Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 37


Orí 37

Àwọn àwo idẹ pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́ míràn ni a tọ́jú pamọ́ lati mú ọkàn wá sí ìgbàlà—Àwọn ará Járẹ́dì ni a parun nítorí ìwà búburú nwọn—Àwọn ìmùlẹ̀ ìkọ̀kọ̀ àti májẹ̀mú nwọn níláti wà ní pípamọ́ kúrò lãrín àwọn ènìyàn nã—Gba ìmọ̀ràn Olúwa nínú ohun gbogbo tí ìwọ bá nṣe—Gẹ́gẹ́bí Liahónà ṣe tọ́ àwọn ará Nífáì sọ́nà, bẹ̃ nã ni ọ̀rọ̀ Krístì ṣe ndarí ènìyàn sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ọmọ mi Hẹ́lámánì, mo pã láṣẹ fún ọ pé kí o gbé àwọn àkọsílẹ̀ nã èyítí a ti fi lé mi lọ́wọ́;

2 Èmi sì tún pã láṣẹ fún ọ pé kí ìwọ kí ó ṣe àkọsílẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yĩ, gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, lé orí àwọn àwo ti Nífáì, kí o sì pa àwọn ohun wọ̀nyí mọ́ ní mímọ́, èyítí èmi ti pa mọ́, àní ní ìbámu pẹ̀lú bí èmi ti ṣe ṣe ìpamọ́ nwọn; nítorí pé fún ìdí ọgbọ́n ni a ṣe nṣe ìpamọ́ nwọn.

3 Àwọn àwo idẹ wọ̀nyí èyítí ó ní àwọn ìfín wọ̀nyí, èyítí ó ní àwọn àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìwé-mímọ́ lórí nwọn, èyítí ó ní ìtàn ìdílé àwọn bàbá nlá wa, àní láti ìbẹ̀rẹ̀—

4 Kíyèsĩ, àwọn bàbá wa ti sọọ́ tẹ́lẹ̀ pé kí a pa nwọ́n mọ́, kí a sì fi nwọ́n lè ọwọ́ àwọn ọmọ wa láti ìran kan dé òmíràn, pé kí a pa nwọ́n mọ́, kí a sì ṣe ìtọ́jú nwọn nípasẹ̀ ọwọ́ Olúwa títí nwọn ó fi tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, pé kí nwọ́n lè mọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ tí ó wà lórí nwọn.

5 Àti nísisìyí kíyèsĩ, bí a bá pa nwọn mọ, nwọ́n níláti wà ní dídán; bẹ̃ni, nwọn ó sì wà ní dídán; àní, bẹ̃ sì ní gbogbo àwọn àwo nã ti a kọ àwọn ohun mímọ́ sí.

6 Nísisìyí ìwọ lè rò wípé ohun aláìgbọ́n ní èyí jẹ́ fún mi láti ṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi wí fún ọ, pé nípa àwọn ohun kékèké tí ó sì rọrùn ní àwọn ohun nlá tí njáde wa; àti pé àwọn ohun kékèké ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà a máa dàmú ọlọgbọ́n.

7 Olúwa Ọlọ́run a sì máa ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà èyítí yíò mú ìpinnu nlá rẹ̀ tĩ ṣe ti ayérayé ṣẹ; àti pé nípa ohun tí ó kéré púpọ̀ Olúwa a máa dàmú ọlọgbọ́n tí yìó sì mú ìgbàlà bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkan.

8 Àti nísisìyí, ní tẹ́lẹ̀rí ó jẹ́ ohun ọgbọ́n nínú Ọlọ́run pé kí a fi àwọn ohun wọ̀nyí sí ìpamọ́; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣí àwọn ènìyàn yĩ ní iyè, bẹ̃ni, nwọ́n sì ti jẹ́ kí púpọ̀ mọ́ ìkùnà ọ̀nà nwọn, nwọ́n sì ti mú nwọn wá sí ìmọ̀ Ọlọ́run nwọn sí ìgbàlà ọkàn nwọn.

