Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 17


Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Mòsíà, tí nwọ́n kọ̀ ẹ̀tọ́ nwọn sí ìjọba, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí nwọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Nífáì láti wãsù sí àwọn ará Lámánì ìjìyà nwọn àti ìtúsílẹ̀ nwọn—gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ èyítí Álmà ṣe.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 17 títí ó fi dé 27 ní àkópọ̀.

Orí 17

Àwọn ọmọ Mòsíà ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, àti ti ìfihàn—Nwọ́n nlọ kãkiri láti kéde ọ̀rọ̀ nã fún àwọn ará Lámánì—Ámọ́nì lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, ó sì di ọmọ-ọ̀dọ̀ Ọba Lámónì—Ámọ́nì kó àwọn agbo ẹran ọba yọ nínú ewu, ó sì pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní etí odò Sébúsì. Ẹsẹ 1 sí 3, jẹ́ ní ìwọ̀n ọdún 77 kí a tó bí Olúwa wa; ẹsẹ 4 jẹ́ ní ìwọ̀n ọdún 91 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa; ẹsẹ 5 sí 39 sì jẹ́ ní ìwọ̀n ọdún 91 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà nrin ìrìn-àjò láti ilẹ̀ Gídéónì lọ sí ìhà gúsù, lọ sí ilẹ̀ Mántì, sa wõ, sí ìyàlẹ́nu rẹ, ó bá àwọn ọmọ Mòsíà pàdé tí nwọ́n nrin ìrìn-àjò lọ sí ìhà ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

2 Nísisìyí, àwọn ọmọ Mòsíà wọ̀nyí wà pẹ̀lú Álmà ní àkokò tí ángẹ́lì kọ́kọ́ yọ sí i; nítorínã, Álmà yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti rí àwọn arákùnrin rẹ̀; èyítí ó sì fi kún ayọ̀ rẹ̀ ni pé nwọ́n ṣì jẹ́ arákùnrin rẹ̀ nínú Olúwa; bẹ̃ni, nwọ́n sì ti di alágbára nínú ìmọ̀ òtítọ́; nítorítí nwọ́n jẹ́ ẹnití ó ní ìmọ̀ tí ó jinlẹ̀, nwọ́n sì ti wá inú ìwé-mímọ́ láìsimi, kí nwọ́n lè mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

3 Ṣùgbọ́n èyí nìkan kọ́; nwọn ti fi ara nwọn fún ọ̀pọ̀ àdúrà, àti ãwẹ̀; nítorínã nwọ́n ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ẹ̀mí ìfihàn, tí nwọ́n bá sì kọ́ni, nwọ́n nkọ́ni pẹ̀lú agbára àti àṣẹ Ọlọ́run.

4 Nwọ́n sì ti nkọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìwọ̀n ọdún mẹ́rìnlá lãrín àwọn ará Lámánì, tí nwọ́n sì ti ṣe àṣeyọrí púpọ̀ nípa mímú ọ̀pọ̀ wá sí ìmọ̀ òtítọ́; bẹ̃ni, nípa agbára ọ̀rọ̀ nwọn, a mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá síwájú pẹpẹ Ọlọ́run, láti képe orúkọ rẹ, kí nwọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn níwájú rẹ̀.

5 Nísisìyí, àwọn ohun wọ̀nyí ni nwọ́n rí nínú ìrìnàjò nwọn, nítorítí nwọ́n rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú; nwọ́n sì jìyà lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti ara àti ti ọkàn, bí ebi, òùngbẹ àti ãrẹ̀, pẹ̀lú ìyọ́nú nínú ẹ̀mí.

6 Nísisìyí èyí ni àwọn ìrìnàjò nwọn; lẹ́hìn tí nwọ́n ti dágbére fún bàbá nwọn, Mòsíà, ní ọdún kíni àwọn onídàjọ́; lẹ́hìn tí nwọn ti kọ ìjọba ti bàbá nwọn fẹ́ gbé lé nwọn lọ́wọ́, èyí tí ó sì jẹ́ èrò àwọn ènìyàn;

7 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n lọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọn sì mú idà nwọn, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ nwọn, àti ọrun nwọn, àti ọfà nwọn, àti kànnà-kànnà nwọn, èyí ni nwọ́n ṣe kí nwọ́n lè pèsè oúnjẹ fún ara nwọn nínú aginjù.

8 Báyĩ sì ni nwọ́n kọjá lọ sínú aginjù pẹ̀lú iye awọn tí nwọ́n ti yàn, láti lọ sí ilẹ̀ Nífáì, lati wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ará Lámánì.

