Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 7


Àwọn ọ̀rọ̀ Álmà èyítí ó sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní Gídéónì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ rẹ̀.

Èyítí a kọ sí orí 7.

Orí 7

A ó bí Krístì nípasẹ̀ Màríà—Òun yíò já ìdè ikú, yíò sì ru ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀—Àwọn tí nwọ́n bá ronúpìwàdà, tí a sì rìbọmi, tí wọ́n sì pa àwọn òfin mọ́ yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun—Ohun ẹ̀gbin kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run—Ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ni a bẽrè. Ní ìwọ̀n ọdún 83 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, níwọ̀n ìgbàtí a ti gbà mí lãyè láti tọ̀ yín wá, nítorínã èmi yíò gbìyànjú láti bã yín sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí èdè mi; bẹ̃ni, láti ẹnu mi, níwọ̀n ìgbàtí ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí èmi yíò bã yín sọ̀rọ̀ láti ẹnu mi nítorítí a ti fi mí sí órí ìtẹ́ ìdájọ́, tí èmi sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe tí wọn kò gbà mí lãyè láti wá sí ọ̀dọ̀ yín.

2 Àti pãpã, èmi kì bá má lè wá ní àkokò yĩ, bíkòṣepé a ti fi ìtẹ́ ìdájọ́ fún ẹlòmíràn, láti ṣe ìdájọ́ dípò mi; Olúwa, nínú ọ̀pọ̀ ãnú sì ti gbà kí èmi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ yín.

3 Sì kíyèsĩ, èmi wá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìrètí àti ìfẹ́-inú pé èmi yíò ríi pé ẹ̀yin ti rẹ àrã yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, àti pé ẹ̀yin ti tẹ̀síwájú ní títọrọ fún õre-ọ̀fẹ́ rẹ̀, pé èmi yíò bã yín ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀, pé èmi yíò ríi pé ẹ̀yin kò sí nínú ipò búburú nnì nínú èyítí àwọn arákùnrin wa wà ní Sarahẹ́múlà.

4 Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run, pé ó ti fi fún mi láti mọ̀, bẹ̃ni, tí ó sì fún mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ tí ó tayọ láti mọ̀ pé wọ́n tún ti padà sí ọ̀nà òdodo rẹ̀.

5 Èmi sì ní ìdánilójú, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó wà nínú mi, pé èmi yíò ní ayọ̀ lórí yín; bíótilẹ̀ríbẹ̃, èmi kò fẹ́ kí ayọ̀ mi lórí yín wá nípa ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti ìbànújẹ́ èyítí èmi ti ní fún àwọn arákùnrin tí ó wà ní Sarahẹ́múlà, nítorí ẹ kíyèsĩ, ayọ̀ mi wá lórí wọ́n lẹ́hìn tí wọ́n ti la ìṣòro ìpọ́njú àti ìbànújẹ́ kọjá.

6 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò sí nínú irú ipò àìnígbàgbọ́ bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ti àwọn arákùnrin yín; mo ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò gbé ọkàn yín sókè nínú ìgbéraga, bẹ̃ni, mo ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò gbé ọkàn an yín lé ọrọ̀ àti ohun asán ayé; bẹ̃ni, mo ní ìdánilójú pé ẹ̀yin kò bọ òrìṣà, ṣùgbọ́n wípé ẹ̀yin nsin Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè, àti pé ẹ̀yin ndúró de ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ títí ayé, èyítí nbọ̀.

7 Nítorí kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ni ó nbọ̀wá; kí ẹ kíyèsĩ, ohun kan wà, èyítí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo nwọn lọ—nítorí kíyèsĩ, àkokò nã kò jìnà tí Olùràpadà nbọ̀wá tí yíò sí máa gbé ãrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

8 Ẹ kíyèsĩ, èmi kò wípé ó nbọ̀wá sí ãrin wa ní àkokò tí ó wà nínú àgọ́ ara; nítorí kí ẹ kíyèsĩ, Ẹ̀mí-Mímọ́ kò tĩ wí fún mi pé báyĩ ni ó rí. Nísisìyí, nípa ohun yíi èmi kò mọ̀; ṣùgbọ́n ohun tí èmi mọ̀ ni èyíi, pé Olúwa Ọlọ́run ní agbára láti ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

9 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Ẹ̀mí-Mímọ́ ti sọ èléyĩ fún mi, wípé: Kígbe sí àwọn ènìyàn yíi, wípé—Ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì tún ọ̀nà Olúwa ṣe, kí ẹ sì rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀, èyítí ó gún; nítorí kíyèsĩ, ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run nã sì nbọ̀wá sí orí ilẹ̀ ayé.