9 Bẹ̃ni, èmi wí fún ọ, bíkòbáṣe ti àwọn ohun wọ̀nyí ti àwọn àkọsílẹ̀ yĩ ní nínú, èyítí ó wà lórí àwọn àwo wọ̀nyí, Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kì bá tí lè yí ẹgbẽgbẹ̀rún púpọ̀ àwọn ará Lámánì padà nínú àìtọ̀nà àṣà àwọn bàbá nwọn; bẹ̃ni, àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí àti ọ̀rọ̀ nwọn mú nwọn wà sí ìrònúpìwàdà; èyí já sí pé, nwọ́n mú nwọn bọ́ sínú ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti láti yọ̀ nínú Jésù Krístì Olùràpadà nwọn.

10 Tani ẹnití ó mọ̀ bóyá àwọn ni yíò mú ọ̀pọ̀ ẹgbẽgbẹ̀rún nwọn, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹgbẽgbẹ̀rún àwọn arákùnrin wa ọlọ́rùnlíle, àwọn ará Nífáì, tí nwọn nṣe ọkàn nwọn le nísisìyí nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé, bọ́ sínú ìmọ̀ Olùràpadà nwọn?

11 Nísisìyí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ yĩ kò tĩ di mímọ̀ fún mi pátápátá; nítorínã èmi yíò dánu dúró.

12 Ó sì tó bí èmi bá sọ wípé a tọ́jú nwọn pamọ́ fún ìdí ọgbọ́n, ìdí èyítí ó jẹ́ mímọ̀ fún Ọlọ́run; nítorítí ó nṣàkóso pẹ̀lú ọgbọ́n lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ọ̀nà rẹ̀ gbogbo ni ó sì tọ́, tí ipa rẹ̀ jẹ́ ọ̀na àìyípadà ayérayé kan.

13 A! rántí, rántí ò, ọmọ mi Hẹ́lámánì, bí àwọn òfin Ọlọ́run ṣe múná tó. Òun sì wípé: Bí ìwọ bá pa òfin mi mọ́, ìwọ yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã—ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá pa òfin rẹ̀ mọ́, a ó ké ọ kúrò níwájú rẹ̀.

14 Àti nísisìyí kí o sì rántí, ọmọ mi, pé Ọlọ́run ti fi ohun wọ̀nyí tĩ ṣe mímọ́ lé ọ lọ́wọ́, èyítí o ti pamọ́ ní mímọ́, àti pẹ̀lú ti yíò pamọ́ ní ìtọ́jú fún ìdí ọgbọ́n nínú rẹ̀, kí ó lè fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn ìran tí nbọ̀wá.

15 Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún ọ nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, pé bí ìwọ bá rékọjá sí òfin Ọlọ́run, kíyèsĩ, a ó gba àwọn ohun wọ̀nyí tí nwọ́n jẹ́ mímọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ nípa agbára Ọlọ́run, a ó sì fi ọ́ lé Sátánì lọ́wọ́, tí òun yíò sì kù ọ́ bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

16 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, tí ìwọ ṣe gẹ́gẹ́bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún ọ lórí àwọn ohun wọ̀nyí tí nwọn í ṣe mímọ́, (nítorítí o níláti bẹ Olúwa fún ohun gbogbo èyíkéyĩ tí ìwọ yíò ṣe pẹ̀lú nwọn) kíyèsĩ, kò sí agbára ayé tàbí ti ọ̀run àpãdì tí ó lè gbà nwọn lọ́wọ́ rẹ, nítorítí Ọlọ́run lágbára tóbẹ̃ tí yíò fi mú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

17 Nítorítí òun yíò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ èyítí oun yio ṣe pẹ̀lú rẹ, nítorítí òun ti mú àwọn ìlérí tí ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn bàbá wa ṣẹ.

18 Nítorítí ó ṣe ìlérí fún nwọn pé òun yíò tọ́jú àwọn ohun wọ̀nyí pamọ́ fún ìdí ọgbọ́n nínú rẹ̀, kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn ìran tí nbọ̀wá.

19 Àti nísisìyí kíyèsĩ, ìdí kan ni ó ti mú ṣẹ, àní sí ìdápadà bọ̀sípò ọ̀pọ̀ ẹgbẽgbẹ̀rún àwọn ará Lámánì sí ìmọ̀ òtítọ́; òun sì ti fi agbára rẹ̀ hàn, òun yíò sì tún fi agbára rẹ̀ hàn nípasẹ̀ àwọn ohun wọ̀nyí sí àwọn ìran tí nbọ̀wá; nítorínã a ó pa àwọn ohun wọ̀nyí mọ́.

