Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 1


Ìwé Ti Álmà
Tí Íṣe Ọmọ Álmà

Àkọsílẹ̀ ti Álmà, ẹnití íṣe ọmọ Álmà, tí íṣe onídàjọ́ àkọ́kọ́ ati onidajọ àgbà lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí ó sì tún jẹ́ olórí àlùfã fún Ìjọ-Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ nípa ìjọba àwọn onídàjọ́, pẹ̀lú ogun àti ìjà lãrín àwọn ènìyàn nã. Àti pẹ̀lú àkọsílẹ̀ nípa ogun lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ Álmà, ẹnítí íṣe onídàjọ́ àkọ́kọ́ ati onídàjọ́ àgbà.

Orí 1

Néhórì nkọ́ni lẹ́kọ̃ èké, ó dá ìjọ kan sílẹ̀, ó sì mú iṣẹ́ àlùfã àrékérekè wá, ó sì pa Gídéónì—A pa Néhórì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—Àwọn iṣẹ́ àlùfã àrékérekè pẹ̀lú inúnibíni tàn lãrín àwọn ènìyàn nã—Àwọn àlùfã pèsè fún àìní ara nwọn, àwọn ènìyàn nã nṣe ìtọ́jú àwọn tálákà, Ìjọ-Ọlọ́run nã sí ṣe rere. Ní ìwọ̀n ọdún 91 sí 88 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe, ní ọdún kíni tí ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, láti ìsisìyí lọ, tí Mòsíà ọba, lẹ́hìntí ó ti re ibi gbogbo ayé írè, tí ó sì ti ja ogun rere, tí ó sì ti rìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run, tí kò sì fi ẹnìkẹ́ni sílẹ̀ pé kí ó jọba dípò ara rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ti fi àwọn òfin lélẹ̀, àwọn ènìyàn sì ti gbà wọ́n; nítorínã nwọn níláti pa àwọn òfin nã mọ́, èyítí ó ti ṣe.

2 Ó sì ṣe pé ní ọdún kíni ìjọba Álmà lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ọkùnrin kan wà tí a mú wá síwájú rẹ̀ pé kí a dájọ́ fún un, ẹnití ó tóbi tí a sì mọ̀ ọ́ fún agbára rẹ̀.

3 Òun sì ti lọ lãrín àwọn ènìyàn nã, tí ó sì nwãsù sí nwọn èyítí òun pè ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì nṣe àtakò ìjọ-Ọlọ́run tí ó nsọ fún àwọn ènìyàn nã pé gbogbo àlùfã àti olùkọ́ni yẹ kí nwọ́n jẹ́ olókìkí; àti pé kò yẹ kí nwọ́n fi ọwọ́ nwọn ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n pé àwọn ènìyàn nwọn níláti ṣe àtìlẹhìn nwọn.

4 Òun sì ṣe ìjẹ́rĩ pẹ̀lú sí àwọn ènìyàn nã pé gbogbo ènìyàn ni a ó gbà là ní ọjọ́ ìkẹhìn, àti pé kí nwọn kí ó máṣe bẹ̀rù tàbí wárìrì, ṣùgbọ́n pé kí nwọ́n gbé orí nwọn sókè, kí nwọ́n sì yọ̀; nítorítí Olúwa ti dá gbogbo ènìyàn, ó sì ti ra gbogbo ènìyàn padà; àti pé, ní ìkẹhìn, gbogbo ènìyàn yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun.

5 Ó sì ṣe tí ó nkọ́ni ní àwọn ohun wọ̀nyí tó bẹ̃gẹ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, àní púpọ̀ tó bẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀ sĩ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un, tí nwọ́n sì nfún un ní owó.

6 Ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìgbéraga nínú ìgbéraga ọkàn rẹ̀, tí ó sì nwọ àwọn aṣọ olówó-iyebíye, bẹ̃ni, ó sì bẹ̀rẹ̀sí dá ìjọ sílẹ̀ pẹ̀lú, gẹ́gẹ́bí ìlànà ìwãsù rẹ̀.

7 Ó sì ṣe bí ó ti nlọ, láti wãsù sí àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ gbọ́, ó bá ọkùnrin kan pàdé, ẹnití íṣe ti ìjọ-Ọlọ́run, bẹ̃ni, àní ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ni nwọn; òun sì bẹ̀rẹ̀sĩ jiyàn pẹ̀lú rẹ̀ kíkan-kíkan, pé kí òun lè darí àwọn ènìyàn ìjọ nã kúrò; ṣùgbọ́n ọkùnrin nã kọjú ìjà síi, ó sì rọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

8 Nísisìyí orúkọ ọkùnrin nã ni Gídéónì; òun sì ni ẹni tí ó jẹ́ ohun èlò lọ́wọ́ Ọlọ́run láti gba àwọn ènìyàn Límháì kúrò nínú oko-ẹrú.

9 Nísisìyí, nítorípé Gídéónì kọjú ìjà síi pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó bínú sí Gídéónì ó sì fa idà rẹ̀ yọ, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣáa. Gẹ́gẹ́bí Gídéónì ti pọ̀ ní ọjọ́, nítorínã, òun kò lè dojú kọ lílù u rẹ̀, nítorínã, a fi idà pa á.