10 Sì kíyèsĩ, a o bĩ nípasẹ̀ Màríà, ní Jerúsálẹ́mù èyítí íṣe ilẹ̀ àwọn bàbá nlá wa, òun yíò sì jẹ́ wúndíá, ohun èlò tí ó níye lórí tí a sì yàn, ẹnití a ó ṣíjibò, tí yíò sì lóyún nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, yíò sì bí ọmọkùnrin kan, bẹ̃ni, àní Ọmọ Ọlọ́run.

11 Òun yíò sì jáde lọ, ní ìfaradà ìrora, ìpọ́njú àti àdánwò onírurú; èyítí ó rí bẹ̃ kí ọ̀rọ̀ nã lè ṣẹ, èyítí ó wípé yíò gbé ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ lé ara rẹ̀.

12 Òun yíò sì gbé ikú lé ara rẹ̀, kí òun kí ó lè já ìdè ikú èyítí ó de àwọn ènìyàn rẹ̀; òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, nípa ti ara, kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera wọn.

13 Nísisìyí, Ẹ̀mí-Mímọ́ mọ ohun gbogbo; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Ọmọ Ọlọ́run jìyà nípa ti ara, kí ó lè gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ ka orí ara rẹ̀, kí ó lè pa gbogbo ìwàìrékọjá nwọn rẹ́, nípa agbára ìdásílẹ̀ rẹ̀; àti nísisìyí kíyèsĩ, èyí ni ẹ̀rí èyítí ó wà nínú mi.

14 Nísisìyí mo wí fún yín pé ẹ̀yin níláti ronúpìwàdà, kí ẹ sì di àtúnbí; nítorítí Ẹ̀mí wípé tí ẹ̀yin kò bá di àtúnbí ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba ọ̀run; nítorínã ẹ wá kí a sì ṣe ìrìbọmi fún yín sí ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin lè jẹ́ wíwẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀yin lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀dọ́-Àgùtàn Ọlọ́run nã, ẹni tí ó kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ, tí ó tóbi láti gbàlà àti láti wẹ̀mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo.

15 Bẹ̃ni, èmi wí fún yín ẹ wá ẹ máṣe bẹ̀rù, kí ẹ sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tì sí apá kan, èyítí ó fi ìrọ̀rùn rọ̀gbàká yín, èyítí ó dè yín mọ́lẹ̀ sí ìparun, bẹ̃ni, ẹ wá, kí ẹ sì kọjá lọ, kí ẹ sì fihàn fún Ọlọ́run yín pé ẹ̀yin ṣetán láti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì bá a dá májẹ̀mú láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì jẹ́ ẹ̀rí ẹ̀yí sí i lòní nípa wíwọ̀ inú omi ìrìbọmi lọ.

16 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ṣe eleyĩ, tí ó sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ láti ìsisìyí lọ, òun kannã ni yíò rántí pé èmi wí fún un, bẹ̃ni, òun yíò rántí pé èmi ti wí fún un, òun yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí Ẹ̀mí Mímọ́ èyítí ó njẹ́rĩ nínú mi.

17 Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ ẹ̀yin gbà àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́? Kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́; ọ̀nà tí èmi sì mọ̀ pé ẹ̀yin gbà wọ́n gbọ́ ni nípa ìṣípayá Ẹ̀mí tí ó wà nínú mi. Àti nísisìyí nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó múná nípa ohun wọnnì, bẹ̃ni, nípa àwọn ohun tí ẹ̀mí sọ, ayọ̀ mí pọ̀ jọjọ.