20 Nítorínã mo pàṣẹ fún ọ, ọmọ mi Hẹ́lámánì, pé kí o tẹramọ́ imúṣẹ ọ̀rọ̀ mi, àti pé kí ìwọ kí ó tẹramọ́ pípa òfin Ọlọ́run mọ́ gẹ́gẹ́bí a ti kọ nwọ́n.

21 Àti nísisìyí, èmi yíò sì bá ọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn àwo mẹ́rìnlélógún nnì, pé kí o pa nwọ́n mọ́, kí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nnì àti àwọn iṣẹ́ òkùnkùn, àti àwọn iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ nwọn, tàbí iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn nnì tí a ti parun, kí ó di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, gbogbo ìpànìyàn nwọn, àti olè jíjà, àti ìkógun nwọn, àti ìwà búburú nwọn àti ìwà ẽrí nwọn, lè di mímọ̀ sí àwọn ènìyàn yìi; bẹ̃ni, àti pé kí o tọ́jú àwọn atúmọ̀ yĩ pamọ́.

22 Nìtorí kíyèsĩ, Olúwa ríi pé àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ ní òkùnkùn, bẹ̃ni, nwọ́n nṣe ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ àti ìwà ẽrí; nítorínã Olúwa wípé, bí nwọn kò bá ronúpìwàdà a ó pa nwọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

23 Olúwa sì wípé: Èmi yíò pèsè fún ìránṣẹ́ mi Gásélémù, òkúta kan, èyítí yíò tanná jáde nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, kí èmi lè fi han àwọn ènìyàn mi tí nwọn nsìn mí, kí èmi lè fi iṣẹ́ ọwọ́ àwọn arákùnrin nwọn hàn nwọ́n, bẹ̃ni, iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ nwọn, àti iṣẹ́ òkùnkùn wọn, àti ìwà búburú àti ohun ìríra nwọn.

24 Àti nísisìyí, ọmọ mi, àwọn atúmọ̀ wọ̀nyí ni a pèsè kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ṣẹ, èyítí ó ti sọ, tí ó wípé:

25 Èmi yíò mú jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ nwọn àti ìwà ẽrí nwọn; àti pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà èmi yíò pa nwọ́n run kúrò lórí ilè ayé; èmi yíò sì fi gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ àti ẽrí nwọn hàn sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní lẹ́hìn èyí.

26 Àti nísisìyí, ọmọ mi, àwa ríi pé nwọn kò ronúpìwàdà; nítorínã a ti pa nwọ́n run, àti pé títí di àkokò yĩ, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti ṣẹ; bẹ̃ni, ohun ẽrí nwọn ìkọ̀kọ̀ ni a ti mú jáde kúrò nínú òkùnkùn tí a sì ti sọ di mímọ̀ fún wa.

27 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo pàa láṣẹ fún ọ́ pé kí ìwọ kí ó fi sí àkóso rẹ gbogbo ìbúra nwọn, àti àwọn májẹ̀mú nwọn, àti àwọn àdéhùn nwọn tí nwọ́n ṣe nínú ìwà ẽrí ìkọ̀kọ̀ nwọn; bẹ̃ni, àti gbogbo ohun àmì àti ìyanu nwọn ni ìwọ yíò pamọ́ kúrò ní mímọ̀ sí àwọn ènìyàn yĩ, kí nwọn má lè mọ̀ nwọ́n, pé bóyá nwọ́n lè ṣubú sínú ìwà búburú, tí nwọn ó sì parun.

28 Nítorí kíyèsĩ, ègún wà lórí gbogbo ilẹ̀ yĩ, pé ìparun yíò wá sí órí gbogbo àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn, ní ìbámu pẹ̀lú agbára Ọlọ́run, nígbàtí nwọ́n bá ti gbó nínú ìwà búburú nwọn; nítorínã ó jẹ́ ìfẹ́-inú mi kí àwọn ènìyàn yìi máṣe parun.