9 Ó sì ṣe tí nwọ́n rin ìrìnàjò fún ọjọ́ pípẹ́ nínú aginjù, tí nwọ́n sì gbãwẹ̀ pẹ̀lú àdúrà púpọ̀ pé kí Olúwa kí ó fún nwọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ kí ó bá nwọn lọ, kí ó sì gbé pẹ̀lú nwọn, kí nwọ́n lè jẹ ohun èlò lọ́wọ́ Ọlọ́run láti mú àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, tí ó bá leè rí bẹ̃, bọ́ sí inú ìmọ̀ otítọ́, sí inú ìmọ̀ àṣà àìpé àwọn bàbá nwọn, èyítí kò tọ̀nà.

10 Ó sì ṣe tí Olúwa bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀, tí ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ gba ìtùnú. A sì tù wọ́n nínú.

11 Olúwa sì wí fún nwọn pẹ̀lú pé: Ẹ lọ sí ãrin àwọn ará Lámánì, àwọn arákùnrin yín, kí ẹ sì gbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin níláti ní ìlọ́ra nínú ìpamọ́ra àti ìpọ́njú, kí ẹ̀yin lè jẹ́ àpẹrẹ rere fún nwọn nínú mi, èmi yíò sì ṣe yín ní ohun èlò ní ọwọ́ mi sí ìgbàlà ọkàn púpọ̀.

12 Ó sì ṣe tí ọkàn àwọn ọmọ Mòsíà pẹ̀lú àwọn tí ó wà pẹ̀lú nwọn, ní ìgboyà láti tọ àwọn ará Lámánì lọ láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún nwọn.

13 Ó sì ṣe nígbàtí nwọn dé agbègbè etí ìlú ilẹ̀ àwọn ará Lámánì, nwọ́n pín ara nwọn sí ọ̀tọ̃tọ̀, nwọ́n sì pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara nwọn, tí nwọ́n sì ní ìrètí nínú Olúwa pé nwọn yíò tun pàdé lẹ́hìn ìkórè nwọn; nítorítí nwọ́n mọ̀ wípé títóbi ni iṣẹ́ tí àwọn ti dáwọ́lé íṣe.

14 Àti pé dájúdájú, títóbi sì nií ṣe, nítorítí nwọn ti dawọ́lé ìwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn tí ó le, tí nwọ́n sì rorò; àwọn ènìyàn tí nwọ́n dunnú sí pípa àwọn ará Nífáì, àti jíjà nwọn ní ólè àti ṣíṣe ìkógun nwọn; ọkàn nwọn sì wà nínú ọrọ̀, tàbí nínú wúrà àti fàdákà, àti òkúta oníyebíye; síbẹ̀ nwọn a máa wá ọ̀nà àti gba ohun wọ̀nyí nípa ìpànìyàn àti ìkógun, kí nwọ́n má bã ṣiṣẹ́ fún nwọn pẹ̀lú ọwọ́ nwọn.

15 Báyĩ ni nwọ́n sì jẹ́ ọ̀lẹ ènìyàn, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn a sì máa bọ òrìṣà, tí ẹ̀gún Ọlọ́run ti bà lé nwọn lórí nítorí àṣà àwọn bàbá nwọn; l’áìṣírò, ìlérí Olúwa wà fún nwọn bí nwọ́n bá rònúpìwàdà.

16 Nítorínã èyí ni ìdí tí àwọn ọmọ Mòsíà ṣe dáwọ́lé iṣẹ́ nã, pé bóyá nwọn yíò mú nwọn wá sí ìrònúpìwàdà; pé bóyá nwọ́n ó mú nwọn mọ́ ìlànà ìràpadà.

17 Nítorínã nwọ́n yára nwọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara nwọn, nwọ́n sì kọjá lọ sí ãrin nwọn, olúkúlùkù lọ́tọ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ àti agbára Ọlọ́run tí a ti fún un.

18 Nísisìyí nítorítí Ámọ́nì jẹ́ olórí lãrín nwọn, tàbí pé òun ni ó ntọ́ nwọn sọ́nà, ó kúrò lãrín nwọn lẹ́hìn tí ó ti súre fún nwọn gẹ́gẹ́bí ipò àti ipè olúkúlùkù, lẹ́hìn tí ó ti kọ́ nwọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí tí ó ti tọ́ nwọn sọ́nà, kí ó tó kọjá lọ kúrò; báyĩ ni nwọ́n sì lọ sí ìrìnàjò nwọn jákè-jádò ilẹ̀ nã.

