Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 33


Orí 33

Sénọ́sì kọ́ni pé kí ènìyàn ó máa gbàdúrà kí nwọ́n sì máa jọ́sìn ní ibi gbogbo, àti pé a mú ìdánilẹ́bi kúrò nítorí Ọmọ nã—Sénọ́kì kọ́ni pé ènìyàn nrí ãnú gbà nítorí Ọmọ nã—Mósè ti gbé irú ẹ̀yà Ọmọ Ọlọ́run sókè nínú aginjù. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí, lẹ́hìn tí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, nwọ́n ránṣẹ́ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti mọ̀ bóyá kí àwọn gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kanṣoṣo, pé kí nwọn lè rí èso nã gbà èyítí ó ti sọ nípa rẹ̀, tàbí bí nwọn ó ṣe gbin irúgbìn nã, tàbí ọ̀rọ̀ nã èyítí ó ti sọ nípa rẹ̀, tí ó ní a níláti gbìn sínú ọkàn nwọn; tàbí báwo ni kí nwọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀sí lò ìgbàgbọ́ nwọn.

2 Álmà sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti sọ wípé ẹ kò lè sin Ọlọ́run nyín nítorípé nwọ́n lée nyín jáde kúrò nínú sínágọ́gù nyin. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, bí ẹ̀yin bá rò pé ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run, ẹ̀yin ṣìnà gidigidi, ó sì yẹ kí ẹ̀yin wá inú ìwé-mímọ́; bí ẹ̀yin bá rò pé nwọ́n ti kọ́ọ nyín ní ohun yĩ, nwọn kò yée nyín.

3 Njẹ́ ẹ̀yin ha rántí pé ẹ ti kà nípa ohun tí Sénọ́sì, wòlĩ ìgbà nnì, ti sọ nípa àdúrà àti ìjọ́sìn bí?

4 Nítorítí ó wípé: Alãnú ni ìwọ íṣe, A! Ọlọ́run, nítorítí ìwọ ti gbọ́ àdúrà mi, àní nígbàtí mo wà nínú aginjù; bẹ̃ni, ìwọ ṣãnú nígbàtí mo gbàdúrà nípa àwọn tí nwọn jẹ́ ọ̀tá mi, ìwọ sì mú nwọn yọ́nú sí mi.

5 Bẹ̃ni, A! Ọlọ́run, ìwọ sì ṣãnú fún mi nígbàtí mo ké pè ọ́ nínú pápá mi; nígbàtí èmi ké pè ọ́ nínú àdúrà mi, ìwọ sì gbọ́ mi.

6 Àti pẹ̀lú, A! Ọlọ́run, nígbàtí èmi lọ sínú ilé mi, ìwọ gbọ́ mi nínú àdúrà mi.

7 Nígbàtí èmi sì wọ inú ìyẹ̀wù mi lọ, A! Olúwa, tí mo sì gbàdúrà sí ọ, ìwọ gbọ́ mi.

8 Bẹ̃ni, ìwọ a máa ṣãnú fún àwọn ọmọ rẹ nígbàtí nwọ́n bá ké pè ọ́, kí ìwọ kí ó lè gbọ́ nwọn láìṣe ènìyàn, ìwọ yíò sì gbọ́ nwọn.

9 Bẹ̃ni, A! Ọlọ́run, ìwọ ti ṣãnú fún mi, ó sì ti gbọ́ igbe mi ní àwùjọ àwọn ènìyàn rẹ.

10 Bẹ̃ni, ìwọ sì ti gbọ́ mi pẹ̀lú nígbàtí nwọ́n lé mi jáde, tí àwọn ọ̀tá mi sì fi mí ṣẹ̀sín; bẹ̃ni, ìwọ gbọ́ igbe mi, o sì bínú sí àwọn ọ̀tá mi, ìwọ sì bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú rẹ pẹ̀lú ìparun kánkán.

11 Ìwọ sì gbọ́ mi nítorí ìpọ́njú mi àti òdodo mi; nítorí Ọmọ rẹ ni ìwọ sì ṣe ti ṣãnú fún mi báyĩ, nítorínã èmi yíò ké pè ọ́ nínú ìpọ́njú mi, nítorípé nínú rẹ ni ayọ̀ mi wà; nítorítí ìwọ ti mú ìdájọ́ rẹ kúrò lórí mi, nítorí ti Ọmọ rẹ.