29 Nítorínã ìwọ yíò pa àwọn ìlànà ìkọ̀kọ̀ ti ìbúra àti májẹ̀mú nwọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yĩ, àwọn ìwà búburú nwọn àti àwọn ìwà ìpànìyàn nwọn àti àwọn ìwà ẽrí nwọn nìkan ni ìwọ yíò jẹ́ kí nwọ́n mọ̀; ìwọ yíò sì kọ́ nwọn láti ní ìkórira fún irú ìwà búburú bẹ̃ àti ìwà ẽrí àti ìwà ìpànìyàn; ìwọ yíò sì kọ́ nwọn pẹ̀lú pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a parun nípasẹ̀ ìwà búburú nwọn àti ìwà ẽrí àti ìwà ìpànìyàn nwọn.

30 Sì kíyèsĩ nwọn pa gbogbo àwọn wòlĩ Olúwa tí nwọ́n wá sí ãrin nwọn láti kéde sí nwọn ní ti ìwà àìṣedẽdé nwọn; ẹ̀jẹ̀ àwọn tí nwọ́n pa sì nké sí Olúwa Ọlọ́run nwọn fún ẹ̀san lórí àwọn tí ó pa nwọ́n; bẹ̃ sì ni ìdájọ́ Ọlọ́run wá sí órí àwọn oníṣẹ́ ìkọ̀kọ̀ àti ẹgbẹ́ òkùnkùn.

31 Bẹ̃ni, ẹ̀gún sì wà lórí ilẹ̀ nã títí láéláé àti láéláé fún àwọn oníṣẹ́ ìkọkọ àti ẹgbẹ́ okunkun, àní sí ìparun, àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà kí nwọ́n tó gbó sínú ìwà búburú.

32 Àti nísisìyí, ọmọ mi, rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ; máṣe fi àwọn ìlànà ìkọ̀kọ̀ nnì hàn sí àwọn ènìyàn yĩ, ṣùgbọ́n kọ́ nwọn ní ìkórira ayérayé fún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé.

33 Wãsù ìrònúpìwàdà sí wọn, àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa; kọ́ nwọn láti rẹ ara nwọn sílẹ̀, àti láti jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ènìyàn; kọ́ nwọn láti tako gbogbo àdánwò èṣù, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Jésù Krístì Olúwa.

34 Kọ́ nwọn láti má ṣãrẹ̀ iṣẹ́ rere ní ṣíṣe, ṣùgbọ́n kí nwọ́n jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ènìyàn; nítorípé irú ẹni báyĩ ni yíò rí ìsinmi fún ọkàn nwọn.

35 A!, rántí, ọmọ mi, kí o sì kọ́ ọgbọ́n ní ìgbà èwe rẹ; bẹ̃ni, kọ́ ní ìgbà èwe rẹ̀ láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.

36 Bẹ̃ni, kí o sì ké pe Ọlọ́run fún gbogbo ìrànlọ́wọ́ rẹ; bẹ̃ni, jẹ́ kí gbogbo ìṣe rẹ jẹ́ ti Olúwa, ibikíbi ti ìwọ bá sì lọ, jẹ́ kí ó jẹ́ nínú Olúwa; bẹ̃ni, jẹ́ kí gbogbo èrò ọkàn rẹ kọjúsí Olúwa; bẹ̃ni, jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ dúró lé Olúwa títí láé.

37 Da ìmọ̀ràn pẹ̀lú Olúwa nínú ohun gbogbo tí ìwọ bá nṣe, òun yíò sì tọ́ ọ sọ́nà fún rere; bẹ̃ni, nígbàtí ìwọ bá dùbúlẹ̀ ní alẹ́, dùbúlẹ̀ sí ipa ti Olúwa, kí òun kí ó lè fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ ọ nínú õrun rẹ; nígbàtí ìwọ bá sì dìde ní òwúrọ̀, jẹ́ kí ọ̀kan rẹ̀ kún fún ọpẹ̀ sí Ọlọ́run; bí ìwọ bá sì ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, a ó gbé ọ sókè ní ọjọ́ ìkẹ́hìn.

38 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo ní ohun kan láti sọ nípa ohun tí àwọn bàbá wa pè ní bọ̃lù, tàbí afọ̀nàhàn—tàbí tí àwọn bàbá wa pẽ ní Liahónà, èyítí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ olùtọ́sọ́nà; Olúwa ni ó sì pèsè rẹ̀.

