Làìhónà
Olùgbàlà ti Ẹni Gbogbo, Ìhìnrere kan fún Ẹni Gbogbo
Oṣù Kẹta 2024


“Olùgbàlà ti Ẹni Gbogbo, Ìhìnrere kan fún Ẹni Gbogbo,” Làìhónà, Oṣù Kẹta 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣoòṣù Làìhónà , Oṣù Kẹta 2024

Olùgbàlà ti Ẹni Gbogbo, Ìhìnrere kan fún Ẹni Gbogbo

Ìhìnrere, Ètùtù, àti Àjínde Jésù Krístì nbùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Àwòrán
Krístì àti ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà

Krístì àti Ọkùnrin Alárùn Ẹ̀gbà, láti ọwọ́ J. Kirk Richards, a kò lè ṣe ẹ̀dà

Ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò, ní àkọ́kọ́, ní ti ìṣaájú, àti títí láé, jẹ́ orísun ìdùnnú pípẹ́, àláfíà tòótọ́, àti ayọ̀ fún gbogbo ènìyàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. Àwọn ìbùkún tí ó nṣàn láti inú ìhìnrere àti láti inú iṣerere àìlódiwọ̀n Krístì kò wà fún àwọn àṣàyàn díẹ̀ nìkan, ní àwọn ìgbà àtijọ́ tàbí ní òde òní.

Bí ó ti wù kí a lè ní ìmọ̀lára àìkún-ojú ìwọ́n tó, àti láìka àwọn ẹ̀ṣẹ̀ sí tí ó lè mú wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ Rẹ̀ fún àkokò kan, Olùgbàlà wa fi dá wa lójú pé “òun nna ọwọ́ rẹ̀ jáde sí [wa] ní gbogbo ọjọ́” (Jákọ́bù 6:4), ní pípè gbogbo wa láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí a sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀.

Àwọn Ìbùkún Ìhìnrere fún Gbogbo Aráyé

Ìhìnrere Jésù Krístì ni a ti “múpadàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí láti bá … àwọn àìní gbogbo orílẹ̀ èdè, ìbátan, ahọ́n, àti àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé pàdé.”1 Ìhìnrere náà tayọ gbogbo jíjẹ́ ti orílẹ̀ èdè àti àwọ̀ nígbàtí ó la gbogbo àwọn ilà àṣà kọjá láti kọ́ni pé “ẹni gbogbo rí bákannáà sí Ọlọ́run” (2 Nefi 26:33).2 Ìwé ti Mọ́mọ́nì dúró bí ẹ̀rí kan tí ó lápẹrẹ nípa òtítọ́ yí.

Àkọsílẹ̀ nlá yí jẹri pé Krístì nrántí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè (wo 2 Nefi 29:7) yíó sì fi “ara rẹ̀ hàn sí gbogbo àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú rẹ̀, … [yíò sì ṣe] àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá, àwọn àmì, àti àwọn ohun yíyanilẹ́nu, ní àárín àwọn ọmọ ènìyàn” (2 Nefi 26:13). Ní àárín àwọn iṣẹ́ ìyànu nlá wọ̀nyí, àwọn àmì, àti àwọn ohun yíyanilẹ́nu ní ìtànkálẹ̀ ìhìnrere. Nítorínáà, a rán àwọn ìránṣẹ ìhìnrere káàkiri ayé láti jẹri nípa ìròhìn rere rẹ̀. Bákannáà a npín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn wọnnì ní àyíká wa. Lílo àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà tí a múpadàbọ̀sípò fún alààyè àti òkú nmú dájú pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere yíò wà ní àrọ́wọ́tó nígbẹ̀hìn fún gbogbo ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àwọn òbí wa ọ̀run—tó ti kọjá, ti ìsisìyí, tàbí ti ọjọ́ iwájú.

Ọkàn ìhìnrere yí—gbùngbun ọ̀rọ̀ gbogbo wòlíì àti àpọ́stélì tí a ti pè rí sí iṣẹ́ náà—ni pé Jésù ni Krístì àti pé Ó wá láti bùkún gbogbo ènìyàn. Àwa gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, a kéde pé ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo aráyé.

