Làìhónà
Gbígbàgbọ́ nínú Krístì Ṣíwájú Kí Ó Tó Wá Lẹ́ẹ̀kansi
Oṣù Kẹrin 2024


“Gbígbàgbọ́ nínú Krístì ṣíwájú Kí Ó Tó Wá Lẹ́ẹ̀kansi,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹrin, 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹrin, 2024

Jarom

Gbígbàgbọ́ nínú Krístì ṣíwájú Kí Ó Tó Wá Lẹ́ẹ̀kansi

Àwọn Ará Néfì ní ìgbàgbọ́ ṣíwájú kí Olùgbàlà tó wá, a sì lè ní ìgbàgbọ́ ṣíwájú kí Òun tó wá lẹ́ẹ̀kansi.

Àwòrán
Jésù Krístì ṣèbẹ̀wò sí àwọn Ará Néfì

Ṣe ẹ ti ronú ohun tí yíò dà bí láti gbàgbọ́ nínú Olùgbàlà ṣíwájú kí Ó tó wá sí ayé? Àwọn Ará Néfì àtijọ́ ní láti kàn ṣe ìyẹn—“wọ́n fojúsọ́nà sí Messia, wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé ó nbọ̀ bí ẹnipé ó ti wá tẹ́lẹ̀” (Jarom 1:11).

Ní ọjọ́ wa, a ní ìwé mímọ́ àti àwọn àkọsílẹ̀ ìwé-ìtàn tí ó jẹri pé Jésù Krístì wà láàyè, ó kú, ó sì jí dìde lẹ́ẹ̀kansi. A gbàgbọ́ nínú Olùgbàlà tí ó ti wá tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n a gbàgbọ́ bákannáà nínú Olùgbàlà ẹni tí yíò wá lẹ́ẹ̀kansi.

Ṣíwájú kí Jésù Krístì tó Dé, àwọn Ará Néfì Ní Ìgbàgbọ́ Sí:

Àwòrán
Ọba Benjamin àti ìyàwó rẹ̀ ngbàdúrà

Gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ pé Krístì nbọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n sì yọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ nlá, tí yíò si dà bí ẹni pé ó ti dé sí àárín wọn,” (Mosiah 3:13; àtẹnumọ́ àfikún).

Àwòrán
Énọ́sì

Dáríji Arawọn

“Ohùn kan sì tọ̀ mí wá, tí ó wípé: Énọ́sì, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. … Nítorí-èyí, a ti gbá ẹ̀bi mi lọ. Mo sì wípé: Olúwa, báwo ni a ṣe ṣe èyĩ? Ó sì wí fún mi pé: Nítorí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Krístì, ẹnití ìwọ kò gbọ́ tàbí rí rí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì kọjá lọ kí ó tó di pé yíò fi ara rẹ̀ hàn ní ẹràn ara; … ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti mú ọ lára dá” (Énọ́sì 1:5–8; àtẹnumọ́ àfikún).

Àwòrán
Jákọ́bù nwàásù

Ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu

“A mọ̀ nípa Krístì, a sì ti ní ìrètí nípa ògo rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọrun ọdún ṣíwájú bíbọ̀ rẹ̀. … Tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi lè pàṣẹ lootọ ní orúkọ Jésù tí àwọn igi, tàbí àwọn òkè gíga, tàbí àwọn ìrusókè omi òkun, tí wọ́n sì gbọ́” (Jacob 4:4, 6; àfikún àtẹnumọ́).

Àwòrán
Mórónì nkọ̀wé sórí àwo

Gba ìfihàn.

“Àwọn púpọ̀ ni ó wà tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára púpọ̀, àní kí Krístì ó tó dé, àwọn tí a kò lè dènà mọ́ ní ibi ìkelè, ṣùgbọ́n tí wọ́n rí i pẹ̀lú ojú ara wọn” (Étérì 12:19; àtẹnumọ́ àfikún).

