Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 8


Orí 8

Álmà nwãsu ó sì nṣe ìrìbọmi ní Mẹ́lẹ́kì—Nwọn kò gbọ́ tirẹ̀ ní Amonáíhà ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀—Ángẹ́lì-Ọlọ́run kan pàṣẹ fún un kí ó padà síbẹ̀ kí ó sì kéde ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã—Ámúlẹ́kì gbã, àwọn méjẽjì sì nwãsù ní Amonáíhà. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí Álmà padà bọ̀ láti ilẹ̀ Gídéónì, lẹ́hìn tí ó ti kọ́ àwọn ará Gídéónì ní ohun púpọ̀ tí a kò lè kọ sílẹ̀, tí ó sì ti da ipa-ọ̀nà ti ìjọ nã sílẹ̀, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe síwájú ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, bẹ̃ni, ó padà sí ilé rẹ̀ ní Sarahẹ́múlà láti fún ara rẹ̀ ní ìsinmi lẹ́hìn lãlã tí ó ti ṣe.

2 Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀sán parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

3 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹẹ̀wá ní ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Álmà jáde lọ kúrò níbẹ̀, tí ó sì mú ìrìnàjò pọ̀n lọ sí ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn odò Sídónì, ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní etí aginjù.

4 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sĩ kọ́ àwọn ènìyàn nã ní ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì gẹ́gẹ́bí ẹgbẹ́ mímọ́ nã ti Ọlọ́run, èyítí a fi pẽ; ó sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ènìyàn nã jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì.

5 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã tọ̃ wá jákè-jádò ìhà etí ilẹ̀ nã èyítí ó wà ní ìhà aginjù. A sì rì nwọn bọmi jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã;

6 Nígbàtí ó sì ti parí iṣẹ́ rẹ̀ ní Mẹ́lẹ́kì, ó jáde kúrò níbẹ̀, ó sì rin ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́ta lọ sí apá àríwá ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì; ó sì dé ìlú-nlá kan tí à npè ní Amonáíhà.

7 Nísisìyí, ó jẹ́ àṣà àwọn ará Nífáì láti pe ilẹ̀ wọn, àti ìlú-nlá wọn, àti ìletò wọn, bẹ̃ni, àní gbogbo ìletò kékèké wọn, ní orúkọ ẹnití ó kọ́kọ́ tẹ̀ nwọ́n dó; báyĩ sì ni ó rí ní ti ilẹ̀ Amonáíhà.

8 Ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti dé ìlú-nlá Amonáíhà ó bẹ̀rẹ̀ sĩ wãsu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

9 Nísisìyí, Sátánì ti gba ọkàn àwọn ará ìlú-nlá Amonáíhà; nítorínã, wọn kò tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ Álmà.

10 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Álmà ṣe lãlã nínú ẹ̀mí, tí ó sì nbá Ọlọ́run ja ìjàkadì nínú ọ̀pọ̀ àdúrà, pé kí ó lè da Ẹ̀mí rẹ̀ lé orí àwọn ènìyàn nã tí wọ́n wà ní ìlú-nlá nã; kí òun kí ó lè ṣe ìrìbọmi fún nwọn sí ti ìrònúpìwàdà.

11 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n sé ọkàn nwọn le, nwọ́n sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, àwa mọ̀ wípé Álmà ni ìwọ íṣe; àwa sì mọ̀ pé ìwọ ni olórí àlùfã lórí ìjọ èyítí ìwọ ti dá sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ilẹ̀ yíi, gẹ́gẹ́bí àṣà rẹ; àwa kĩ ṣe ti ìjọ rẹ, àwa kò sì gba iru àwọn àṣà aṣiwèrè wọnnì gbọ́.

12 Àti nísisìyí, àwa mọ̀ wípé nítorípé àwa kĩ ṣe ti ìjọ rẹ, àwa mọ̀ wípé ìwọ kò ní agbára lórí wa; ìwọ sì ti gbé ìtẹ́ ìdájọ́ lé Néfáíhà lọ́wọ́; nítorínã ìwọ kĩ ṣe adájọ́-àgbà lórí wa.

13 Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì ti wí báyĩ tán, tí wọ́n sì ta ko gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí nwọ́n sì pẹ̀gàn rẹ̀, tí wọ́n tutọ́ síi lára, tí wọ́n sì lée jáde kúrò nínú ìlú wọn, ó kúrò níbẹ̀, ó sì mú ìrìn-àjò rẹ̀ lọ sí ìhà ìlú-nlá èyítí à npè ní Áárọ́nì.

14 Ó sì ṣe, nígbàtí ó nrin ìrìn-àjò lọ síbẹ̀, bí ó ti jẹ́ pé ìbànújẹ́ wọ̃ lọ́rùn, tí ó sì nlọ pẹ̀lú ìpọ́njú àti ìrora ọkàn, nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìlú-nlá Amonáíhà, ó sì ṣe, bí Álmà sì ti ṣe kún fún ìbànújẹ́, wõ, ángẹ́lì Ọlọ́run kan yọ síi, tí ó wípé:

15 Alábùkún-fún ni ìwọ, Álmà; nítorínã, gbé orí rẹ sókè kí o sì yọ̀, nítorítí ìwọ ní ìdí pàtàkì láti yọ̀; nítorítí ìwọ ti jẹ́ olódodo nípa pipa awọn òfin Ọlọ́run mọ́, láti ìgbàtí ìwọ ti kọ́kọ́ gba ọ̀rọ̀ láti ọwọ́ rẹ̀. Kíyèsĩ, èmi ni ẹnití ó fíi fún ọ.