39 Sí kíyèsĩ, kò sì sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè ṣe irú iṣẹ́ ọnà aláràbarà dáradára báyĩ. Sì kíyèsĩ, a pèsè rẹ̀ láti fi hàn àwọn bàbá wa ipa ọ̀nà tí nwọn yíò rìn nínú aginjù.

40 Ó sì ṣiṣẹ́ fún nwọn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn nínú Ọlọ́run; nítorínã, bí nwọ́n bá ní ìgbàgbọ́ láti gbàgbọ́ pé Ọlọ́run lè mú kí àwọn kẹ̀kẹ́ nã kọjú sí ọ̀nà tí ó yẹ kí nwọ́n gba, kíyèsĩ, bẹ̃ ni ó rí; nítorínã, nwọn ní iṣẹ́ ìyanu yĩ, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu míràn pẹ̀lú èyítí agbára Ọlọ́run múwá, lójojúmọ́.

41 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorípé àwọn iṣẹ́ ìyanu nã wá nípasẹ̀ àwọn ohun kékèké, ó fi ohun ìyanu hàn nwọ́n. Nwọ́n yọ̀lẹ, nwọ́n sì gbàgbé láti lo ìgbàgbọ́ àti ìtẹramọ́ nwọn, nígbànã sì ni àwọn iṣẹ́ ìyanu nã dáwọ́dúró, nwọn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò nwọn;

42 Nítorínã, nwọ́n ní ìdádúró nínú aginjù nã, tàbí pé nwọn kò rìn ní ọ̀nà tãrà, nwọ́n sì rí ìpọ́njú ebi àti òhùngbẹ, nítorí ìwàìrékọjá nwọn.

43 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èmi fẹ́ kí ìwọ mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí kò ṣaláì ní òjìji; nítorípé nígbàtí àwọn bàbá wa ya ọ̀lẹ láti kíyèsí atọ́nisọ́nà yĩ (ní báyĩ àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ ti ara) nwọn kò ṣe rere; bẹ̃ gẹ́gẹ́ sì ni àwọn ohun tí íṣe ti ẹ̀mí.

44 Nítorí kíyèsĩ, ó rọrùn láti fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Krístì, èyítí yíò tọ́ka ọ̀nà tí ó gún sí àlãfíà pípé ayérayé sí ọ, bí o ṣe rí fún àwọn bàbá wa láti fetísílẹ̀ sí atọ́nisọ́nà yìi, èyítí yíò tọ́ka ọ̀nà tí ó gún sí ilẹ̀ ìlérí nã sí nwọn.

45 Àti nísisìyí, èmi wí pé, njẹ́ kò ha sí irú rẹ̀ nínú ohun yĩ? Nítorípé gẹ́gẹ́bí afinimọ̀nà yĩ ní tõtọ́ ṣe mú àwọn bàbá wa, nípa títẹ̀lé ipa ọ̀nà rẹ̀, lọ sí ilẹ̀ ìlérí nã, bẹ̃ni awọn ọ̀rọ̀ Krístì, bí àwa bá tẹ̀lé ipa ọ̀nà wọn, yíò gbé wa kọjá àfonífojì ìbànújẹ́ yì, sínú ilẹ̀ ìlérí tí ó dára ju èyí nnì lọ.

46 A! ọmọ mi, ma jẹ́ kí a ya ọ̀lẹ nítorí ìrọ̀rùn ọ̀nà nã; nítorípé bẹ̃ni ó rí fún àwọn bàbá wa; nítorípé bẹ̃ ni a ti ṣe pèsè rẹ̀ fún nwọn, pé tí nwọ́n bá lè wõ nwọn lè yè; bẹ̃ nã ni ó rí pẹ̀lú wa. A ti pèsè ọ̀nà nã sílẹ̀, bí àwa bá sì lè wò ó àwa yíò yè títí láéláé.

47 Àti nísisìyí, ọmọ mi, rí i pé o tọ́jú àwọn ohun mímọ́ yĩ, bẹ̃ni, ríi pé ìwọ yí ojú rẹ sí Ọlọ́run kí o sì yè. Lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ènìyàn yĩ kí o sì kéde ọ̀rọ̀ nã, kí o sì mã ronu jinlẹ. Ọmọ mi, ó dìgbóṣe.