18 Nítorí bí èmi ṣe wí fún yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá pé èmi ní ìrètí pé ẹ̀yin kò sí ní ipò búburú nnì gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nyin, bẹ̃ gẹ́gẹ́ èmi ríi pé ìrètí mi ni a ti tẹ́ lọ́rùn.

19 Nítorí èmi ríi pé ẹ̀yin wà ní ipa ọ̀nà òdodo; mo ríi pé ẹ̀yin wà ní ipa ọ̀nà tí ó tọ́ni sí ìjọba Ọlọ́run; bẹ̃ni, èmi ríi pé ẹ̀yin nṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.

20 Mo ríi pé a ti sọọ́ di mímọ̀ fún yín, nípa ẹ̀rí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kò lè rìn ní ipa ọ̀na tí ó wọ́; bẹ̃ni kĩ yapa kúrò ní èyítí ó bá ti sọ; bẹ̃ sì ni kò sí àmì ìyípadà kanṣoṣo láti ọ̀tún sí òsì, tàbí láti èyítí ó tọ̀nà sí èyítí ó kùnà; nítorínã, ipa ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ipa ọ̀nà ayérayé kan tí kò yípadà.

21 Òun kĩ sĩ gbé inú tẹ́mpìlì àìmọ́, bẹ̃ sì ni a kò lè gba ohun ẹ̀gbin tàbí ohunkóhun tí kò mọ́ sínú ìjọba Ọlọ́run; nítorínã èmi wí fún un yín pé àkokò nã nbọ̀wá, bẹ̃ni, yíò sì rí bẹ̃ ní ìgbà ìkẹhìn, pé ẹnití ó bá ní ìríra yio wà ní ipò ìríra rẹ̀.

22 Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún un yín kí èmi kí ó lè ta yín jí sí ojúṣẽ yín sí Ọlọ́run kí ẹ̀yin lè rìn láìlẹ́bi níwájú rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè rìn ní ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, èyítí a ti gbà yín sí.

23 Àti nísisìyí, èmi rọ̀ yín kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, kí ẹ sì tẹríba, kí ẹ sì ṣe ìwà-pẹ̀lẹ́; kí ẹ ní ìwà tútù; kí ẹ kún fún ìfaradà àti ìlọ́ra; pẹ̀lú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ohun gbogbo; sí ìtẹramọ́ pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní ìgbà gbogbo; ní ìbẽrè ohunkóhun tí ẹ̀yin ṣe aláìní, ní ti ẹ̀mí àti ti ara; kí ẹ sì mã fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nínú ohun gbogbo tí ẹ̀yin bá rí gbà.

24 Kí ẹ̀yin kí ó sì ríi pé ẹ ní ìgbàgbọ́, ìrètí, pẹ̀lú ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, nígbànã ni ẹ̀yin yíò sì lè ṣe iṣẹ́ rere.

25 Kí Olúwa kí ó sì bùkún un yín, kí ó sì pa aṣọ yín mọ́ láìlábàwọ́n, kí ẹ̀yin lè bá Ábráhámù, Ísãkì àti Jákọ́bù jòkó ní ìkẹhìn, pẹ̀lú àwọn wòlĩ mímọ́ tí wọ́n ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé, tí aṣọ yín sì wà ní àìlábàwọ́n, àní gẹ́gẹ́bí aṣọ wọ́n ṣe wà láìlábàwọ́n, ní ìjọba ọ̀run, tí kò sì ní jáde kúrò níbẹ̀ mọ́.

26 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi sọ àwọn ohun wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí Ẹ̀mí-Mímọ́ èyítí ó njẹ́rĩ nínú mi; ẹ̀mí mi sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹramọ́ pẹ̀lú ìfọkànsìn tí ẹ̀yin ti fi fún ọ̀rọ̀ mi.

27 Àti nísisìyí, njẹ́ kí àlãfíà Ọlọ́run kí ó bà lé yín lórí, àti lórí ilé yín àti ilẹ̀ yín, àti ọ̀wọ́-ẹran, àti agbo-ẹran an yín, àti ohun ìní yín gbogbo, àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ yín, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rerẽ yín, láti ìsisìyí lọ, àti títí láéláé. Báyĩ sì ni èmi ti sọ̀rọ̀. Àmin.