2023
Ìṣètò Ìjọ Jésù Krístì
Oṣù Kẹwa 2023


“Ìṣètò Ìjọ Jésù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kẹwa, 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹwa 2023

Ìṣètò Ìjọ ti Jésù Krístì

Àwòrán
àwòrán Jésù Krístì

Olúwa Jésù Krístì, láti ọwọ́ Del Parson

Jésù Krístì ni olórí Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn. Ó nmísí àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì láti darí Ìjọ ní òní, bí Ó ti ṣe ní àwọn ìgbà Májẹ̀mú Titun. A nràn wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn olórí Ìjọ.

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ Ìjọ Olùgbàlà. O jẹ́ “kíkọ́ lé orí ìpìlẹ̀ àwọn àpóstélì àti àwọn wòlíì, tí Jésù Krístì fúnrarẹ̀ jẹ́ pàtàkì òkúta igun ilé” (Éfésù 2:20). Èyí túmọ̀ sí pé Òun ni apákan pàtàkì jùlọ ti ìpìlẹ̀ náà. Ó ntọ́ Ìjọ sọ́nà nípasẹ̀ àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì tí Ó ti yàn láti jẹ́ àwọn olórí.

Àwòrán
Àjọ Áarẹ Ìkínní

Àjọ Ààrẹ Ìkínní Náà

Ààrẹ Ìjọ ni wòlíì Ọlọ́run lórí ilẹ̀-ayé loni. Òun ni Àpóstélì àgbà àti ẹnìkanṣoṣo lórí ilẹ̀-ayé tí ó ngba ìfihàn láti tọ́ gbogbo Ìjọ sọ́nà. Olúwa nmísí i láti mọ àwọn Àpóstélì méjì èyí tí yíò pè láti sìn bí àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀. Wọ́n di Àjọ Ààrẹ Ìkínní. Gbogbo àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wòlíì, aríran, àti olùfihàn.

Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá

Àwọn ọmọ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá jẹ́ wòlíì, aríran, àti olùfihàn bákannáà. A pè wọ́n láti jẹ́ àwọn ẹlẹri pàtàkì ti Jésù Krístì. Wọ́n nrin ìrìnàjò káàkiri ayé láti kọ́ni àti láti jẹri nípa Rẹ̀. (Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:32, 33).

Àwọn Iyejú ti Àádọ́rin

Àwọn ọmọ Iyejú ti Àádọ́rin ni a pè bí ẹlẹri Jésù Krístì bákannáà (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:25). Wọ́n nran Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá lọ́wọ́ láti kọ́ni ní ìhìnrere àti láti gbé Ìjọ ga káàkiri àgbáyé.

Àwòrán
àwọn olórí ndámọ̀ràn papọ̀

Àwòrán láti ọwọ́ Machiko Horii

Àwọn Olórí Ìbílẹ̀

Àjọ ààrẹ èèkàn tàbí ẹ̀kùn, bìṣọ́príkì tàbí àjọ̀ ààrẹ ẹ̀ka, àti àwọn àjọ̀ ààrẹ iyejú àwọn alàgbà àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ni a ti pè bákannáà láti ọwọ́ Ọlọ́run. Wọ́n lè ràn yín lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere. Ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa díẹ̀ lára àwọn ìpè wọ̀nyí nínú àtẹ̀kọ Àwọn Kókó Ìhìnrere, Oṣù Kẹta 2022, “Sísìn nínú àwọn Ìpè Ìjọ.”