Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 11


Orí 11

A gbé ètò ìṣirò owó kalẹ̀ fún àwọn ará Nífáì—Ámúlẹ́kì bá Sísrọ́mù jà—Krístì kì yíò gba àwọn ènìyàn là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn—Àwọn tí ó bá jogún ìjọba ọ̀run nìkan ni a gbàlà—Gbogbo ènìyàn ni yíò jínde sínú ipò àìkú ayérayé—Kò sí ikú lẹ́hìn Àjĩnde. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Báyĩ sì ni ó rí nínú òfin Mòsíà pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá jẹ́ adájọ́ ti òfin, tàbí àwọn tí a yàn láti jẹ́ onídàjọ́, ní ẹ̀tọ́ láti gba owó ọya ní ìbámu pẹ̀lú àsìkò tí nwọ́n fi ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí a bá mú tọ̀ nwọ́n wá fún ìdájọ́.

2 Nísisìyí bí ẹnìkan bá jẹ òmíràn ní gbèsè owó, tí òun kò sì san èyítí ó jẹ, tí a sì fi sun adájọ́; tí adájọ́ sì lo àṣẹ rẹ̀, tí ó sì rán àwọn oníṣẹ́ rẹ láti mú ọkùnrin nã wá sí iwájú òun; tí ó sì ṣe ìdájọ́ fún ọkùnrin nã ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti ẹ̀rí tí nwọ́n jẹ́ síi, tí a sì fi ipá múu kí ó san gbèsè tí ó jẹ, tàbí kí a gba gbogbo ohun ìní rẹ, tàbí kí a lée jáde kúrò lãrín àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí olè tàbí ọlọ́ṣà.

3 Adájọ́ nã sì gba owó ọya rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àkokò tí ó lò—ìwọ̀n wúrà kan fún ọjọ́ kan, tàbí ìwọ̀n fàdákà kan, èyítí íṣe ìwọ̀n wúrà kan; èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí nwọ́n ṣe.

4 Nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn onírurú ẹyọ wúrà nwọn, àti ti fàdákà nwọn, gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti níye lórí. Àwọn ará Nífáì ni ó sì fún nwọn lórúkọ nã, nítorítí àwọn kò ṣe ìṣirò oye-orí gẹ́gẹ́bí àwọn Jũ tí nwọ́n wà ní Jerúsálẹ́mù tií ṣe; bẹ̃ ni nwọn kò díwọ̀n gẹ́gẹ́bí àwọn Jũ; ṣùgbọ́n nwọ́n yí ìṣirò oye-orí ti nwọn padà, pẹ̀lú ìṣirò-ìwọ̀n nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú ọkàn àti ipò tí àwọn ènìyàn nã bá wà, ní ìran kan dé òmíràn, títí dé ìjọba àwọn onídàjọ́, àwọn èyítí ọba Mòsíà ti ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀.

5 Nísisìyí ìṣirò nã ni èyí—sénínì wúrà kan, séónì wúrà kan, ṣọ́mù wúrà kan, àti límnà wúrà kan.

6 Sẹ́númù fàdákà kan, ámnórì fàdákà kan, ésrómù fàdákà kan àti ọ́ntì fàdákà kan.

7 Ẹyọ sénúmù fàdákà kan jẹ́ ẹyọ sénínì wúrà kan, èyíkẽyí wọ̀n sì jẹ́ ìwọ̀n barley kan, àti pẹ̀lú ó sì wà fún ìwọ̀n onírũrú ọkà.

8 Báyĩ iye-orí séónì kan jẹ́ ìlópo méjì iye sẹ́nínì kan.

9 Ìwọ̀n ṣọ́mù wúrà kan sì jẹ́ ìlọ́po méjì iye-orí ìwọ̀n séonì kan.

10 Ìwọ̀n límnà wúrà kan sì jẹ́ iye-orí gbogbo àwọn yĩ.

11 Ìwọ̀n ámnórì fàdákà kan sí níye lórí tó sénúmù méjì.

12 Ìwọ̀n ésrọ́mù fàdákà kan sì níye lórí tó sénúmù mẹ́rin.

13 Ìwọ̀n ọ́ntì kan sì níye lórí tó gbogbo àwọn wọ̀nyí.

14 Èyí sì ni iye-orí àwọn ìṣirò nwọn kékèké—

15 Ìwọ̀n ṣíblọ́nì kan jẹ́ ìdajì sénúmù; nítorínã ìwọ̀n ṣíblọ́nì kan jẹ́ ìdajì ìwọ̀n barley kan.

16 Ìwọ̀n ṣíblúmù kan jẹ́ ìdajì ìwọ̀n ṣíblọ́nì.

17 Ìwọ̀n léù kan sì jẹ́ ìdajì ìwọ̀n ṣíblúmù.