19 Ámọ́nì sì lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, ilẹ̀ èyítí a pe ní órúkọ àwọn ọmọ ọkùnrin Íṣmáẹ́lì, tí nwọ́n ti di ara àwọn ará Lámánì.

20 Bí Ámọ́nì sì ṣe wọ inú ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, àwọn ará Lámánì múu, nwọ́n sì dẽ, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà nwọn láti de gbogbo ará Nífáì tí ó bá bọ́ sí nwọn lọ́wọ́, tí nwọn ó sì gbé nwọn lọ síwájú ọba; bayi ni yio sì jẹ ìdùnnú oba lati pa wọn, tabi ki o fi wọn sílẹ̀ ninu ìgbèkùn, tabi kí o gbé wọn si inú túbú, tabi ki o le wọn jáde kuro nínú ìlẹ̀ rẹ̀; gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ ati ìdùnnú rẹ̀.

21 Báyĩ sì ni nwọn gbé Ámọ́nì lọ siwaju ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; tí orúkọ rẹ̀ sì íṣe Lámónì; ọmọ àtẹ̀lé Íṣmáẹ́lì nií sĩ ṣe.

22 Ọba nã sì bẽrè lọ́wọ́ Ámọ́nì bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ inúu rẹ̀ láti gbé inú ìlú nã lãrín àwọn ará Lámánì, tàbí lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

23 Ámọ́nì sì wí fún un pé: Bẹ̃ni, mo fẹ́ láti gbé lãrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún àkokò díẹ̀; bẹ̃ni, bóyá títí ọjọ́ ikú mi.

24 Ó sì ṣe tí inú ọba Lámónì dùn púpọ̀ sí Ámọ́nì, tí ó sì ní kí nwọ́n tú ìdè rẹ̀; tí ó sì fẹ́ kí Ámọ́nì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe aya.

25 Ṣùgbọ́n Ámọ́nì wí fún un pé: Rárá, ṣùgbọ́n èmi yíò jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ. Nítorínã Ámọ́nì di ọmọ-ọ̀dọ̀ fún Lámónì ọba. Ó sì ṣe tí a fi sí ãrin àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ yókù láti ṣọ́ àwọn agbo ẹran Lámónì, gẹ́gẹ́bí àṣà àwọn ará Lámánì.

26 Nígbàtí ó sì ti nṣiṣẹ́-ìsìn fún ọba fún ọjọ́ mẹ́ta, bí ó sì ti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ Lámónì tí wọ́n jẹ́ ará Lámánì, tí nwọn nlọ pẹ̀lú agbo-ẹran nwọn sí ibi omi, èyítí à npè ní omi Sébúsì, gbogbo àwọn ará Lámánì nã ni nwọn a sì máa da agbo ẹran nwọn wá síbẹ̀, kí nwọ́n lè mumi.

27 Nítorínã, bí Ámọ́nì pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ọba ti nda agbo ẹran nwọn lọ sí ibi omi yìi, wòo, àwọn ará Lámánì kan, tí nwọ́n ti wà pẹ̀lú agbo ẹran nwọn láti fún nwọn lómi, dúró, nwọ́n sì tú àwọn agbo ẹran Ámọ́nì àti ti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba ká, nwọ́n sì tú nwọn ká tó bẹ́ẹ̀ tí nwọ́n fi sá kãkiri ọ̀nà púpọ̀.

28 Nísisìyí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba bẹ̀rẹ̀sí ráhùn wípé: Ní báyĩ ọba yíò pa wá, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe pa àwọn arákùnrin wa, nígbàtí àwọn ẹni búburú wọ̀nyí tú agbo-ẹran nwọn ká. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sọkún púpọ̀púpọ̀, nwọ́n nwípé: Wõ, gbogbo agbo-ẹran wa ni nwọ́n ti túká.

29 Báyĩ nwọ́n sọkún nítorí ìbẹ̀rù pé a ó pa nwọ́n. Bí Ámọ́nì ṣe rí èyí ọkàn an rẹ̀ kún fún ayọ̀ nínũ rẹ̀; nítorítí, ó wípé, èmi yíò fi agbára mi han àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ mi, tàbí agbára èyítí nbẹ nínú mi, fún ìdápadà àwọn agbo-ẹran wọ̀nyí sí ọ́dọ̀ ọba, kí èmi kí ó lè rí ojú-rere àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlẹ́gbẹ́ mi, kí èmi kí ó lè tọ́ nwọn sọ́nà gbígba ọ̀rọ̀ mi gbọ́.

30 Àti nísisìyí, àwọn yìi ni èrò ọkàn Ámọ́nì, nígbàtí ó rí ìjìyà àwọn tí ó pè ní arákùnrin rẹ̀.