16 Sì kíyèsĩ, a rán mi láti pàṣẹ fún ọ pé kí o padà lọ sí ìlú-nlá Amonáíhà, kí o sì tún wãsù sí àwọn ènìyàn ìlú nã; bẹ̃ni, kí o wãsù sí nwọn. Bẹ̃ni, wí fún wọn, bí wọn kò bá ronúpìwàdà Olúwa Ọlọ́run yíò pa wọ́n run.

17 Nítorí kíyèsĩ, ní àkokò yí, wọ́n gbìmọ̀ láti pa òmìnira àwọn ènìyàn rẹ run, (nítorí báyĩ ni Olúwa wí) èyí tí ó sì lòdì sí ìlànà, ìdájọ́ àti òfin, èyítí ó ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ̀.

18 Nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí Álmà ti gba iṣẹ́ yíi láti ọwọ́ ángẹ́lì Olúwa, ó padà kánkán lọ sí ilẹ̀ Amonáíhà. Ó sì bá ọ̀nà míràn wọ inú ìlú-nlá nã, bẹ̃ni, ọ̀nà èyítí ó wà ní ìhà gúsù ìlú-nlá Amonáíhà.

19 Bí ó sì ti wọ ìlú-nlá nã, ebi npã, òun sì wí fún ọkùnrin kan pé: Njẹ́ ìwọ lè fún onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ìránṣẹ́-Ọlọ́run ní ohun tí yíò jẹ́?

20 Ọkùnrin nã sì wí fún un: Ará Nífáì ni èmi, èmi sì mọ̀ wípé wòlĩ mímọ́ Ọlọ́run ni ìwọ íṣe, nítorí ìwọ ni ẹni nã tí ángẹ́lì wí nínú ìran pé: Ìwọ yíò gbã. Nítorínã, tẹ̀lé mi lọ sí ilé mi èmi yíò sì fún ọ nínú oúnjẹ mi; èmi sì mọ̀ wípé ìwọ yíò jẹ́ ìbùkún fún èmi àti ilé mi.

21 Ó sì ṣe tí ọkùnrin nã gbã sí ilé rẹ̀; ọkùnrin nã sì ni à npè Ámúlẹ́kì; òun sì mú oúnjẹ jáde wá pẹ̀lú ẹran, ó sì gbé wọn sí iwájú Álmà.

22 Ó sì ṣe tí Álmà jẹ oúnjẹ, ó sì yó; ó sì súre fún Ámúlẹ́kì àti ilé rẹ, ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run.

23 Lẹ́hìn tí ó sì ti jẹun tí ó si yo; ó wí fún Ámúlẹ́kì: Èmi ni Álmà, èmi sì ni olórí àlùfã lórí ìjọ Ọlọ́run jákè-jádò ilẹ̀ nã.

24 Sì kíyèsĩ, a ti pè mí láti wãsu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín àwọn ènìyàn yíi gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀; èmi sì wà ní ilẹ̀ yíi, wọ́n kò gbà mí, ṣùgbọ́n wọ́n lé mí síta, èmi sì ti ṣetán láti kẹ̀hìn sí ilẹ̀ yíi títí láéláé.

25 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a ti pã láṣẹ fún mi kí èmi kí ó tún padà, kí èmi sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yíi, bẹ̃ni, kí èmi sì jẹ́ ẹ̀rí sí wọn nípa àìṣedẽdé nwọn.

26 Àti nísisìyí, Ámúlẹ́kì, nítorítí ìwọ fún mi ní oúnjẹ tí ìwọ sì gbà mi wọlé, ìbùkún ni fún ọ; nítorípé ebi ti pa mí, nítorítí èmi ti ngbãwẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀.

27 Álmà sì dúró fún ọjọ́ púpọ̀ pẹ̀lú Ámúlẹ́kì kí ó tó bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã.

28 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã tẹra mọ́ ìwà búburú ṣíṣe lọ́pọ̀lọpọ̀.

29 Ọ̀rọ̀ nã sì tọ Álmà wá, wípé: Lọ; kí o sì wí fún ìránṣẹ́ mi Ámúlẹ́kì, jáde lọ kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yíi, wípé—Ẹ ronúpìwàdà, nítorípé báyĩ ni Olúwa wí, tí ẹ̀yin kò bá ronúpìwàdà èmi yíò bẹ àwọn ènìyàn yí wò nínú ìbínú mi, bẹ̃ni, èmi kò sì ní ká ìbínú mi kúrò.

30 Álmà sì jáde lọ, àti Ámúlẹ́kì pẹ̀lú, lãrín àwọn ènìyàn nã, láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wọn; wọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

31 A sì fún nwọn ní agbára, tó bẹ̃ tí wọn kò rí wọn dè mọ́lẹ̀ nínú túbú; kò sì ṣeéṣe kí ẹnìkẹ́ni lè pa wọ́n; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọn kò lo agbára wọn, àfi ìgbà tí wọ́n dè wọ́n ní ìdè, tí nwọ́n sì jù wọ́n sínú túbú. Nísisìyí, a ṣe eleyĩ, kí Olúwa bá lè fi agbára rẹ̀ hàn nínú wọn.

32 Ó sì ṣe tí wọ́n jáde lọ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sĩ wãsù tí wọ́n sì nsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí àti agbára èyítí Olúwa ti fifún nwọn.