Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 57


Orí 57

Hẹ́lámánì sọ nípa bí nwọ́n ṣe mú Ántípárà àti nípa bí Kúménì ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ àti ìdáabò bò rẹ̀ nígbàtí ó ṣe—Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ tí í ṣe ará Ámmọ́nì jà takuntakun; gbogbo nwọn ni ó fi ara gba ọgbẹ́, ṣùgbọ́n kò sí èyítí a pa—Gídì sọ nípa pípa tí nwọ́n pa àwọn ará Lámánì tí a kó lẹ́rú àti ìsálọ nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 63 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí èmi gba ìwé kan láti ọwọ́ Ámmórọ́nì, ọba, tí ó wípé bí èmi yíò bá jọ̀wọ́ àwọn ẹnití a ti kó lẹ́rú nnì tí àwa ti mú, òun yíò jọ̀wọ́ ìlú-nlá Ántípárà fún wa.

2 Ṣùgbọ́n èmi kọ ìwé sí ọba nã, wípé ó dá wa lójú wípé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tó láti mú ìlú-nlá Ántípárà nípa agbára wa; àti pé bí àwa bá jọ̀wọ́ àwọn tí a ti kó lẹ́rú ní ìpãrọ̀ fún ìlú-nlá nã àwa yíò rí bí aláìgbọ́n ènìyàn, àti pé àwa yíò jọ̀wọ́ àwọn tí a kó lẹ́rú ní ìpãrọ̀.

3 Ámmórọ́nì sì kọ àbá mi, nítorítí ó kọ̀ láti ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú; nítorínã ni àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìmúrasílẹ̀ láti lọ kọlu ìlú-nlá Ántípárà.

4 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Ántípárà fi ìlú-nlá nã sílẹ̀, nwọ́n sì sálọ sí àwọn ìlú-nlá nwọn míràn, tí nwọ́n ní ní ìní, láti dãbò bò nwọ́n; báyĩ sì ni ìlú-nlá Ántípárà bọ́ sí ọwọ́ wa.

5 Báyĩ si ni ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

6 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n, ni àwa gba ìpèsè àwọn oúnjẹ àti àfikún fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa, láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti làti àwọn ilẹ̀ ti o yiká, ní iye ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àwọn ọmọ ogun, yàtọ̀ sí ọgọ́ta àwọn ọmọ àwọn ará Ámọ́nì tí nwọ́n ti wá darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi ẹgbẹ̀rún méjì. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa lágbára, bẹ̃ni àwa sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèsè oúnjẹ tí nwọ́n ti kó wá fún wa.

7 Ó sì ṣe tí àwa ní ìfẹ́ láti bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí nwọ́n fi ṣọ́ ìlú-nlá Kúménì jagun.

8 Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi yíò fi hàn ọ́ pé àwa yíò mú ìfẹ́ inú wa di ṣíṣe láìpẹ́; bẹ̃ni, pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí ó lágbára, tàbí pẹ̀lú apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí ó lágbára, ni àwa ká ìlú-nlá Kúménì mọ́ ní òru, ní kété kí nwọ́n tó gba ìpèsè oúnjẹ nwọn.

9 Ó sì ṣe, tí àwa pàgọ́ yí ìlú-nlá nã ká fún òru ọjọ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n àwa sùn pẹ̀lú idà wa, a sì nṣọ́nà, kí àwọn ará Lámánì ó máṣe lè wá kọlũ wá lóru kí nwọ́n sì pa wá, èyítí nwọn gbìyànjú rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà; ṣùgbọ́n a ta ẹ̀jẹ̀ nwọn sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí nwọ́n gbìyànjú.

10 Nígbàtí ó yá ìpèsè oúnjẹ wọn dé, nwọ́n sì ṣetán láti wọ inú ìlú-nlá nã ní alẹ́. T’í àwa, èyítí àwa ìbá fi jẹ́ ará Lámánì, àwa sì jẹ́ ará Nífáì; nítorínã, àwa sì mú nwọn àti àwọn ìpèsè oúnjẹ wọn.

11 Àti l’áìṣírò a ti ké àwọn ará Lámánì kúrò lára ìrànlọ́wọ́ nwọ́n ní ọ̀nà yĩ, nwọ́n sì pinnu láti di ìlú-nlá nã mú; nítorínã ó di dandan fún wa láti kó àwọn ìpèsè nnì kí a sì fi nwọ́n ránṣẹ́ sí Jùdéà, àti láti fi àwọn ẹrú wa ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

12 Ó sì ṣe pé láìpẹ́ ọjọ́ ni àwọn ará Lámánì bẹ̀rẹ̀sí sọ ìrètí nù lórí gbígba ìrànlọ́wọ́; nítorínã nwọn jọ̀wọ́ ìlú-nlá nã lé wa lọ́wọ́; báyĩ sì ni àwa ṣe àṣeyọrí lórí ète láti gba ìlú-nlá Kúménì.