Ìnílò fún Ètùtù Àìlópin àti ti Ayérayé

Bí mo ti nlọ kiri ayé, mo ṣe àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ìṣètò gbígbòòrò àwọn ọmọ Ìjọ. Mo ní ìmísí láti gbọ́ bí wọ́n ti nní ìmọ̀lára àwọn ìbùkún Ètùtù Jésù Krístì nínú ayé wọn, àní nígbàtí wọ́n njẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ to ti pẹ́. Ó ti yanilẹ́nu tó pé ìtùnú ìwẹ̀nùmọ́ ti Ètùtù Rẹ̀ nfi ìgbàgbogbo wà ní àrọ́wọ́tó sí gbogbo wa!

“Ètùtù kan gbọ́dọ̀ jẹ́ síṣe,” Amulek kéde, “bíkòjẹ́ bẹ́ẹ̀ gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣègbé láìleyẹ̀.” A ó di “ṣíṣubú àti … sísọnù títíláé, … bíkòṣe pé ó jẹ́ nípasẹ̀ ètùtù náà,” èyí tí ó bèèrè fún “ìrúbọ àìlópin àti ti ayérayé.” “Nítorítí kò le sí ohun kankan lẹ́hìn ètùtù àìlópin náà tí ó lè tó fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé” (Alma 34:9, 10, 12).

Wòlíì nlá náà Jákọ́bù bákannáà kọ́ni pé nítorípé “ikú ti wá sórí gbogbo ènìyàn, … ó di dandan kí agbára àjínde wà” láti mú wa wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (2 Nefi 9:6).

A nílò láti ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú pẹ̀lú. Èyí ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà, èyítí Ó fi ìgboyà parí fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Àwòrán
Krísti ní Gẹ́tsémánì

Gẹ́tsémánì, by J. Kirk Richards, a kò lè ṣe ẹ̀dà

Ìrúbọ Olùgbàlà Wa

Ní òru Rẹ̀ tí ó kẹ́hìn ní ayé ikú, Jésù Krístì wọnú Ọgbà Gẹ́tsémánì. Níbẹ̀, Ó kúnlẹ̀ ní àárín àwọn igi ólífì ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀kalẹ̀ sínú ìrora tí ẹ̀yin àti èmi kò lè mọ̀ láéláé.

Níbẹ̀, Ó bẹ̀rẹ̀ láti gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lé orí Ararẹ̀. Ó ní ìmọ̀lára ìrora, ìrora-ọkàn, àti ìbànújẹ́, Ó sì farada gbogbo ìpọ́njú àti ìjìyà tí a nní ìrírí rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀yin, èmi, àti gbogbo ọkàn tí wọ́n ti gbé rì tàbí tí yíò gbé rí. Ìjìyà nlá àti àìlópin yí “mú kí [Òun], … tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, láti gbọ̀nrìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:18). Òun nìkan ni ó lè ṣe èyí.

Kò sí òmíràn tí ó dára tó.

Láti san owó ẹ̀ṣẹ̀.

Òun nìkan ni ó lè ṣí ilẹ̀kùn.

Ti ọ̀run kí a lè wọlé.3

Jésù ni a mú lọ sí Calvary nígbànáà, àti ní àkokò àìdára búburú jùlọ nínú ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ayé yí, a kàn Án mọ́ àgbélèbú. Kò sí ẹnìkan tí ìbá lè gba ẹ̀mí Rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Rẹ̀. Bí Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo Ọlọ́run, Ó ní agbára lórí ikú ti ara. Òun ìbá ti gbàdúrà sí Baba Rẹ̀, àti pé àwọn lígíọ́nì àwọn ángẹ́lì ìbá ti wá láti pa àwọn aninilára Rẹ̀ rẹ́ kí wọ́n sì ṣàpèjúwe ìjọba Rẹ̀ lórí àwọn ohun gbogbo. “Ṣùgbọ́n nígbànáà báwo ni a ó ṣe mú àwọn ìwé mímọ́ ṣẹ,” Jésù bèèrè lọ́wọ́ ọ̀dàlẹ̀ Rẹ̀, “pé báyìí ni ó gbọ́dọ̀ rí?” (Matteu 26:54).

