Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 18


Orí 18

Ọba Lámónì rò wípé Ámọ́nì ni Òrìṣà Nlá nã—Ámọ́nì kọ́ ọba nã ní ẹ̀kọ́ nípa ìdásílẹ̀ ayé, nípa bí Ọlọ́run ṣe nbá ènìyàn lò, àti nípa ìràpadà tí ó wá nípasẹ̀ Krístì—Lámónì gbàgbọ́ ó sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹnití ó ti kú. Ní ìwọ̀n ọdún 90 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí ọba Lámónì pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá síwájú kí nwọ́n sì jẹ́rĩ sí gbogbo ohun tí nwọ́n ti rí nípa ọ̀rọ̀ nã.

2 Nígbàtí gbogbo nwọ́n sì ti jẹ́rĩ sí gbogbo ohun tí nwọ́n ti rí, tí òun sì ti gbọ́ nípa ìwà òtítọ́ Ámọ́nì bí ó ti pa agbo-ẹran rẹ̀ mọ́, àti nípa agbára rẹ̀ tí ó fi bá àwọn tí nwọ́n fẹ́ paá jà, ẹnu yã lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì wípé: Nítoótọ́, eleyĩ kĩ ṣe ènìyàn lásán. Kíyèsĩ, njẹ́ kĩ ha íṣe Òrìṣà Nlá nnì tí ó bẹ àwọn ènìyàn yĩ wò pẹ̀lú ìyà nítorí ìpànìyàn nwọn?

3 Nwọ́n sì dá ọba lóhùn, nwọn wípé: Yálá Òrìṣà Nlá nnì nií ṣe tàbí ènìyàn, àwa kò mọ̀; ṣùgbọ́n, èyí ni àwa mọ̀, pé àwọn ọ̀tá ọba kò lè paá; bẹ̃ sì ni nwọn kò lè tú àwọn agbo-ẹran ọba ká nígbàtí ó wà pẹ̀lú wa, nítorí ìmọ̀ rẹ̀ àti agbára nlá rẹ̀; nítorínã, àwa mọ̀ wípé ọ̀rẹ́ ọba nií ṣe. Àti nísisìyí Á! ọba, àwa kò gbàgbọ́ pé ènìyàn kan lè ní irú agbára nlá bẹ̃, nítorítí àwa mọ̀ pé nwọn kò lè paá.

4 Àti nísisìyí, nígbàtí ọba nã gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún nwọn pé: Báyĩ èmi mọ̀ wípé Òrìṣà Nlá nnì ni íṣe; òun sì ti sọ̀kalẹ̀ wá ní àkókò yí láti pa ẹ̀mí yín mọ́, kí èmi kí ó má bã pa yín gẹ́gẹ́bí èmi ṣe pa àwọn arákùnrin yín. Nísisìyí, èyí ni Òrìṣà Nlá nã, èyítí àwọn bàbá wa ti sọ nípa rẹ̀.

5 Nísisìyí èyí sì ni àṣà èyítí Lámónì ti gbà láti ọwọ́ bàbá rẹ̀, wípé Òrìṣà Nlá kan wà. L’áìṣírò nwọ́n gbàgbọ́ nínú Òrìṣà Nlá kan, tí nwọ́n sì lérò pé ohunkóhun tí nwọ́n bá ṣe ni ó dára; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Lámónì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù gidigidi, pẹ̀lú ìbẹ̀rù pé bóyá òun ti kùnà nínú pipa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ òun;

6 Nítorítí ó ti pa púpọ̀ nínú nwọn nígbàtí àwọn arákùnrin nwọn tú agbo-ẹran nwọn ká ní ìdí odò; tí ó sì jẹ́ wípé bí nwọ́n ṣe tú agbo-ẹran nwọn ká nnì, a ti pa nwọ́n.

7 Nísisìyí, ó jẹ́ àṣà àwọn ará Lámánì láti dúró sí ìdí odò Sébúsì láti tú agbo-ẹran àwọn ènìyàn nã ká, nípasẹ̀ èyítí nwọn yíò lé púpọ̀ àwọn tí nwọ́n túká lọ sí orí ilẹ̀ tiwọn, èyítí íṣe ìwà ìkógun lãrín nwọn.

8 Ó sì ṣe tí ọba Lámónì bẽrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: Níbo ni ọkùnrin yí tí ó ní irú agbára nlá nã wà?

9 Nwọ́n sì wí fún pé: Kíyèsĩ, ó nfún àwọn ẹṣin rẹ ní óúnjẹ. Báyĩ ṣãju àkokò yí tí nwọ́n nfún àwọn agbo-ẹran ni ómi, ọba ti pàṣẹ pé kí nwọ́n pèsè àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sílẹ̀, kí nwọ́n sì gbé òun yí ilẹ̀ Nífáì ká, nítorítí bàbá Lámónì tí íṣe ọba lórí ilẹ̀ nã gbogbo ti pèsè àpèjẹ kan ní ilẹ̀ Nífáì.

10 Nísisìyí, nígbàtí ọba Lámónì gbọ́ wípé Ámọ́nì npèsè àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sílẹ̀, ẹnu túbọ̀ yã sí, nítorí ìṣòdodo Ámọ́nì, ó sì wípé: Dájúdájú kò tĩ sí ọmọ-ọ̀dọ̀ kan lãrín gbogbo ọmọ-ọ̀dọ̀ mi tí ó jẹ́ olõtọ́ bí ọkùnrin yí; nítorítí ó tún rántí gbogbo àṣẹ tí mo pa kí òun lè ṣe nwọ́n.

11 Nísisìyí, èmi mọ̀ dájú pé Òrìṣà Nlá nã ni èyí, èmi sì ní ìfẹ́ sí pé kí ó wá sí iwájú mi, ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ ṣe bẹ̃.

12 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ámọ́nì ti pèsè àwọn ẹṣin pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọba sílẹ̀ tán; ó tọ ọba lọ, ó sì ríi pé ojú ọba ti yí padà; nítorínã, ó fẹ́ padà kúrò níwájú rẹ̀.

13 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba sì sọ fún un wípé: Rábbánà, èyítí ó túmọ̀ sí, ọba alágbára tàbí ọba nlá, nítorítí nwọ́n ka àwọn ọba nwọn sí alágbára; báyĩ ni ó sì wí fún un: Rábbánà, ọba fẹ́ kí ìwọ kí ó dúró.

14 Nítorínã, Ámọ́nì yípadà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó sì wí fún un pé: Kíni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ, A! ọba? Ọba kò sì dáa lóhùn fún ìwọ̀n wákàtí kan, gẹ́gẹ́bí ìṣirò àkókò tiwọn, nítorítí kò mọ́ ohun tí òun yíò sọ fún ún.

15 Ó sì ṣe tí Ámọ́nì tún wí fún un pé: Kíni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ? Ṣùgbọ́n ọba kò fèsì fún un.

16 Ó sì ṣe, tí Ámọ́nì, nítorítí ó kún fún Ẹ̀mí Ọlọ́run, nígbànã ni ó mọ́ èrò ọkàn ọba. Ó sì wí fún un pé: Ṣé nítorítí ìwọ ti gbọ́ pé èmi dãbò bò àwọn agbo-ẹran rẹ, tí èmi sì pa méje nínú àwọn arákùnrin nwọn pẹ̀lú kànnà-kànnà àti idà, tí èmi sì gé apá àwọn yókù, láti lè dãbò bò àwọn agbo-ẹran rẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ; wõ, njẹ́ èyí ni ó ha fa ìyàlẹ́nu fún ọ?

17 Èmi wí fún ọ, kíni ìdí rẹ̀ tí ìyàlẹ́nu rẹ fi tó èyí? Wõ, ènìyàn ni èmi íṣe, ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ sì ni èmi; nítorínã, ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ tí ó tọ̀nà, òun nã ni èmi yíò ṣe.

18 Nísisìyí nígbàtí ọba ti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹnu tún yã sĩ, nítorítí ó rĩ pé Ámọ́nì lè mọ àwọn èrò ọkàn òun; ṣùgbọ́n l’áìṣírò eyi, ọba Lámónì la ẹnu rẹ̀, ó sì wí fún un pé: Tani ìwọ íṣe? Njẹ́ ìwọ ni Òrìṣà Nlá nnì, tí ó mọ ohun gbogbo?

19 Ámọ́nì dáa lóhùn ó sì wí fún un pé: Èmi kọ́.

20 Ọba sì tún wípé: Báwo ni ìwọ ha ṣe mọ́ àwọn èrò ọkàn mi? Ìwọ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, kí ó sì sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún mi; kí ìwọ sì tún sọ fún mi nípa agbára èyítí ìwọ fi pa àwọn arákùnrin mi, àwọn tí nwọn ntú àwọn agbo-ẹran mi ká, tí ìwọ sì tún gé apá nwọn—

21 Àti nísisìyí, bí ìwọ bá lè sọ fun mí nípa ohun wọ̀nyí, ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́, èmi yíò fún ọ; tí ó bá sì yẹ, èmi yíò ṣọọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun mi; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ìwọ lágbára ju gbogbo nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí èmi fún ọ, èmi yíò fún ọ.

22 Nísisìyí, Ámọ́nì jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kò sì ní ẹ̀mí ìpanilára, ó wí fún Lámónì: Njẹ́ ìwọ yíò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí èmi bá sọ fún ọ nípa agbára tí èmi fi nṣe ohun wọ̀nyí? Èyí sì ni ohun tí èmi fẹ́ láti ọwọ́ rẹ.

23 Ọba sì dáa lóhùn, ó sì wí pé: Bẹ̃ni, èmi yíò gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Báyĩ sì ni a fi ẹ̀tàn múu.

24 Ámọ́nì sì bẹ̀rẹ̀sí bã sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, ó sì wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ ha gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ?

25 Òun sì dáhùn, ó sì wí fún un pé: Èmi kò mọ́ ìtúmọ̀ èyí nnì.

26 Ámọ́nì sì tún wípé: Njẹ́ ìwọ ha gbàgbọ́ pé Òrìṣà Nlá kan nbẹ?

27 Ó sì wí pé, Bẹ̃ni.

28 Ámọ́nì sì wípé: Èyí yĩ ni Ọlọ́run. Ámọ́nì sì tún wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé Òrìṣà Nlá yìi, tí íṣe Ọlọ́run, ni ó dá ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ayé?

29 Ó sì wí pé: Bẹ̃ni, mo gbàgbọ́ pé òun ni ó dá ohun gbogbo tí ó wà ní ayé; ṣùgbọ́n èmi kò mọ̀ nípa àwọn ọ̀run.

30 Ámọ́nì sì wí fún un pé: Ọ̀run jẹ́ ibi tí Ọlọ́run ngbé ati gbogbo àwọn ángẹ́lì mímọ́ rẹ̀.

31 Ọba Lámónì sì wípé: Ṣe òkè ayé ni ó wà ni?

32 Ámọ́nì sì wípé: Bẹ̃ni, òun a sì máa bojúwò gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn nísàlẹ̀; òun sì mọ gbogbo èrò inú ọkàn; nítorítí nípa ọwọ́ rẹ ni a dá nwọn ní àtètèkọ́ṣe.

33 Ọba Lámónì wípé: Mo gba ohun wọ̀nyí gbogbo gbọ́ tí ìwọ ti sọ. Njẹ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti rán ọ wá?

34 Ámọ́nì wí fún un pé: Ènìyàn ni èmi íṣe; a sì dá ènìyàn ní àtètèkọ́ṣe ní àwòrán Ọlọ́run, a sì pè mí nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rè láti kọ́ àwọn ènìyàn yí ní àwọn ohun wọ̀nyí, kí a lè mú wọn wá ìmọ̀ èyítí ó tọ́ tí ó sì jẹ́ òtítọ́;

35 Apákan Ẹ̀mí ná ni sì ngbé inú mi, èyítí ó nfún mi ní ìmọ̀, pẹ̀lú agbára gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ mi àti ìfẹ́ ọkàn mi tí nwọn nbẹ nínú Ọlọ́run.

36 Nísisìyí nigbati Ámọ́nì sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó bẹ̀rẹ̀ láti dídá ayé sílẹ̀, àti dídá Ádámù, ó sì sọ ohun gbogbo fún un nípa ìṣubú ènìyàn, ó sì tún sọọ́ ní yékéyéké, àwọn àkọsílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ àwọn ènìyàn nã, tí àwọn wòlĩ ti sọ nípa nwọn àní títí dé ìgbà tí Léhì bàbá nwọn fi kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

37 Ó sì tún sọọ́ yé nwọn yékéyéké (nítorítí ó ṣe èyí sí ọba àti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ) gbogbo ìrìnàjò àwọn bàbá nwọn nínú aginjù, àti gbogbo ìpọ́njú nwọn pẹ̀lú ebi àti òùngbẹ, àti ìdãmú nwọn, àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

38 Ó sì tún sọọ́ ní yéké fún nwọn nípa ọ̀tẹ̀ Lámánì pẹ̀lú Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn ọmọ Íṣmáẹ́lì, bẹ̃ni, gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ nwọn ni ó rò fún nwọn; ó sì ṣe àlàyé fún nwọn lórí àwọn àkọsílẹ̀ àti àwọn ìwé-mímọ́ láti ìgbà tí Léhì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, títí dé àkokò yí.

39 Ṣùgbọ́n èyí nìkan kọ́; nítorítí ó ṣe àlàyé nípa ìlànà ìràpadà fún nwọn, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; òun sì sọ fún nwọn nípa bíbọ̀ Krístì, gbogbo iṣẹ́ Olúwa ni òun sì sọ nípa rẹ̀ fún nwọn.

40 Ó sì ṣe nígbàtí ó ti sọ gbogbo nkan wọ̀nyí tán, tí ó sì ṣe àlàyé lórí nwọn fún ọba, ni ọba sì gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.

41 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé Olúwa, wípé: Á! Olúwa, ṣãnú; gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀ ãnú rẹ èyítí ìwọ ti ní fún àwọn ènìyàn Nífáì, ṣãnú fún mi, àti àwọn ènìyàn mi.

42 Àti nísisìyí, nígbàtí ó sọ eleyĩ tán, ó ṣubú lulẹ̀, bí ẹnipé ó ti kú.

43 Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ múu, tí nwọ́n sì gbée lọ sí ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀, nwọ́n sì gbée sórí ibùsùn kan; òun sì sùn bí ẹnipé ó ti kú fún ìwọ̀n ọjọ́ méjì àti òru méjì; ìyàwó rẹ, àti àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ obìnrin rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn ará Lámánì; tí nwọ́n sì ndárò lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ikú rẹ.