Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ọ̀kan Pàtàkì Ìpè Ẹni-Ọlá
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Ọ̀kan Pàtàkì Ìpè Ọlọ́lá

Gẹ́gẹ́ bi àwọn obìnrin ìgbàgbọ́, a lè fa lórí òtítọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ látinú àwọn ìrírí Wòlíì Joseph tí o pèsè òye fún gbígba ìfihàn ti wa.

Mo dúpẹ́ láti dojú ọ̀rọ̀ mi loni kọ ojúṣe ìtẹ̀síwáju àwọn obìnrin nínú Ìmúpadàbọ̀sípò. Ó yéni pé jákèjádò ìwé-ìtàn àwọn obìnrin ti di ibi ìyàtọ̀ kan mú nínú ètò Bàbá wa Ọ̀run. Ààrẹ Nelson kọ́ni, “Kò ní lè ṣeéṣe láti díwọ̀n ipa tí … àwọn obìnrin ni, kìí ṣe lórí àwọn ẹbí nìkan ṣùgbọ́n lórí Ìjọ Olúwa, bíi àwọn ìyàwó, àwọn ìyá, àti àwọn ìyá-ìyá; bí àwọn obìnrin àti àwọn àbúrò ìyá obìnrin; bí àwọn olùkọ́ àti olórí; àti pàápàá bíi àpẹrẹ olùfọkànsìn olùgbèjà ìgbàgbọ̀.”1

Ní ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ni Nauvoo ni ọdún méjìdinlọgọsan sẹ́hìn, Wòlíì Joseph Smith gba àwọn obìnrin ní ìmọ̀ràn láti “gbé ìgbé ayé ti o tó ànfàní [wọn].”2 Àpẹrẹ wọn kọ́ wa loni. Wọ́n fi ìṣọ̀kan tẹ̀lé ohùn wòlíì kan wọ́n si gbé pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì bí wọ́n ti ṣèrànlọ́wọ́ fi ìpìnlẹ̀ tí a dúró lé lórí nísisìyí lélẹ̀. Ẹ̀yin obìnrin, ìgbà wa nìyí. A ní iṣé ti ọ̀run láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti pe, ìrànlọ́wọ́ àràọ̀tọ̀, òtítọ́ wa ṣe kóko.

Ààrẹ Spencer W. Kimball ṣàlàyé: “Láti jẹ́ obìnrin olódodo ní àkokò ẹ̀fúùfù ní ilẹ̀ ayé, kí ó tó di ìpadàbọ̀ Olùgbàlà lẹ́ẹ̀kejì, jẹ́ ìpè pípé ọlọ́lá jùlọ. Okun obìnrin olódodo àti ipa rẹ loni lè jẹ ìlọ́po mẹwa ohun tí yio jẹ ni àwọn àkokó àlááfíà.”3

Ààrẹ Nelson bákanáà rọ̀: “Mo bẹ̀ àwọn arábìnrin mi ti ìjọ [náà] … Láti gbésẹ̀ síwájú! Ẹ gba ipò tí o tọ tí o si wúlò ní ilé yín, ni agbègbè, àti ìjọba Ọlọ́run—more ju bí ẹ ti ṣe tẹ́lẹ̀ lọ.”4

Láìpẹ́, Mo ní ànfàní, pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ọmọ alákọbẹrẹ̀, láti pàdé Ààrẹ Russell M. Nelson ní jíjọra ilé ẹbí Smith ni Palmyra, New York. Gbọ́ bi àwọn wòlíì wa ti nkọ́ àwọn ọmọde ohun tí wọn le ṣe láti gbésẹ̀ síwájú.

Arábìnrin Jones: “Mo wà ní ìyàlẹ́nu láti mọ bóyá ẹ ní ìbéèrè ti ẹ fẹ́ láti bi Ààrẹ Nelson. Ẹ wà ní ijoko pẹ̀lú wòlíì. Njẹ́ a rí ohunkóhun ti ẹ ti fẹ bi wòlíì léèrè nígbàgbogbo? Bẹ́ẹ̀ni, Pẹ́ẹ̀lìl.”

Pearl: “Njẹ ó nira láti jẹ wòlíì? Njẹ́, ẹ n, ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ gan ni?

Ààrẹ Nelson: “dájúdájú ó le. Ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹ̀lú dídà bi Olùgbàlà síi nira. Bí àpẹrẹ, nígbà ti Ọlọ́run fẹ fún Mósè ni Òfin Mẹwa, ibo ni O sọ fún Mósè ki o lọ? Orí òkè kan, orí Òkè Sínáì. Nítorínáà Mósè ní láti rìn lọ si orí òkè láti gba Òfin Mẹwa. Bayi, Bàbá Ọ̀run le sọ pé, ‘Mósè, bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀, Èmi yio bẹ̀rẹ̀ níbí, Èmi yio si pàdé rẹ laarin.’ Rárá, Olúwa fẹ́ran ìtiraka, àti pe ìtiraka nmú èrè wa ti ko le wa láì sí i. Gẹ́gẹ́ bi àpẹrẹ, njẹ́ ẹ ti gba àwọn ẹ̀kọ́ dùrù ri?”