Nínú ìgbọràn pípé sí Baba Rẹ—àti ìfẹ́ pípé fún wa—Jésù fi tìfẹ́tìfẹ́ fúnni ní ẹ̀mí Rẹ ó sì parí ìrúbọ ètùtù ayérayé àti àìlópin Rẹ̀, èyí tí ó dé ẹ̀hìn ní àkokò àti síwájú la gbogbo ayérayé já.

Ìṣẹ́gun Olùgbàlà Wa

Jésù pàṣẹ fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ Rẹ̀ lẹ́hìn ikú Rẹ̀. Báwo ni wọn ó ti ṣe é? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn kàn jẹ́ apẹja lásán, àti pé kò sí ẹni tí a dálẹkọ nínú àwọn sínágọ́gù fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà. Ní àkokò náà, Ìjọ Krístì dàbí dídá fún píparẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn Àpóstélì rí okun láti gbé ìpè wọn àti láti tún ìtàn-àkọọ́lẹ̀ ayé ṣe.

Kíni ó nmú okun wá láti inú irú àìlera híhàn bẹ́ẹ̀? Olórí ìjọ anglican àti ọ̀mọ̀wé Frederic Farrar wípé: “Ọ̀kan wà, àti i`dáhùn kanṣoṣo tí ó ṣeéṣe ni—àjínde láti inú òkú. Gbogbo ìyára yíyíká jẹ́ nítorí agbára àjínde Krístì.”4 Gẹ́gẹ́bí àwọn ẹlẹri Olúwa tó jínde, àwọn Àpóstélì mọ̀ pé kò sí ohun tí ó lè dá iṣẹ́ yí dúró ní lílọsíwájú. Ẹ̀rí wọn jẹ́ orísun agbára ìmúdúró bí Ìjọ ìṣíwájú ṣe ṣẹ́gun gbogbo àwọn ìlòdì.

Nínú Ọdún Àjínde yí, bí ọ̀kan lára àwọn ẹlẹri Rẹ̀ tí a yàn, mo kéde pé ní òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi rírẹwà kan, Olúwa Jésù Krístì dìde kúrò nínú òkú láti fún wa lókun àti láti já àwọn ìdè ikú fún gbogbo ènìyàn. Jésù Krístì Wà Láàyè! Nítorí Rẹ, ikú kìí ṣe òpin wa. Àjínde ni ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ àti káríayé ti Krístì fún ẹni gbogbo.

Àwòrán
Krístì àti Mary Magdalene ní ibi ibojì

Krístì àti Mary ní ibi Ibojì, láti ọwọ́ Joseph Brickey

Wá sí ọ̀dọ̀ Krístì

Ìhìnrere àti Ètùtù Jésù Krístì wà fún gbogbo ènìyàn—èyí ni pé, olukúlùkù èníyàn. Ọ̀nà kanṣoṣo tí a fi nní ìrírí àwọn ìbùkún kíkún ìrúbọ ètùtù Olùgbàlà ni nípa títẹ́wọ́gba ìpè Rẹ̀ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan: “Wá sí ọ̀dọ̀ mi” (Matteu 11:28).

À nwá sí ọ̀dọ̀ Krístì bí a ti nlo ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ tí a sì nronúpìwàdà. À nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ bí a ti nrì wá bọmi ní orúkọ Rẹ̀ tí a sì ngba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. À nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ bí a ti npa àwọn òfin mọ́, gba àwọn ìlànà, bu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú, ṣe ìgbàmọ́ra àwọn ìrírí nínú tẹ́mpìlì, tí a sì ngbé irú ìgbé ayé tí àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì gbé.