18 Báyĩ sì ni iye nwọn, gẹ́gẹ́bí ìṣirò nwọn.

19 Báyĩ ìwọ̀n ántíónì kan ti wúrà jẹ́ ìwọ̀n mẹ́ta ṣíblónì.

20 Nísisìyí, èyí wà fún ìdí pàtàkì láti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrè, nítorítí nwọ́n ngba owó ọya nwọn gẹ́gẹ́bí nwọ́n ṣe ṣiṣẹ́ sí, nítorínã, nwọn a máa rú àwọn ènìyàn sókè sí ìrúkèrúdò, àti onírurú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àti ìwà búburú, pé kí nwọ́n lè rí iṣẹ́ ṣe síi, pé kí nwọ́n lè gba owó gẹ́gẹ́bí àwọn ẹjọ́ tí nwọ́n gbé wá síwáju nwọn; nítorínã ni nwọ́n ṣe nrú àwọn ènìyàn sókè tako Álmà àti Ámúlẹ́kì.

21 Sísrọ́mù yí sì bẹ̀rẹ̀sí bí Ámúlẹ́kì lẹ́jọ́ pé: Njẹ́ ìwọ yíò dáhùn ìbẽrè díẹ̀ tí èmi yíò bí ọ́? Báyĩ Sísrọ́mù jẹ́ ènìyàn tí ó jáfáfá nínú àwọn ète èṣù, láti lè pa ohun tí ó dára run; nítorínã, ó wí fún Ámúlẹ́kì: Njẹ́ ìwọ yíò dáhùn àwọn ìbẽrè tí èmi yíò bí ọ́?

22 Ámúlẹ́kì sì wí fún un pé: Bẹ̃ ni, tí o bá bá Ẹ̀mí-Mímọ́ Olúwa mu, èyítí ó wà nínú mi; nítorítí èmi kò ní sọ ohunkóhun tí ó lòdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ Olúwa. Sísrọ́mù sì wí fún un pé: wõ, óntì fàdákà mẹ́fà ni èyí, gbogbo èyí ni èmi yíò sì fi fún ọ tí ìwọ bá lè sẹ́ wíwà Ọlọ́run Ẹnití-O-Tóbi-Jùlọ.

23 Nísisìyí Ámúlẹ́kì wípé: Á!, ìwọ ọmọ ọ̀run-àpãdì, ẽṣe tí ìwọ ndán mi wò? Ìwọ kò ha mọ̀ pé olódodo kò lè jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún irú àdánwò bí èyí?

24 Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé kò sí Ọlọ́run? Èmi wí fún ọ, Rárá, ìwọ mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà, ṣùgbọ́n ìwọ fẹ́ràn owó jũ lọ.

25 Àti nísisìyí ìwọ níye ti purọ́ fún mi níwájú Ọlọ́run. Ìwọ wí fún mi pé—Wo àwọn óntì mẹ́fà wọ̀nyí, tí nwọ́n níye lórí púpọ̀púpọ̀, èmi yíò fi fún ọ—nígbàtí ìwọ níi lọ́kàn rẹ láti fi wọ́n pamọ́ fún mi; tí ó sì jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ nìkan ni kí èmi ó sẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè, kí ìwọ kí ó lè ní ìdí láti pa mi run. Àti nísisìyí kíyèsĩ, fún ìwà búburú nlá yĩ, ìwọ yíò gba èrè rẹ.

26 Sísrọ́mù sì wí fún un pé: Ìwọ wípé Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè nbẹ bí?

27 Ámúlẹ́kì sì wípé: Bẹ̃ni, Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè nbẹ.

28 Báyĩ Sísrọ́mù sọ wípé: Njẹ́ ó ju Ọlọ́run kanṣoṣo tí ó nbẹ?

29 Òun sì dáhùn pé, Rárá.

30 Báyĩ Sísrọ́mù tún wí fún un pé: Báwo ni ìwọ ṣe mọ́ ohun wọ̀nyí?

31 Òun sì sọ wípé: Ángẹ́lì kan ni ó ti fi nwọ́n mọ̀ fún mi.

32 Sísrọ́mù sì tún wípé: Tani ẹni nã tí nbọ̀wá? Njẹ́ Ọmọ Ọlọ́run ha ni bí?

33 Ó sì wí fún un pé, bẹ̃ni.

34 Sísrọ́mù tún wípé: Njẹ́ òun yíò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn bí? Ámúlẹ́kì sì dáhùn ó sì wí fún un pé: Èmi wí fún ọ, òun kò ní ṣe èyí, nítorítí ó ṣòro fún un láti sẹ́ ọ̀rọ̀ọ rẹ̀.

35 Nísisìyí Sísrọ́mù wí fún àwọn ènìyàn nã: Kí ẹ rántí àwọn ohun wọ̀nyí; nítorítí ó wípé Ọlọ́run kan ni ó wà; síbẹ̀ ó tún wí pé Ọmọ Ọlọ́run nbọ̀wá, ṣùgbọ́n kò ní gba àwọn ènìyàn là—bí èyítí òun ní àṣẹ láti pàṣẹ fún Ọlọ́run.

