2023
Ẹ̀mí Mímọ́ Lè Ràn Wá Lọ́wọ́
Oṣù Kẹfà 2023


“Ẹ̀mí Mímọ́ Lè Ràn Wá Lọ́wọ́,” Làìhónà, Oṣù Kẹfà 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹfà 2023

Ẹ̀mí Mímọ́ Lè Ràn Wá Lọ́wọ́

Àwòrán
Ọkùnrin njoko ó sì nwo yíyọ-òrùn kan

Ẹmí Mímọ́ ni ẹni kẹta ti Àjọ-Olórí-Ọlọ́run. Àwọn ìwé mímọ́ bákannáà tọ́ka sí I bí Ẹ̀mí, Ẹ̀mí Mímọ́, tàbí Olùtùnú. Bí a ti nkọ́ láti fetísílẹ̀ sí ohùn Rẹ̀, Òun ó jẹri sí wa nípa Jésù Krístì yíò sì ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn òtítọ́ ìhìnrere.

Ara-Àjọ-Olórí-Ọlọ́run

Baba Ọ̀run, Jésù Krístì, àti Ẹ̀mí Mímọ́ ni Àjọ-Olórí-Ọlọ́run Wọ́n nífẹ wa wọ́n sì nṣiṣẹ́ láti mú ètò ìgbàlà wá sí ìmúṣẹ. Bíótilẹ̀jẹ́pé Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ní àwọn àgọ́ ara ti ẹran ara àti egungun, Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní. Ó jẹ́ ẹ̀mí kan.

Àwòrán
Àwòrán jígí-kedere ti Baba àti Ọmọ

Ẹlẹ́ri ti Bàbá àti Ọmọ.

Ẹ̀mí Mímọ́. “Njẹri Baba àti Ọmọ” (2 Nefi 31:18). Èyí túmọ̀sí pé a lè gba ẹ̀rí kan nípa Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

Ó njẹri Òtítọ́

Ẹ̀mí Mímọ́ njẹri gbogbo òtítọ́. Òun yíò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ìhìnrere—pẹ̀lú ètò ìgbàlà, awọn òfin Ọlọ́rún, Ìmúpadàbọ̀sípò, àti Ètùtù Jésù Krístì—jẹ́ òtítọ́. Òun yíò fún ẹrí wa lókun bí a ti ntẹ̀síwájú láti máa gbàdúrà, pa àwọn òfin mọ́, àti ṣíṣe àṣàrò ìhìnrere.

Àwòrán
ọwọ́ ndi atọ́nà kan mú

Ó Ntọ́ Wa Sọ́nà ó sì Ndá Ààbò Bò Wá

Ẹ̀mí Mímọ́ lè tọ́wasọ́nà nínú àwọn ìpinnu wa kí ó sì dá ààbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ewu àfojúrí àti ti-ẹ̀mí. Òun yíò ràn wá lọ́wọ́ láti wá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè wa bí a bá gbàdúrà tí a sì gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó tọ́. Òun ó darí wa nígbàgbogbo “láti ṣe rere” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 11:12).

Ntù Wá Nínú

Ẹ̀mí Mímọ́ ni à ntọ́kasí nígbàmíràn bí “Olùtùnú” (Jòhánù14:26). Òun lè kún inú wa “pẹ̀lú ìrètí àti ìfẹ́ pípé” (Mórónì 8:26) nígbàtí a bá ndàmú, nbanújẹ́, tàbí nbẹ̀rù. Bí Ó ti nràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run, a lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì kí a sì gba okun nínú àwọn àdánwò wa.

Ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Lẹ́hìn tí a bá ṣe ìrìbọmi, a ó gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ìlànà kan tí à pè ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀. Nígbàtí a bá ti gba ẹ̀bùn yí, a lè ní ojúgbà Ẹ̀mí Mímọ́ léralérá níwọ̀n ìgbà tí a bá ngbé ìgbé-ayé òdodo.

Àwòrán
obìnrin nka àwọn ìwé-mímọ́

Ìjúwe láti ọwọ́ J. Kirk Richards

Bí A Ti Ngbọ́ Ti Ẹ̀mí Mímọ́

Ẹ̀mí Mímọ́ nbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwọ̀nyí lè ní àláfíà, àwọn ìmọ̀lára títuni-nínú tàbí àwọn òye nípa ohun láti sọ tàbí ṣe. Bí a ti ngbàdúrà fún ìtọ́nisọ́nà tí a sì nfetísílẹ̀ fún àwọn ìṣíniléti Rẹ̀, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ bí Ó ṣe nsọ̀rọ̀ sí wa.