Nígbàmíràn, ẹ lè dojúkọ ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìjákulẹ̀. Ẹ lè ní ìrora ọkàn fún ara yín tàbí ẹnìkan tí ẹ fẹ́ràn. Ẹ lè ní àjàgà nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn àṣìṣe tí ẹ ti ṣe—bóyá àwọn líle—lè mú kí ẹ bẹ̀rù pé àláfíà àti ìdùnnú tí fi yín sílẹ̀ títíláé. Ní irú àwọn ìgbà bẹ́ẹ̀, ẹ rántí pé Olùgbàlà kìí gbé àjàgà ẹ̀ṣẹ̀ sókè nìkan ṣùgbọ́n bákannáà “ó [ti] jìyà àwọn ìrora àti ìpọ́njú àti àdánwò onírurú” (Álmà 7:11), pẹ̀lú tiyín! Nítorí ohun tí Ó là kọjá fún yín, Ó mọ̀ fúnrarẹ̀ bí yíò ti ràn yín lọ́wọ́ bí ẹ ti ngba ìpè Rẹ̀ tó nyí ìgbé ayé padà: “Wá sí ọ̀dọ̀ mi.”

Ẹni Gbogbo Ló Káàbọ̀

Jésù Krístì ti mú un hàn kedere pé gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run ní ẹ̀tọ́ dídọ́gba lórí àwọn ìbùkún ìhìnrere àti Ètùtù Rẹ̀. Ó nrán wa létí pé gbogbo ènìyàn “ní ànfàní ní ọ̀kan bí òmíràn, a kò sí kà ọ̀kankan léèwọ̀” (2 Nefi 26:28).

“Ó pe gbogbo wọn láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n ó sì ní ìpín nínú oore rẹ̀; kò sì sẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, dúdú àti funfun, òndè àt òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin” (2 Nefi 26:33).

“Ó pe gbogbo wọn”—èyí túmọ̀ sí gbogbo wa! A kò níláti fi àwọn àlẹ̀mọ́ òfégè àti ìyàtọ̀ àfọwọ́dá lé orí ara wa tàbí àwọn míràn. A kò níláti fi ìdènà kankan sí ìfẹ́ Olúgbàlà tàbí fi àyè gba àwọn èrò pé àwa tàbí àwọn míràn kọjá àrọ́wọ́tó Rẹ̀. Bí mo ti wí tẹ́lẹ̀, “kò ṣeéṣe fún [ẹnikẹ́ni] láti ri wọlẹ̀ ju àwọn ìtànsán ìmọ́lẹ́ àìlópin ti Ètùtù Krístì lọ.”5

Dípò bẹ́ẹ̀, bí Arábìnrin Holland àti èmi ti kọ́ni ní nkan bíi oṣù díẹ̀ ṣíwájú kíkọjálọ rẹ̀, a pàṣẹ́ fún wá láti “ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́, ifẹ́ àìlẹ́gbẹ́ èyítí ó jẹ́ ìfẹ́” (2 Nefi 26:30).6 Èyí ni ìfẹ́ tí Olùgbàlà fihàn wá, nítorí “Òun kìí ṣe ohunkóhun bíkòṣe pé ó jẹ́ fún èrè aráyé; nítorí ó fẹ́ràn aráyé; àní tí ó fi fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ kí ó lè fa gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀” (2 Nefi 26:24).

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé ìhìnrere àti Ètùtù Jésù Krístì wà fún gbogbo ènìyàn. Mo gbàdúrà pé ẹ ó fi tayọ̀tayọ̀ gba àwọn ìbùkún tí Ó nmú wa mọ́ra.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Howard W. Hunter, “Ìhìnrere—Ìgbàgbọ́ Gbogbo Àgbáyé,” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Kọkànlá. 1991, 18.

  2. Wo Howard W. Hunter, “Ẹni Gbogbo Jẹ́ Bákannáà Sí Ọlọ́run” (Brigham Young University fireside, Feb. 4, 1979), 1–5, speeches.byu.edu.

  3. Òkè Aláwọ̀ Ewé Kan Wá Ọ̀ǹa Jíjín Réré,” Àwọn Orin Ìsìn, no. 194.

  4. Frederic W. Farrar, Ìgbé Ayé Krístì (1994), 656.

  5. Jeffrey R. Holland, “Àwọn Òṣìṣẹ́ Nínú Ọgbà Àjàrà,” Làìhónà, Oṣù Karun 2012, 33.

  6. Wo Jeffrey àti Patricia Holland, “Ọjọ́ Iwájú Kan Tí Ó Kún Fún Ìrètí” (ìfọkànsìn káríayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, Ọjọ́ Kẹ́jọ, Oṣù Kínní, 2023), broadcasts.ChurchofJesusChrist.org.