12 Àti nísisìyí Álmà sì wí fún nwọn pé: Njẹ́ ẹ̀yin ha gba àwọn ìwé-mímọ́ tí àwọn ará ìgbà nnì kọ gbọ́ bí?

13 Ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá gbà nwọ́n gbọ́, ẹ ó gba ohun tí Sénọ́sì sọ gbọ́; nítorí, ẹ kíyèsĩ ó wípé: Ìwọ ti mú ìdájọ́ rẹ kúrò nítorí Ọmọ rẹ.

14 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi yíò bẽrè bí ẹ̀yin bá ti ka àwọn ìwé-mímọ́? Bí ẹ̀yin bá ti kà nwọ́n, báwo ni ẹ̀yin ṣe lè ṣe aláìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run?

15 Nítorítí a kò kọọ́ pé Sénọ́sì nìkan ni ó sọ nípa ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n Sénọ́kì nã sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí—

16 Nítorí, ẹ kíyèsĩ, ó wípé: Ìwọ nbínú, A! Olúwa, sí àwọn ènìyàn yĩ, nítorípé nwọn kò ní òye nípa ãnú rẹ tí ìwọ ti fi fún nwọn nítorí ti Ọmọ rẹ.

17 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin ríi pé wòlĩ kejì ìgbà nnì ti ṣe ìjẹ́rĩ sí nípa Ọmọ Ọlọ́run, àti nítorípé àwọn ènìyàn nã kọ̀ láti ní òye ọ̀rọ̀ rẹ̀ nwọ́n sọọ́ ní òkúta pa.

18 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyĩ nìkan kọ́; àwọn wọ̀nyí nìkan kọ́ ni ó ti sọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ọlọ́run.

19 Ẹ kíyèsĩ, Mósè sọ nípa rẹ̀; bẹ̃ni, kí ẹ sì wõ, a gbé irú rẹ̀ sókè nínú aginjù, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbé ojú sókè wò ó yíò yè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì wò ó tí nwọn sì yè.

20 Ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn tí ohun wọ̀nyí yé, èyí, nítorí líle ọkàn nwọn. Ṣùgbọ́n púpọ̀ ni àwọn tí ọkàn nwọn le tó bẹ̃ tí nwọn kò wõ, nítorínã, nwọ́n parun. Báyĩ, ìdí rẹ̀ tí wọn kò fi ní wò ó ni wípé nwọn kò gbàgbọ́ pé yíò wò nwọ́n sàn.

21 A! ẹ̀yin ará mi, bí ẹ̀yin bá lè rí ìwòsàn nípa fífi ojú nyín wò ṣá kí ẹ̀yin lè rí ìwòsàn, njẹ́ ẹ̀yin kò ní wõ ní kíákíá, tàbí ó tẹ́ẹ nyín lọ́rùn láti sé ọkàn nyín le nínú àìgbàgbọ́, kí ẹ sì ya ọ̀lẹ, kí ẹ sì má lè fi ojú nyín wõ, tí ẹ̀yin ó sì parun?

22 Bí ó bá rí bẹ̃, ègbé yíò wá sí orí nyín; ṣùgbọ́n bí kò bá rí bẹ̃, ẹ fi ojú nyín wõ nígbànã, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé ó nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú fún ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyítí yíò mú àjĩnde-òkú nã ṣẹ, tí gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú rẹ̀, fún ìdájọ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ nwọn, ní ọjọ́ ìkẹhìn nnì tí í ṣe ọjọ́ ìdájọ́.

23 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ gbin ọ̀rọ̀ yĩ sínú ọkàn nyín, bí ó sì ṣe bẹ̀rẹ̀sí wú sókè, bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin bọ́ọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nyín. Ẹ sì kíyèsĩ, yíò di igi, tí yíò sì máa sun sí ìyè àìlópin nínú nyín. Kí Ọlọ́run kí ó sì jẹ́ kí ìnira nyín di fífúyẹ́, nípasẹ̀ ayọ̀ nínú Ọmọ rẹ̀. Gbogbo nkan wọ̀nyí ni ẹ̀yin lè ṣe, bí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ àti ṣeé. Àmín.