Làìhónà
Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù
Oṣù Kẹta 2024


“Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2024, 26–27.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2024

Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Jákọ́bù jẹ́ arákùnrin kékeré ti Néfì. A bí i lẹ́hìn tí ẹbí wọn kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Jákọ́bù wá sí ilẹ̀ ìlérí bí ọmọdé.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Jákọ́bù àti Néfì Rí Jésù. Wọ́n ṣe àbápín àwọn ẹ̀rí wọn pẹ̀lú ẹbí wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Jésù.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Wọ́n ṣe àbápín àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh pẹ̀lú. Ìsàíàh bákannáà tí rí Jésù ó sì kọ nípa Rẹ̀ nínú àwọn ìwé-mímọ́. Jákọ́bù àti Néfì lo àwọn ọ̀rọ̀ Ìsàíàh láti inú àwọn ìwé-mímọ́ láti kọ́ àwn ẹbí wọn nípa Jésù.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Wọ́n kọ́ni wípé Jésù yíò wá sí ilẹ̀-ayé. Òun yíò kú yíò sì yè lẹ́ẹ̀kansi. Wọ́n ṣe àbápín ẹ̀rí Jésù Krístì kí àwọn ẹbí wọn lè wo iwájú fún bíbọ̀ Rẹ̀.

Kíkùn Ojú-ewé

Jésù Ni Olùgbàlà Wa.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà nihin

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

Nígbàwo ni ẹ nní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti Jésù?