Ìjọ fún àwọn ọmọdé ni ìwé ìròhìn Fríẹ́ndì. Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ ni ìwé ìròhìn fún àwọn ọ̀dọ́. Àwọn ìwé-ìròhìn wọ̀nyí ní àwọn ìtàn, àwọn ìkọ́ni, àti àwọn oun ṣíṣe nínú tí a kọ nípàtàkì fún àwọn ọmọdé àti àwọn èwe.

Àwòrán
Ẹhìn ìwé-ìtọ́nisọ́nà ní Spanish

Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ Ìwé-ìtọ́nisọ́nà

Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́nisọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn nkọ́ àwọn ọ̀dọ́ nípa àwọn òtítọ́ ìhìnrere. Ó nkọ́ wọn bí wọn ó ti ṣe àwọn ìpinnu tí yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Bákannáà ó ní àwọn ìdáhùn nínú sí àwọn ìbèèrè tí àwọn ọ̀dọ́ lè ní nípa bí wọ́n ti lè gbé ìgbé ayé ìhìnrere.

Ibi Ìkàwé Ìhìnrere

Ibi Ìkàwé Ìhìnrere ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ohun-èlò díjítà, nínú èyítí àwọn fídíò, orin, àwọn ìtàn inú ìwé-mímọ́, àti àwọn ohun síṣe. Bákannáà ó ní àwọn ohun-èlò láti ran àwọn òbí àti àwọn olórí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ìhìnrere. Àwọn ohun-èlò wọ̀nyí ni a lè rí nínú Ibi Íkàwé Ìhìnrere ní ChurchofJesusChrist.org àti nínú áàpù Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.

Àwọn Ìpàdé Àpapọ̀ FOO

Bíbẹ̀rẹ̀ nínú ọdún tí wọ́n bá pé ọdún mẹ́rìnlá àwọn ọ̀dọ́ ni a npè láti wà níbi àwọn ìpàdé àpapọ̀ (FOO) Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí àwọn ohun ṣíṣe àti kíláàsì nínú tí ó nṣèrànwọ́ láti fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì lókún àti láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti dàgbà níti-ẹ̀mí, níti-ìbákẹ́gbẹ́, níti-ara, àti níti-òye.