Àwọn ọmọde: “Bẹ́ẹ̀ni.”

Pẹ́ẹ̀lì: “Mo nkọ́ faolínì.”

Ààrẹ Nelson: “Njẹ o nkọ́ọ?”

Àwọn ọmọde: “Bẹ́ẹ̀ni.”

Ààrẹ Nelson: “Kíni o nṣẹlẹ̀ tí ẹ kò bà kọ́ọ?”

Pearl: “Ẹ ó gbàgbé.”

Ààrẹ Nelson: “Bẹ́ẹ̀ni, ẹ ko ní tẹ̀síwájú, abi?” Ìdáhùn náà ni bẹ́ẹ̀ni, Pẹ́ẹ̀lì. Ó gba ìtiraka, iṣẹ́ àṣekára púpọ̀, àṣàrò púpọ̀, àti pé kò sí òpin láéláé. Ìyẹn dára! Ìyẹn dára, nítorí a ntẹ̀síwájú nígbàgbogbo. Pàápàá ní ayé tó nbọ̀ a nní ìtẹ̀síwájú.”

Èsì Ààrẹ Nelson sí àwọn ọmọ iyebíye wọ̀nyí dé ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Olúwa fẹ́ran ìtiraka, àti pe ìtiraka nmú èrè wa. À nkọ́ọ síi. A ntẹ̀síwáju nígbàgbogbo bi a bá nlàkàkà láti tẹ̀lé Olúwa.5 Ohun ko retí àṣepé loni. A ntẹramọ́ gígun Òkè Sínáì araẹni wa síi. Bí àkokò tó kọjá, ìrìnàjò wa nítòótọ́ gba ìtiraka, iṣẹ́ àṣekára, àti àṣàrò, ṣùgbọ́n ìfaramọ wa láti tẹ̀síwájú mú ère ayérayé wá.6

Kínni ohun ti a tún kọ látọ̀dọ̀ Wòlíì Joseph Smith àti Ìran Àkọ́kọ́ nípa ìtiraka, iṣẹ́ àṣekára, àti àṣàrò? Ìran Àkọ́kọ́ fún wa ni ìtọ́sọ́nà ni àràọ̀tọ̀, ìtẹ̀síwájú ojúṣe wa Gẹ́gẹ́ bi àwọn obìnrin ìgbàgbọ́, a lè fa lórí òtítọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ látinu àwọn ìrírí Wòlíì Joseph tí o pèsè òye fún gbígba ìfihàn ti wa. Fún àpẹrẹ:

  • À nṣiṣẹ́ lábẹ́ àwọn ìṣòro.

  • A yí padà si àwọn ìwé mímọ́ láti gba ọgbọ́n láti ṣe ìṣe.

  • A njúwe ìgbàgbọ́ wa àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run.

  • A lo agbára wa láti bẹ Ọlọ́run láti rànwálọ́wọ́ láti yí ipa ọ̀tá po.

  • A nfi àwọn ìfẹ́ ọkàn wa sí Ọlọ́run fúnni.

  • A dojúkọ ìmọ́lẹ̀ Rẹ ti o ntọ́ àwọn yíyàn ayé wa sọ́nà àti láti simi le wa nígbà ti a ba yípadà si I.

  • A mọ̀ pé O mọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nípa orúkọ àti àwọn ojúṣe kọ̀ọ̀kan fún wa láti múṣe.7

Ní àfikún, Joseph Smith mú ọgbọ́n padàbọ̀sípò pé a ní agbára ti ọ̀run àti ayérayé tó tọ sí wa. Nítori ìbáṣepọ̀ náà si Bàbá wa Ọ̀run, Mo gbàgbọ́ pé Ó nretí kí á gba ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Olúwa gba Emma Smith ni ìmọ̀ràn láti “gba Ẹ̀mí Mímọ́,” kẹkọ púpọ̀, “gbé àwọn ohun ayé sẹgbẹ, … wá àwọn ohun dídara,” àti láti “di àwọn májẹ̀mú” [rẹ̀] pẹ̀lú Ọlọ́run mú daindain.8 Kíkọ́ ẹ̀kọ́ jẹ́ ọ̀kan si ìlọsíwájú, pàápàánípàtàkì bi ojúgbà léraléra ti Ẹ̀mí Mímọ́ kọ wa ohun ti a nílò fún ẹnìkọ̀ọkan wa láti gbé sẹgbẹ—ó túmọ̀ sí pé ohun tí o lè dà wá lâmu tàbí ìlọsíwájú wa lọ́wọ́.