10 Ẹni nã tí ó pa á ni àwọn ènìyàn ìjọ-Ọlọ́run mú wá sí iwájú Álmà, kí a lè dájọ́ fún un gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀.

11 Ó sì ṣe tí òun wá síwájú Álmà, tí ó sì wí àwíjàre fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgboyà.

12 Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: wõ, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a ó ri iṣẹ́ àlùfã àrékérekè lãrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Sì kíyèsĩ, ìwọ kò jẹ̀bi iṣẹ́ àrékérekè nìkan, ṣùgbọ́n ìwọ ti gbìyànjú láti ṣe bẹ̃ pẹ̀lú idà; tí o bá sì ri bẹ̃ pé a ó fi ipá ṣe iṣẹ́ àlùfã àrékérekè lãrín àwọn ènìyàn yíi yíò já sí ìparun nwọn pátápátá.

13 Ìwọ sì ti ta ẹ̀jẹ̀ olódodo sílẹ̀, bẹ̃ni, ẹni tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun dáradára lãrín àwọn ènìyàn yíi; tí àwa bá sì dá ọ sí, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yíò wá sórí wa fún ẹ̀san.

14 Nítorínã, a dá ọ lẹ́bi lati ikú, gẹ́gẹ́bí òfin èyítí Mòsíà, ọba wa ti ó jẹ kẹ́hìn ti fi fún wa; àwọn ènìyàn yĩ sì ti gbã, nítorínã, àwọn ènìyàn yíi níláti tẹ̀lé òfin.

15 Ó sì ṣe tí nwọ́n múu; orúkọ rẹ̀ sì ni Néhórì; nwọ́n sì gbé e lọ sórí òkè Mántì, níbẹ̀ ni a sì ṣe ti, tàbí ni ó sì gba, ní ãrin àwọn ọ̀run òun ayé, wípé ohun èyítí òun ti kọ́ àwọn ènìyàn lòdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; níbẹ̀ ni ó sì kú ikú ìtìjú.

16 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, èyí kò fi òpin sí ìtànkalẹ̀ iṣẹ́ àlùfã àrékérekè jákè-jádò ilẹ̀ nã; nítorítí àwọn tí nwọ́n ní ìfẹ́ sí àwọn ohun asán ayé pọ̀, nwọ́n sì nlọ láti wãsù àwọn ẹ̀kọ́ èké; èyí ni nwọ́n sì ṣe nítorí ọrọ̀ àti ọlá.

17 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n kò jẹ́ purọ́, nítorípé tí a bá mọ́ irọ́ nwọn, nítorí ìbẹ̀rù òfin, nítorípé a máa jẹ àwọn òpùrọ́ níyà, nítorínã nwọ́n wãsù bí ẹnipé bí ìgbàgbọ́ nwọn ṣe rí ni èyí; àti nísisìyí, òfin kò lè de ẹnikẹ́ni fún ìgbàgbọ́ rẹ̀.

18 Nwọn kò sì jalè, fún ìbẹ̀rù òfin, nítorítí wọn a máa fi ìyà jẹ irú àwọn bẹ̃; bẹ̃ ni nwọn kò gbọ́dọ̀ fi ipá jalè, tàbí ṣe ìpànìyàn, nítorítí ẹnití ó bá pànìyàn ni a ó fi ìyà jẹ de oju ikú.

19 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe, tí àwọn tí nwọn kĩ ṣe ará ìjọ-Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀sĩ ṣe inúnibíni sí àwọn tĩ ṣe ará ìjọ-Ọlọ́run, tí nwọ́n sì ti gba orúkọ Krístì lé ara nwọn.

20 Bẹ̃ni, nwọ́n nṣe inúnibíni sí nwọn, nwọ́n sì nyọ nwọ́n lẹ́nu pẹ̀lú onírurú ọ̀rọ̀, èyĩ nítorí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ nwọn; nítorítí nwọn kò gbéraga lójú ara nwọn, àti nítorítí nwọn sọ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní ọ̀kan pẹ̀lú òmíràn, láìgbowó àti láìdíyèlé.

21 Nísisìyí, òfin tí ó múná kan wà lãrín àwọn ènìyàn ìjọ nã, pé kí ẹnìkẹ́ni tĩ bá íṣe ti ìjọ-Ọlọ́run, máṣe ṣe inúnibíni sí àwọn tí kĩ ṣe ti ìjọ-Ọlọ́run, àti pé kí inúnibíni má sì ṣe wà lãrín ara nwọn.

22 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nínú nwọn tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìgbéraga, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe àríyànjiyàn líle pẹ̀lú àwọn tí ó lòdì sí nwọn, tí nwọ́n fi nlu ara nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n lu ara pẹ̀lú ìkũkù.

23 Èyí sì jẹ́ ọdún kejì ìjọba Álmà, ó sì jẹ́ ohun tí ó mú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú bá ìjọ; bẹ̃ni, ó jẹ́ ohun tí ó mú ọ̀pọ̀ ìdánwò fún ìjọ nã.