13 Ṣùgbọ́n ó ṣe tí àwọn ẹrú wa di púpọ̀ gan-an, l’áìṣírò àwa kò pọ̀ tóbẹ̃, ó di dandan fún wa láti lo gbogbo àwọn ọmọ ogun wa láti ṣọ́ nwọn, tàbí láti pa nwọ́n.

14 Nítorí kíyèsĩ, nwọn a máa já ara nwọn gbà lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọn a sì máa jà pẹ̀lú òkúta wẹ́wẹ́, àti pẹ̀lú kùmọ̀, tàbí ohunkóhun tí ọwọ́ nwọn bá bà, tóbẹ̃ tí àwa fi pa oye tí ó ju ẹgbẹ̀rún méjì nínú nwọn lẹ́hìn tí nwọ́n ti jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ fún ìkólẹ́rú.

15 Nítorínã ni ó ṣe di dandan fún wa láti fi òpin sí ìgbe ayé nwọn, tàbí kí a máa ṣọ́ nwọn, pẹ̀lú idà lọ́wọ́, títí dé ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; àti pẹ̀lú pé àwọn ìpèsè oúnjẹ wa kò tó mọ́ fún àwọn ènìyàn ara wa, l’áìṣírò àwa ti gbà lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

16 Àti nísisìyí, nínú àkokò tí ó léwu yĩ, ó di ohun tí ó ṣe pàtàkì fún wa láti ṣe fún àwọn tí a kó lẹ́rú yĩ; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a pinnu láti rán nwọn lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nítorínã ni a ṣe yan díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa, tí a sì fún wọn ní àṣẹ lórí àwọn ẹrú wa wọ̀nyí láti lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

17 Ṣùgbọ́n ó sì se ní ọjọ́ kejì nwọ́n sì padà. Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa kò bí nwọ́n lẽrè nípa àwọn ẹrú nã; nítorítí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì nã ti nkọlù wá, nwọ́n sì padà kánkán láti yọ wá kúrò nínú ìṣubú sí ọwọ́ nwọn. Nítorí kíyèsĩ, Ámmórọ́nì ti fi ìpèsè oúnjẹ titun ránṣẹ́ sí nwọn fún ìrànlọ́wọ́ àti ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun.

18 Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ ogun nnì tí a rán pẹ̀lú àwọn ẹrú sì padà wá kánkán láti dè nwọ́n lọ́nà, ní bí nwọ́n ṣe fẹ́ borí wa.

19 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́ta nnì jà takuntakun; bẹ̃ni, nwọ́n dúró gbọingbọin níwájú àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì fi ikú pa gbogbo àwọn tí ó takò nwọ́n.

20 Àti bí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa tí ó kù ṣe fẹ́rẹ̀ sá padà níwájú àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́ta nnì dúró gbọingbọin láìfàsẹ́hìn.

21 Bẹ̃ni, nwọ́n sì ṣe ìgbọràn, nwọ́n tiraka láti pa gbogbo àṣẹ mọ́ pátápátá; bẹ̃ni, àti pãpã ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nwọn ni a ṣe ṣeé fún nwọn; èmi sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí nwọ́n sọ fún mi pé àwọn ìyá nwọn ni ó kọ́ nwọn.

22 Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ọmọ mi wọ̀nyí, àti àwọn ọmọ ogun nnì tí a ti yàn láti darí àwọn ẹrú nnì, ni àwa jẹ ní gbèsè fún ìṣẹ́gun nlá yĩ; nítorítí àwọn ni ó na àwọn ará Lámánì nã; nítorínã ni a ṣe lé nwọn padà sínú ìlú-nlá Mántì.

23 Àwa sì di ìlú-nlá wa Kúménì mú, nwọn kò sì lè pa gbogbo wa run pẹ̀lú idà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwa ti pàdánù lọ́pọ̀lọpọ̀.

24 Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí àwọn ará Lámánì ti sá, ní kía ni mo pàṣẹ pé kí nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun mi tí nwọ́n ti fi ara gba ọgbẹ́ kúrò lãrín àwọn tí ó ti kú, tí mo sì mú kí nwọ́n di ọgbẹ́ nwọn.