Ṣíwájú Kí Jésù Krístì Tó Wá Lẹ́ẹ̀kansi, A Lè Ní Ìgbàgbọ́ Láti:

Gba ìdáríjì, daríji arawa, ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, kí a sì gba ìfihàn (bíiti àwọn Ará Néfì).

Àwòrán
ọ̀dọ́mọkùnrin nkọrin nínú ilé ìjọsìn

Mura arawa sílẹ̀ fún bíbọ̀ Rẹ̀.

Bí a ti ntiraka láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, à nmúrasílẹ̀ láti gbé nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. “Nítorí ẹ kíyèsi, ìgbésí-ayé yí jẹ́ àkokò tí ènìyàn níláti múrasílẹ̀ láti bá Ọlọ́run pàdé; bẹ́ẹ̀ni, ẹ kíyèsi ọjọ́ ìgbésí-ayé yí ni ọjọ́ tí ènìyàn níláti ṣe iṣẹ́ wọn” (Álmà 34:32).

Àwòrán
àwọn ọ̀dọ́ ní iwájú tẹ́mpìlì

Múra ayé sílẹ̀ fún bíbọ Rẹ̀.

A ti gba ìfipè nípasẹ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson láti jẹ́ ara “iṣẹ́ títóbi jùlọ ní ilẹ̀-ayé”—ìkórajọ ti Ísráẹ́lì. “Baba Wa Ọrun ti ṣe ìpamọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí Rẹ̀ tí wọ́n ní ọlá jùlọ—bóyá, mo le sọ pé, àwọn ẹgbẹ́ Rẹ̀ tí ó dára jùlọ—fún ìgbésẹ̀ ìparí yi. Àwọn ọlọ́lá ẹ̀mí wọnnì—àwọn òṣèré tí wọ́n dára jùlọ wọnnì, àwọn akíkanjú wọnnì—ni ẹ̀yin!”1

Àwòrán
àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin dìmọ́ra

Ẹ ní ìrètí ní àwọn ìgbà ìṣòro.

Nígbàtí Olùgbàlà bá wá lẹ́ẹ̀kansi, àwọn olódodo yíò gbé ní àláfíà. Olùgbàlà yíò jọba, àti pé àìdára ni a ó mú dára. “Nítorí Olúwa yíò wà ní ààrin wọn, àti pé ògo rẹ̀ yíò wà ní orí wọn, òun yíò sì jẹ́ ọba wọn àti aṣòfin wọn”(Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 45:59).

Àwòrán
ọ̀dọ́mọbìnrin

Ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Àjínde.

Gbogbo ènìyàn yíò jínde. A ó ní ara pípé, àìkú. A lè rí àwọn àyànfẹ́ tí wọ́n ti kọjá lọ lẹ́ẹ̀kansi. “Ẹ̀mí àti ara yíò tún darapọ̀ sí ipò pípé wọn; àwọn ẹ̀yà ara àti orike ara ni a ó dá padà sí ipò wọn, àní bí àwa ṣe wà ní àkókò yí” (Álmà 11:43).

Àwòrán
Jésù Krístì nfarahàn sí àwọn Ará Néfì

Àwọn Ará Néfì àtijọ́ ní ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà ṣíwájú bíbọ̀ Rẹ̀. A lè ní ìgbàgbọ́ pé Olùgbàlà yíò wá lẹ́ẹ̀kansi—Nígbàtí “[a] ó ri [I] nínú àwọ̀ sánmọ̀ ti ọ̀run, ní wíwọ̀ ní aṣọ agbára àti ògò nlá” (Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 45:44; bákannáà wo Ìṣe àwọn Àpóstélì 1:11). Báwo ni mímọ̀ pé Òun yíò wá lẹ́ẹ̀kansi ó fi yí ohun tí ẹ yíò ṣe ní òní padà?

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ìrètí ti Ísráẹ́lì” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), Gospel Library.