24 Nítorítí a mú ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ sé le, a sì ti pa orúkọ nwọn rẹ́, tí a kò sì rántí nwọn mọ́ lãrín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Àti bákannã, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yọ ara nwọn kúrò lãrín nwọn.

25 Nísisìyí, eleyĩ jẹ́ ìdánwò nlá fún àwọn tí nwọ́n dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n dúró ṣinṣin láìyẹsẹ̀ ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ nwọ́n sì faradà gbogbo inúnibíni tí a fi bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú ìrọ́jú.

26 Nígbàtí àwọn àlùfã sì fi iṣẹ́ nwọn sílẹ̀ láti kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn ènìyàn nã bákannã fi iṣẹ́ nwọn sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbàtí àlùfã bá sì ti kọ́ nwọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tán gbogbo nwọn a tún padà sí ṣíṣe iṣẹ́ nwọn tọkàntara; àlùfã nã kò sì ka ara rẹ̀ kún níwájú àwọn olùgbọ́ rẹ̀, nítorítí oníwãsù kò sunwọ̀n ju olùgbọ́ lọ, olùkọ́ni nã pẹ̀lú kò sunwọ̀n ju akẹ́kọ̃ lọ; bẹ̃ni gbogbo nwọn jẹ́ ọgbọ̃gba, nwọ́n sì jọ nṣe iṣẹ́ olúkúlùkù, gẹ́gẹ́bí agbára rẹ̀.

27 Nwọ́n sì nṣe ìfifún ni nínú ohun ìní nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èyí tí ó ní, fún àwọn tálákà, àwọn aláìní, àwọn aláìsàn, àti àwọn tí ìyà njẹ; nwọn kò sì wọ aṣọ olówo-iyebíye, síbẹ̀ nwọ́n fínjú, nwọ́n sì lẹ́wà.

28 Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe fi ojúṣe ìjọ-Ọlọ́run nã lélẹ̀; báyĩ sì ni nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní àlãfíà tí ó pẹ́ títí, l’áìṣírò nwọn nṣe inúnibíni sí nwọn.

29 Àti nísisìyí, nítorí ìdúróṣinṣin ìjọ nã, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní ọrọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọ́n ní ọ̀pọ̀ ohun gbogbo tí nwọ́n ṣe aláìní—ọ̀pọ̀ agbo-ẹran àti ọ̀wọ́-ẹran, àti àwọn onírũrú àbọ́pa, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èso, àti wúrà, àti fàdákà, àti àwọn ohun oníyebíye, àti ọ̀pọ̀ aṣọ ṣẹ̀dá àti aṣọ ọ̀gbọ tí ó jọjú, àti onírũrú aṣọ ìwọ́lẹ̀.

30 Bẹ̃ gẹ́gẹ́, nínú ipò ãsìkí yíi, nwọn kò ta ẹnikẹ́ni ti o wà ni ìhòhònù, tàbí tí ebi npa, tàbí tí òngbẹ ngbẹ, tàbí tí ó ṣàìsàn, tàbí tí kò rí jẹ tó; nwọn kò sì kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀; nítorínã, nwọ́n lawọ́ sí gbogbo ènìyàn; àgbà àti ọmọdé, pẹ̀lú ẹnití ó wà ní ìdè tàbí ní òmìnira, ọkùnrin àti obìnrin, yálà ní òde ìjọ Ọlọ́run tàbí ní inú ìjọ-Ọlọ́run, tí nwọn kò sì ṣe ojúṣãjú ènìyàn ní ti ẹni tí ó ṣe aláìní.

31 Ati bẹ̃ gẹ́gẹ́ ní nwọ́n ní ãsìkí, tí nwọ́n sì ní ọrọ̀ ju àwọn tí nwọn kò jẹ́ ti ìjọ nã lọ.

32 Nítorítí àwọn tí nwọn kĩ ṣe ará ìjọ nã ti kún fún ìwà àrékérekè, àti ìbọ̀rìṣà, àti nínú ọ̀rọ̀ asán tàbí ìmẹ́lẹ́, àti ìlara àti asọ̀; tí nwọ́n nwọ aṣọ olówó-iyebíye; tí nwọ́n nrú ọkàn nwọn sókè nínú ìgbéraga ojú ti ara nwọn; ìṣe inúnibíni, irọ́ pípa, olè jíjà, fífi ipá jalè, ṣíṣe àgbèrè àti ìpànìyàn, àti onírũrú ìwà búburú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a fi òfin de gbogbo àwọn tí nwọn bá rée kọjá, níwọ̀n bí a ti lè ṣeé.

33 Ó sì ṣe, nígbàtí a sì fi òfin lélẹ̀ báyĩ fún nwọn, tí olúkúlùkù sì jìyà gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, nwọ́n sì pọ̀ síi, nwọn kò sì hu ìwà búburú èyí tí a lè mọ̀; nítorínã àlãfíà púpọ̀ wà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì títí dé ọdún karũn ìjọba àwọn ónídàjọ̃.