25 Ó sì ṣe tí igba nínú àwọn ọmọ mi ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́ta nnì, dákú nítorípé nwọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ ṣòfò; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nípa dídára Ọlọ́run, àti sí ìyàlẹ́nu nlá fún wa, àti ayọ̀ gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa pẹ̀lú, kò sí ẹyọ ẹ̀mí kan nínú nwọn tí ó ṣègbé; bẹ̃ni, àti pé kò sì sí ẹyọ ẹ̀mí kan lãrín nwọn tí kò fi ara gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgbẹ́.

26 Àti nísisìyí, ìpamọ́ nwọn jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa, bẹ̃ni, pé kí a dá wọn sí nígbàtí àwọn ẹgbẹ̀rún nínú àwọn arákùnrin wa ti kú. Àti pé láìṣiyèméjì ni àwa kã kún agbára ìyanu Ọlọ́run, nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó tayọ nínú èyítí àwọn ìyá nwọn ti kọ́ nwọn láti gbàgbọ́—pé Ọlọ́run tí ó tọ́ kan nbẹ, àti pé ẹnìkẹ́ni tí kò bá ṣiyèméjì, pé nwọn yíò wà ní ìpamọ́ nípa agbára ìyanu rẹ̀.

27 Nísisìyí èyí ni ìgbàgbọ́ àwọn wọ̀nyí tí èmi ti sọ nípa nwọn; nwọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, ọkàn nwọn sì dúró ṣinṣin, nwọ́n sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé nwọn sí ínú Ọlọ́run títí lọ.

28 Àti nísisìyí ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí àwa ti tọ́jú àwọn ọmọ ogun wa tí nwọ́n fi ara gba ọgbẹ́ tán báyĩ, tí a sì ti sin àwọn ará wa tí ó kú àti àwọn ará Lámánì tí ó kú pẹ̀lú, tí nwọ́n sì pọ̀, kíyèsĩ, àwa bẽrè lọ́wọ́ Gídì nípa àwọn ẹrú tí nwọ́n ti bẹ̀rẹ̀sí bá lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

29 Nísisìyí Gídì jẹ́ olórí ológun fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí a yàn láti ṣọ́ nwọn lọ sínú ilẹ̀ nã.

30 Àti nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí Gídì sọ fún mi: Kíyèsĩ, àwa bẹ̀rẹ̀sí lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà pẹ̀lú àwọn ẹrú wa. Ó sì ṣe tí àwa bá àwọn amí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa pàdé, tí nwọ́n ti rán lọ láti ṣọ́ àgọ́ àwọn ará Lámánì.

31 Nwọ́n sì kígbe pè wá wípé—Kíyèsĩ, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì nkọjá lọ sínú ìlú-nlá Kúménì; sì kíyèsĩ, nwọn yíò kọlũ nwọ́n, bẹ̃ni, nwọn yíò sì pa àwọn ènìyàn wa run.

32 Ó sì ṣe tí àwọn ẹrú wa gbọ́ igbe nwọn, tí ó sì fún nwọn ní ìgboyà; nwọn sì dìde sì wa ní àtakò.

33 Ó sì ṣe nítorí àtakò yĩ tí àwa sì mú kí idà wa ó gbé lù nwọ́n. Ó sì ṣe tí nwọ́n sì rọ́ lu idà wa, nínú èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn kú; tí àwọn tí ó kù sì sá jáde tí nwọ́n sálọ mọ́ wa lọ́wọ́.

34 Sì kíyèsĩ, nígbàtí nwọ́n ti sálọ tí àwa kò sì lè lé nwọn bá, àwa mú ìrìnàjò wa ní kánkán lọ sí ìlú-nlá Kúménì; sì kíyèsĩ, àwa sì dé ibẹ̀ lásìkò láti lè ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ láti pa ìlú-nlá nã mọ́.

35 Sì kíyèsĩ, a sì tún yọ wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa. Ìbùkún sì ni fún orúkọ Ọlọ́run wa; nítorítí kíyèsĩ, òun ni ẹnití ó kó wa yọ; bẹ̃ni, tí ó ti ṣe ohun nlá yĩ fún wa.

36 Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí èmi, Hẹ́lámánì, ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Gídì wọ̀nyí, ayọ̀ kún inú mi lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí dídára Ọlọ́run ní pípa wá mọ́, kí gbogbo wa ó máṣe ṣègbé; bẹ̃ni, èmi sì ní ìdánilójú wípé ẹ̀mí àwọn tí nwọ́n pa ti wọ inú ìsinmi Ọlọ́run nwọn lọ.