2023
Oúnjẹ Olúwa Ìkínní
Oṣù Kẹfà 2023


“Oúnjẹ Olúwa Ìkínní,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹfà 2023, 46–47.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù kẹfà 2023

Àwọn Ìtàn Ìwé Mímọ́

Oúnjẹ Olúwa Ìkínní

Àwòrán
Jésù joko ní ibi tábìlì pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀

Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ṣíwájú kí Ó tó kú, Jésù Krístì pàdé pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀. Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa.

Àwòrán
Jésù ndi búrẹ́dì mú

Jésù já búrẹ́dì ó sì fi fún wọn. Ó ní kí wọn jẹ ẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún wọn láti rántí pé Òun fi ẹ̀mí Rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn.

Àwòrán
Jésù ndi ago mú

Nígbànáà Jésù fún wọn ní ago kan. Ó ni kí wọ́n mu nínú rẹ̀. Yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí Rẹ̀ bákannáà.

Àwòrán
Àwọn Krístẹ́nì ìṣíwájú njẹ oúnjẹ Olúwa

Àní lẹ́hìn tí Jésù kò sí pẹ́lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀ mọ́, oúnjẹ Olúwa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ronú nípa Rẹ̀. Wọn lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ kí wọ́n sì rántí láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo Lè Jẹ Oúnjẹ Olúwa

Àwòrán
Ọmọdékùnrin njẹ oúnjẹ Olúwa

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Nígbàtí mo bá jẹ́ oúnjẹ Olúwa, mo lè rántí Jésù àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún mi.