Ààrẹ Nelson wípé, “Mo bẹ̀ yín ki ẹ fi kún agbára ti ẹ̀mí yín láti gba ìfihàn.”9 Àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì wà pẹ̀lú mi títí bí mo ti nro àwọn obìnrin àti agbàra wọn láti lọsíwájú. Ó bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú wa, èyí ti o tọ́ka sí pàtàkì. Ó n kọ́ wa bí a ṣe le yè nípa ti ẹ̀mí nínú ayé aláìsàn-ẹlẹ́ṣẹ̀ nípa gbígba àti ṣíṣe lórí ìfihàn.10 Bí a ti n ṣe bẹ, bíbuọlá àti gbígbé àwọn òfin Olúwa, a ṣe ìlérí fún wa, gẹ́gẹ́bí Emma Smith ti wà, “adé òdodo kan.”11 Wòlíì Joseph kọ́ nípa pàtàkì mímọ pé Ọlọ́run fọwọ́sí ọ̀nà tí a n lépa ní ìgbésí ayé yí. Láìsí ìmọ̀ náà, a ó “ṣe àárẹ ni ọkàn [wa] a ó sì dákú.”12

Ní ìpàdé àpapọ̀ yi, a o gbọ́ àwọn òtítọ́ ti yio mí sí wa láti yí padà, dárasi, àti láti wẹ̀ ayé wa mọ́. Nípa ìfihàn araẹni, a le dèna ohun ti àwọn kan pè ní “ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò pọ̀jù”—nígbàtí a ba gba ti a si pinnu lati ṣe gbogbo bayi. Àwọn obìnrin wọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ate, ṣùgbọ́n ko ṣeéṣe, ko si ṣe kókó, láti wọ gbogbo rẹ lẹ́ẹ̀kanáà. Ẹ̀mí ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu èyí iṣẹ́ ti a o fojú si loni.13

Ipa olùfẹ́ni Olúwa nípa Ẹ̀mí Mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ipò Rẹ fún ìlọsíwájú wa. Gbígbọ́ ìfihàn araẹni darí lọ sí ìlọsíwájú araẹni.13 A fetísílẹ̀ a sì ṣe ìṣe.14 Olúwa wípé, “Bèèrè lọ́wọ́ Bàbá ni orúkọ mi nínú ìgbàgbọ̀, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ o ri gbà, ẹ o si ni Ẹ̀mí Mímọ́, ti o nfi ohun gbogbo ti o ṣànfàní hàn.”15 Ojúṣe ìtẹ̀síwájú wa ni láti gba ìfihàn ìtẹ̀síwájú.

Bí a ti ni àṣeyọrí ti òye tí o tóbi púpọ̀ bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, a lè gba agbára síi nípa ojúṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ṣiṣẹ ìránṣẹ́ àti láti mú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbésókè ṣẹ—láti ni tòótọ́ “gbé sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ohun ayé yi, kí a si wa àwọn ti o dára.”16 Nìgbánáà a le mísí àwọn ìran wa tó n dìde dáadáa láti ṣe bákannáà.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, gbogbo wa n wá agbára Ọlọ́run nínú ayé wa.17 Ìṣọ̀kan rírẹwà wà laarin àwọn ọkùnrin àti obìnrin ni ṣíṣe àṣepé iṣẹ́ Ọlọ̀run loni. A ní ààyè sí agbára oyèàlúfáà nípa àwọn májẹ̀mú, ti a ṣe lakọkọ nínú omi ìrìbọmi àti nígbànáà laarin àwọn odi tẹ́mpìlì mímọ́.18 Ààrẹ Nelson kọ́ wa, “Gbogbo obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́, tí wọ́n sì nkópa ní yíyẹ́ nínú àwọn ìlànà oyèàlùfáà, ni ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run.”19

Gbígbà ti ara mi loni ni pé èmi kìí tètè fi ìgbàgbogbo mọ̀, ṣíwájú nínú ayé, pe mo ni ààyè , nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mi, sí agbára oyèàlúfáà nípa àwọn májẹ̀mú mi.21 Ẹ̀yin Arábìnrin, Mo gbàdúrà pé a o dá agbára oyèàlúfáà mọ̀ kí a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ “dàpọ̀ mọ́ àwọn májẹ̀mú [wa],”22 gbá òtítọ́ àwọn ìwé mímọ́ mọ́ra, kí a sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì alààyè wa.

Ẹ jẹ́ ki a fi ìgboyà kéde ìjọ́sìn wa si Bàbá wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa, “pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí kò mikàn nínú rẹ̀, ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá lórí àṣepé rẹ̀,, ẹni tí ó jẹ́ alágbára láti gbàlà.”23 Ẹ jẹ́ ki a fi tayọ̀tayọ̀ tẹ̀síwájú ni ìrìnàjò sí ibi gíga agbára ti ẹ̀mí wa àti láti ran àwọn ti o wa ní àyíká wa lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìfẹ́, iṣẹ́ ìsìn, àti àánú.

Alàgbà James E. Talmage fi ìrọ́nú ránwa létí, “Aṣaájú nla jùlọ ayé ti obìnrin àti ipò obìnrin ni Jésù Krístì.”24 Ní ìtúsíwẹ́wẹ́ ìparí ojúṣe ìtẹ̀síwáju àwọn obìnrin nínú ìmúpadàbọ̀sípò, àti fún gbogbo wa, ojúṣe wo ni o lókìkí jù? Mo jẹri pe láti gbọ Ọ ni,25 láti tẹ̀lé E,26 láti gbọ́kàn lé E,27 àti láti di ìtẹ̀síwájú ìfẹ́ Rẹ.28 Mo mọ̀ pé Ó wà láàyè.29 Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín