Làìhónà
Ẹ Bọ́ Ẹ̀mí Yín pẹ̀lú Àdúrà Lemọ́lemọ́
Oṣù Kẹrin 2024


“Ẹ Bọ́ Ẹ̀mí Yín pẹ̀lú Àdúrà Lemọ́lemọ́,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́rin 2024

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́rin 2024

Ẹ Bọ́ Ẹ̀mí Yín pẹ̀lú Àdúrà Lemọ́lemọ́

A nílò ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run, ìbùkún kan tí ó wà fún wa níbigbogbo àti nígbàgbogbo.

Àwòrán
Énọ́sì ngbàdúrà

Àwòrán òṣéré tí ó nfi Énọ́sì hàn láti ọwọ́ Matt Reier

Gbogbo wa ti ní ìmọ̀lára ìpebi tẹ́lẹ̀rí. Àwọn irọbi Ebi ni ọ̀nà tí ara fi nwí fún wa pé òun nílò ìṣìkẹ́. Àti pé nígbàtí ẹbi bá npa wa, a mọ ohun tí a níláti ṣe—jẹun.

Àwọn ẹ̀mí wa bákánnáà ní àwọn ọ̀nà jíjẹ́ kí a mọ ìgbàtí a nílò ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ó dàbí ẹnipé ó rọrùn fún wa láti pa ebi ti-ẹ̀mí tì lásán ju ebi ti-ara.

Gẹ́gẹ́bí onírurú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oúnjẹ ti wà ni a fi lè jẹun nígbàtí ebí bá npa wá. Fún àpẹrẹ, a lè “ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì” (2 Nefi 32:3) nínú àwọn ìwé-mímọ́ àti nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ áwọn wòlíì. A lè lọ sílé ìjọsìn déédé kí a sì ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:9). A lè sin Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ (wo Mòsíàh 2:17).

Ṣùgbọ́n orísun ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí míràn wà fún wa ní gbogbo ìgbà, ní gbogbo àkokò ti ìgbé-ayé wa, bí ó ti wù kí àwọn ipò wa rí. A lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run nígbàgbogbo nípasẹ̀ àdúrà.

“Ẹ̀mí Mi Kébi”

Bí wòlíì Énọ́sì ṣe ndọdẹ àwọn ẹrànko nínú ijù, ó ronú nípa “àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí [òun] sábà máa ngbọ́ tí baba [rẹ] nsọ nípa ìyè àìnípẹ̀kun, àti ayọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ ìwọ̀nyí “wọ ọkàn [rẹ̀] lọ jinlẹ̀jinlẹ̀” (Énọ́sì 1:3).

Nítorí Énọ́sì wà ní ipò inú ti-ẹ̀mí yí, ó ní ìmọ̀lára ìnílò líle: “Ẹ̀mí mi kébi,” ni ó wí (Énọ́sì 1:4; àtẹnumọ́ àfikún).

Kíni Énọ́sì ṣe nígbàtí ó ní ìmọ̀lára ìkébi ti-ẹ̀mí yí, ìnílò fún ìṣìkẹ́ ti ẹ̀mí yí? “Mo sì kúnlẹ̀ níwájú Ẹlẹ́da mi,” ó wípé, “mo sì kígbe pẽ nínú ọ̀pọ̀ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ tí ó lágbára fún ẹ̀mí ara mi” (Enos 1:4).

Títóbi gidi ni ìkébi ti-ẹ̀mí Énọ́sì tí ó fi gbàdúrà “ní gbogbo ọjọ́ … àti nígbàtí alẹ́ sì lẹ́ [ó] tún gbé ohùn [rẹ̀] sókè tí ó fi dé àwọn ọ̀run” (Énọ́sì 1:4). Nígbẹ̀hìn, Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ̀ Ó sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jìí. Énọ́sì ní ìmọ̀lára tí a wẹ ẹ̀bi rẹ̀ nù kúrò. Ṣùgbọ́n ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí rẹ̀ kò tán síbẹ̀.

Ó kọ́ nípa agbára ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ó sì tú gbogbo ọkàn rẹ̀ jáde ní ìtìlẹhìn àwọn ènìyàn rẹ̀—àní àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ó dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa ó si mú àwọn ìlérí rẹ̀ dúró láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Àti pé lẹ́hìn àdúrà alágbára Énọ́sì, ó lọ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ̀ ní sísọtẹ́lẹ̀ àti jijẹri nípa àwọn ohun tí ó ti gbọ́ tí ó sì ti rí. (Wo Énọ́sì 1:5-19.)

Kìí ṣe gbogbo àdúrà ni a ó gba ìdáhùn sí ní ọ̀nà àrà bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ìrírí wa pẹ̀lú àdúrà ṣì lè jẹ́ onítumọ̀ àti yíyí ìgbé ayé padà. A lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú ìrírí Énọ́sì pẹ̀lú àdúrà. Fún àpẹrẹ:

  • Títiraka láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere ní kíkún lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n ìkébi ti ẹ̀mí wa.

  • Ìkébi ti ẹ̀mí wa lè ó sì níláti mú wa wá sí orí eékún wa láti wá ìrànlọ́wọ́ Baba Ọ̀run.

  • Gbígbàdúrà sí Baba Ọ̀run lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ́ ìkébi ti ẹ̀mí wa lọ́rùn—àti àwọn kan nígbànáà.

  • A lè gbàdúrà níbikíbi, nígbàkugbà.

  • Àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà.

  • Àdúrà lè fún ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krístì lókun.

  • A lè gba ẹ̀rí ti araẹni kan pé Baba wa Ọ̀run ngbọ́ wa Ó sì ní ìfura nípa wa.

  • Ẹ̀rí àti okun tí a gbà nípasẹ̀ àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ láti sìn àti láti fún àwọn míràn lókun.

Àwòrán
Alàgbà Soares bí ọ̀dọ́mọdékùnrin kan

Ìrírí Mi pẹ̀lú Agbára Àdúrà

Bíiti Énọ́sì, mo kọ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kannáà nípasẹ̀ ìrírí araẹni. Àwọn òbí mi darapọ̀ mọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin, mo sì ṣe ìrìbọmi nígbàtí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ. Mo fi ìgbàgbogbo ní ìmọ̀lára ìyárí, rere nínú ọkàn mi nípa Baba mi Ọ̀run àti nípa Jésù Krístì, ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Rẹ̀, àti Ìjọ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìgbà tí mo tó fẹ́rẹ̀ di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mo tó gbàdúrà nípa òtítọ́ àwọn ohun wọ̀nyí.

Bíṣọ́ọ̀pù mi onimisi ní kí nkọ́ kílásì Ilé-ẹ̀kọ́ Ọjọ́-ìsinmi àwọn ọ̀dọ́ kan. Ó yẹ kí nkọ́ ẹ̀kọ́ kan nípa bí a ṣe lè jèrè ẹ̀rí nípa ìhìnrere nípa àdúrà. Yíyànsíṣẹ́ yí láti ọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀pù mi mú kí èmi ó ronú jìnlẹ̀ gidi nípa ẹ̀rí ti ara mi. Mo ti ní àkokò láti ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì mo sì nní ìmọ̀lára pé Ìjọ jẹ́ òtítọ́ nígbàgbogbo. Mo ti máa nní ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà Jésù Krístì nígbàgbogbo, ṣùgbọ́n èmì kò ì tíì fi ìlérí Mórónì sí ọkàn tí a rí ni Mórónì 10:4–5. Èmi kò ì tíì gbàdúrà nípa ti-òtítọ́ ìhìnrere rí.

Mo rántí ìmọ̀lára nínú ọkàn mi pé bí mo bá máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí bí wọn ó ti jéré ẹ̀rí kan nípasẹ̀ àdúrà, mo níláti gbàdúrà fún ẹ̀rí kan fún ara mi. Ẹ̀mí mi kébi—bóyá ní ọ̀nà míràn yàtọ̀ sí ti Énọ́sì, ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ èmi ní ìmọ̀lára ìnílò ti ẹ̀mí.

Bí mo ti nmúra ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, mo kúnlẹ̀ mo sì fi ìfẹ́ inúọkàn mi fún Baba Ọ̀run láti fi ẹsẹ̀ òtítọ́ tí mo ní ní inú múlẹ̀. Èmi kò retí ìfihàn nlá kankan. Ṣùgbọ́n nígbàtí mo bèèrè lọ́wọ́ Olúwa bí ìhìnrere náà bá jẹ́ òtítọ́, ìmọ̀lára dídùn kan wá sínú ọkàn mi gan—ohùn jẹ́jẹ́, kékeré náà tí ó nfi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ sí mi pé ó jẹ́ òtítọ́ àti pé mo níláti tẹ̀síwájú ní ṣíṣe ohun tí mò nṣe.

Ìmọ̀lára tí ó lágbára gidi tí èmi kò fi lè pa ìdáhùn náà tì kí èmi sì wípé èmi kò mọ̀ ọ́. Mo lo gbogbo ọjọ́ náà ní níní ìmọ̀ ìdùnnú gidi. Iyè-inú mi wà ní àwọn ọ̀run tí ó ngbèrò ẹwà ìmọ̀lára náà nínú ọkàn mi.

Ní Ọjọ́-ìsinmi tótẹ̀le, mo dúró ní iwájú àwọn akẹ́gbẹ́ kílásì mi mẹ́ta tàbí mẹ́rin, tí gbogbo wọ́n kéré jù mí. Mo jẹ́ ẹ̀rí sí wọn pé Baba Ọ̀run yíò dáhùn àdúrà wọn bí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́.

Àwòrán
Alàgbà Soares

Ìdáhùn kan sí àdúrà tí Alàgbà Soares gbà bí ọ̀dọ́mọkùnrin ti fi àyè gbàá láti jẹri—bí òjíṣẹ́ ìhìnrere kan (ṣíwájú), baba àti ọkọ, àti Àpóstélì—pé Baba Ọ̀run ndáhùn àwọn àdúrà tí a gbà nínú ìgbàgbọ́.

Láti ìgbà náà lọ, ẹ̀rí yí ti dúró pẹ̀lú mi. Ó ti ràn mi lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnú, nípàtàkì ní àwọn àkokò nígbàtí mo ti dojúkọ àwọn ìpènijà. Àdúrà náà ní ọjọ́ náà, lẹgbẹ pẹ̀lú àfikún àwọn ẹ̀rí tí mo ti gbà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ti fi àyè gbà mi láti jẹri sí àwọn ènìyàn, pẹ̀lú ìdánilójú, pé wọ́n lè gba àwọn ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run bí wọ́n bá gbàdúrà nínú ìgbàgbọ́. Èyì ti jẹ́ òtítọ́ gẹ́gẹ́bí mo ti jẹri bí òjíṣẹ́ ìhìnrere kan, gẹ́gẹ́bí olórí Ìjọ kan, gẹ́gẹ́bí baba àti ọkọ, àti pé àní gẹ́gẹ́bí Àpóstélì kan ní òní.

Ìgbàwo àti Ohun ti Àdúrà

Bẹ́ẹ̀ni, a kìí gbàdúrà nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára ìnílò alágbára ti-ẹ̀mí kan nìkan. Nítorínáà, ìgbàwo ni a níláti gbàdúrà? Àti pé kíni a níláti gbàdúrà fún? Ìdáhùn kúkurú náà ni ìgbàkugbà àti fún ohunkóhun.

Ọlọ́run ni Bàbá wa Ọ̀run. Mímọ èyí nyí bí a ti ngbàdúrà padà. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé: “Níní òye Ọlọ́run, à nbẹ̀rẹ̀ láti mọ̀ bí a ó ṣe dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀, àti bí a ó ṣe bèèrè kí a lè gba ìdáhùn. … Nígbàtí a bá ṣetán láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, Òun ti ṣetán láti wá sí ọ̀dọ̀ wa.”1

Baba wa Ọ̀run ṣetán láti fetísílẹ̀ sí wa Ó sì nfẹ́ kí a gbàdúrà sí Òun léraléra àti lemọ́lemọ́ nígbàgbogbo. A níláti “dámọ̀ràn pẹ̀lú Olúwa nínú gbogbo ṣíṣe [wa]” (Álmà 37:37) kí a sì gbàdúrà ní òwúrọ̀, ìyálẹ̀ta, àti òru. A níláti gbàdúrà ní ilé, ní ibi iṣẹ́, ní ilé-ìwé—níbikíbi tí a lè wà àti lórí eyikeyi àwọn ìṣe wa (wo Álmà 34:17–26).

A níláti gbàdúrà nínú àwọn ẹbí wa (wo 3 Nefi 18:21). A níláti gbàdúrà “síta àti nínú ọkàn [wa], ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 81:3). Àti “nígbàtí [ẹ̀yin] kò bá sì kígbe pe Olúwa, [ẹ jẹ́] kí ọkàn [wa] kún, kí ó sì fà síi ninu àdúrà láìsimi fún àlãfíà [wa], àti pẹ̀lú fún àlãfíà àwọn tí nwọ́n wa ní àyíká [wa]” (Álmà 34:27). Àti pé a gbúdọ̀ gbàdúrà nígbàgbogbo sí Baba ní orúkọ Jésù Krístì (wo 3 Nefi 18:19–20).

Àwòrán
Joseph Smith bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan

Ìjúwe Joseph Smith láti ọwọ́ Walter Rane, ni a kò lè ṣe ẹ̀dà rẹ̀

Dídé Ọ̀dọ̀ Baba Wa Ọ̀run

Baba wa ní Ọ̀run nfẹ́ láti bùkún wa. Òun Ó sì ṣe é—bí a bá bèèrè. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé, “Rántí pé láì bèèrè a kò lè gba ohunkóhun; nítorínáà, bèèrè nínú ìgbàgbọ́, ẹ̀yin ó sì gba irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ tí Ọlọ́run ri pé ó tọ́ láti fi lée yín lórí.”2

Àwọn àdúrà déédé àti lemọ́lemọ́ jẹ́ ara pàtàkì ti kíkúnjú-ìwọ̀n ìṣìkẹ́ ti-ẹ̀mí sí ìkébi àwọn ẹ̀mí wa. Sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run nípasẹ̀ àdúrà wà ó sí jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níbigbogbo àti nígbàgbogbo.

Ọ̀kan lára ààyò àwọn ìwé mímọ́ mi kọ́ni bí a ṣe níláti dé ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run nígbàti a bá kúnlẹ̀ láti gbàdúrà: “Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀; Olúwa Ọlọ́run rẹ yíò sì darí rẹ nípa ọwọ́ rẹ̀, yíò sì fún ọ ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà rẹ” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 112:10). Nígbàtí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti olùgbọràn, Baba Ọ̀run yíò wà pẹ̀lú wa. Òun yíò darí wa nípa ọwọ́ rẹ̀ Òun yíò mí sí wa pẹ̀lú ibi láti lọ àti ohun láti ṣe. Òun yíò dáhùn àwọn àdúrà wa gẹ́gẹ́bí ìfẹ́, ọ̀nà, àkokò, àti òye kíkún Rẹ̀ nípa ohun tí ó dára fún wa.

A níláti rántí èyí kí a sì ṣìkẹ́ àwọn ànfàní láti dé ibi ìtẹ́ Ọlọ́run kí a sì gba àwọn ìbùkún ní ọwọ́ Rẹ̀.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ìkọ́ni Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith (20011), 40, 41.

  2. Àwọn Ìkọ́ni: Joseph Smith, 131.