2023
Jésù Wo Obìnrin kan Sàn
Oṣù Kejì 2023


“Jésù Wo Obìnrin kan Sàn,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2023

“Jésù Wo Obìnrin kan Sàn”

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2023

Jésù Wo Obìnrin kan Sàn

Àwòrán
Jésù nrìn lọ sísàlẹ̀ òpópónà kan

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ní ọjọ́ kan Jésù rìn lọ sí ìsàlẹ̀ òpópónà kíkún kan. Nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀-èrò ni obìnrin kan wà tí ó ti nṣàárẹ̀ fún ọdún méjìlá.

Àwòrán
obìnrin nfọwọ́kan ẹ̀wù Jésù

Obìnrin náà ní ìgbàgbọ́ pé Jésù lè wò ó sàn. Ó nawọ́ jáde ó si fọwọ́kan aṣọ Rẹ̀. Lọ́gán ó gba ìwòsàn!

Àwòrán
Jésù Krístì

“Tani ó fọwọ́kan aṣọ mi?” Jésù bèèrè. Ẹ̀rù ba obìrin náà. Ó kúnlẹ̀ ní iwájú Jésù ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Ún.

Àwòrán
Jésù nsọ̀rọ̀ sí obìnrin kan

Jésù jẹ́ olùfẹ́ni. Ó wípé, “Tújúká.” Ó wí fún pé ó gba ìwòsàn nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Àwòrán
àwọn ọmọdé nínú ọkọ̀-ojú omi kan

Èmi lè ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Ìfẹ́ Rẹ̀ lè ràn mí lọ́wọ́ kí ó sì mú àláfíà wá fún mi.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Krístì

Àwòrán
ìyà àti ọmọkùnrin ngbàdúrà

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Báwo ni ẹ ti nfì ìgbàgbọ́ yín hàn?