36 Nísisìyí Ámúlẹ́kì tún wí fún un pé: Kíyèsĩ ìwọ purọ́, nítorítí ìwọ sọ wípé èmi nsọ̀rọ̀ bí ẹni tí ó ní àṣẹ láti pàṣẹ fún Ọlọ́run nítorí èmi wípé òun kì yíò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

37 Èmi sì tún wí fún ọ pé òun kò lè gbà nwọ́n là nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; nítorítí èmi kò lè sẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ, òun sì ti sọ wípé ohun àìmọ́ kan kò lè jogún ìjọba ọ̀run; nítorínã, báwo ni ẹ̀yin yíò ṣe gbàlà, àfi tí ẹ̀yin bá jogún ìjọba ọ̀run? Nítorínã, ẹ̀yin kò lè rí ìgbàlà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.

38 Nísisìyí Sísrọ́mù tún wí fún un pé: Njẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nã ni Bàbá Ayérayé nã?

39 Ámúlẹ́kì sì wí fún un pé: Bẹ̃ni, òun ni Bàbá Ayérayé ti ọ̀run òun ayé, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, ìkínní àti ìgbẹ̀hìn;

40 Òun yíò sì wá sínú ayé láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà; òun yíò sì gba àwọn ìwà ìrékọjá àwọn tí ó gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ lé ara rẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni nwọn yíò sì ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìgbàlà kò sì sí fún ẹlòmíràn.

41 Nítorínã, àwọn ènìyàn búburú wà bí ẹnipé a kò ṣe ìràpadà, àfi ti títú ìdè ikú; nítorí kíyèsĩ, ọjọ́ nã nbọ̀wá tí gbogbo ènìyàn yíò jínde kúrò nínú òkú, tí nwọn yíò sì dúró níwájú Ọlọ́run, tí a ó sì dájọ́ fún nwọn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn.

42 Nísisìyí, ikú kan wà èyítí à npè ní ikú ti ara; ikú ti Krístì yíò sì tú ìdè ikú ti ara yĩ, tí gbogbo ènìyàn yíò fi jínde kúrò nínú ikú ti ara yĩ.

43 Ẹ̀mí àti ara yíò tún darapọ̀ sí ipò pípé nwọn; àwọn ẹ̀yà ara àti oríkẽ ara ni a ó dá padà sí ipò nwọn, àní bí àwa ṣe wà ní àkọ́kọ́ yĩ; a ó sì mú wa dúró níwájú Ọlọ́run, tí àwa yíò sì mọ̀ gẹ́gẹ́bí àwa ṣe mọ̀ nísisìyí, tí a ó sì ní ìrántí tí ó yè kõro sí gbogbo ìdálẹ́bi wa.

44 Nísisìyí, ìdápadà sípò yí yíò wá fún gbogbo ènìyàn, gbogbo ẹ̀nítí ó dàgbà àti ẹ̀nítí ó jẹ́ ọmọdé, gbogbo ẹnití ó wà ní ìdè tàbí ní òminira, gbogbo ọkùnrin àti obìnrin, gbogbo ènìyàn búburú àti olódodo; àti pãpã, ẹyọ irun orí nwọn kan kò ní sọnù; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni a ó da padà sí ipò rẹ pípé, bí ó ṣe wà nísisìyí, tàbí ní ti ara yĩ, tí a ó sì mú nwọn wá sí iwájú ìtẹ́ Krístì tí íṣe Ọmọ, àti Ọlọ́run tí íṣe Bàbá, àti Ẹ̀mí Mímọ́, tí íṣe Ọlọ́run Ayérayé ọ̀kanṣoṣo, láti ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí iṣẹ wọn, ní ti rere tàbí ní ti búburú.

45 Nísisìyí, kíyèsĩ, mo ti bá yín sọ̀rọ̀ nípa ikú ti ara, àti nípa àjĩnde ara. Èmi wí fún yín pé ara yĩ ni a ó gbé dìde sí ara àìkú, àní kúrò nínú ikú, àní kúrò nínú ikú ìkíní, sí ìyè, tí nwọn kò lè kú mọ́; tí ẹ̀mí nwọn yíò sì dàpọ̀ mọ́ ara nwọn, tí nwọn kò ní pínyà mọ́; tí gbogbo ara yíò sì di ti ẹ̀mí ati àìkú, tí nwọn kò sì lè rí ìbàjẹ́ mọ́.

46 Nísisìyí, nígbàtí Ámúlẹ́kì ti parí àwọn ọ̀rọ̀ yí, ẹnu tún bẹ̀rẹ̀sí ya àwọn ènìyàn nã, àti Sísrọ́mù pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀sí wá rìrì. Èyí sì jẹ́ òpin ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì, tàbí pé èyí ni àwọn ohun tí èmi kọ.