31 Ó sì ṣe tí ó sọ̀rọ̀ ìṣírí sí nwọn, tí ó wípé: Ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ tújúká kí ẹ sì jẹ́ kí àwa kí ó wá àwọn agbo-ẹran wa lọ, àwa yíò sì gba nwọn jọ, a ó sì kó nwọn padà wá sí ibi omi; báyĩ àwa yíò pa àwọn agbo-ẹran nã mọ́ fún ọba, òun kò sì ní pa wá.

32 Ó sì ṣe tí nwọ́n wá àwọn agbo-ẹran nã lọ, nwọ́n sì tẹ̀lé Ámọ́nì, nwọ́n sì sáré síwájú kánkán, ṣãju àwọn agbo-ẹran ọba, nwọ́n sì tún kó nwọn jọ lọ sí ibi omi.

33 Àwọn ọkùnrin nã tún dúró láti tú agbo-ẹran nwọn ká; ṣùgbọ́n Ámọ́nì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: Ẹ pagbo yí àwọn agbo-ẹran nã ká, kí nwọn má lè sálọ; èmi yíò sì lọ dojú ìjà kọ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí nwọn ntú àwọn agbo-ẹran wa ká.

34 Nítorínã, nwọ́n ṣe gẹ́gẹ́bí Ámọ́nì ṣe pàṣẹ fún nwọn, ó sì lọ ó dúró láti dojú ìjà kọ àwọn tí ó dúró ní ẹ̀bá omi Sébúsì; iye nwọn kò sì kéré rárá.

35 Nítorínã nwọn kò bẹ̀rù Ámọ́nì, nítorítí nwọ́n rò pé ọkàn nínú nwọn lè pa ní ìrọ̀rùn, nítorípé nwọn kò mọ̀ pé Olúwa ti ṣèlérí pẹ̀lú Mòsíà pé òun yíò yọ àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ nwọn; bẹ̃ sì ni nwọn kò mọ́ ohunkóhun nípa Olúwa; nítorínã ni nwọ́n ṣe nyọ̀ nínú ìparun àwọn arákùnrin nwọn; nítorí ìdí èyí ni nwọ́n ṣe dúró láti tú agbo-ẹran ọba ká.

36 Ṣùgbọ́n Ámọ́nì dúró lókẽrè, ó sì bẹ̀rẹ̀sí sọ òkò sí nwọn pẹ̀lú kànnà-kànnà rẹ̀; bẹ̃ni, pẹ̀lú agbára nlá ni ó fi sọ òkò sí ãrin nwọn; bẹ̃ni ó sì pa nínú nwọn tó bẹ̃ tí ẹnu bẹ̀rẹ̀sí yà nwọ́n nípa agbára rẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ inú bí nwọn nítorí àwọn arákùnrin nwọn tí ó ti pa, tí nwọ́n sì pinnu pé nwọn yíò ṣẹ́gun nwọn; nígbàtí nwọn sì ríi pé òkò nwọn kò bã, nwọ́n wá pẹ̀lú kùmọ̀ láti fi paá.

37 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, gbogbo ẹnití ó gbé kùmọ̀ sókè láti lu Ámọ́nì, ni ó gé apá rẹ kúrò pẹ̀lú idà rẹ; nítorítí ó tako lílù nwọ́n nípa gígé apá nwọn pẹ̀lú idà rẹ̀, tó bẹ̃ tí ẹnu bẹ̀rẹ̀sí yà nwọ́n, tí nwọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀; bẹ̃ni, nwọn kò sì mọ́ díẹ̀ ní iye rárá; ó sì lé nwọn sá nípa agbára ọwọ́ rẹ.

38 Nísisìyí, àwọn mẹ́fà nínú nwọn ni ó ti ṣubú nípa kànnà-kànnà nã, ṣùgbọ́n kò pa ọ̀kan nínú nwọn, àfi olórí nwọn pẹ̀lú idà rẹ; ó sì gé apá gbogbo àwọn tí nwọ́n kọlũ kúrò, nwọn kò sì mọ́ ní díẹ̀ rárá.

39 Nígbàtí ó sì ti lé nwọn jìnà réré, ó padà nwọ́n sì fún àwọn agbo-ẹran nwọn lómi, nwọ́n sì dá nwọn padà sínú pápá oko ọba, nwọ́n sì tọ ọba lọ, pẹ̀lú àwọn apá tí idà Ámọ́nì ti gé kúrò, tí àwọn tí nwọ́n fẹ́ paa; nwọ́n sì gbé nwọn tọ ọba lọ fún ẹ̀rí ohun tí nwọ́n ti ṣe.