Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Oyèàlùfáà Mẹlkisèdèkì àti àwọn Kọ́kọ́rọ́ Rẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2020


Oyèàlùfáà Mẹlkisèdèkì àti àwọn Kọ́kọ́rọ́ Rẹ̀

Nínú Ìjọ àṣẹ oyèàlùfáà ni à nlo lábẹ́ ìdarí ti olórí oyèàlùfáà tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà náà mú.

Mo ti yàn láti sọ̀rọ̀ síwájú sí nípa oyèàlùfáà Ọlọ́run, ẹ̀kọ́ tí a sọ tẹ́lẹ̀ latọwọ àwọn olùsọ̀rọ̀ mẹta tí wọ́n ti kọ́ wa nípa bí oyèàlùfáà ṣe nbùkún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, áti àwọn obìnrin.

Oyèàlùfáà jẹ́ agbára tọ̀run àti aṣẹ tí a dìmú ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ láti lo fún iṣẹ́ Ọlọ́run fún èrè ti gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Oyèàlùfáà kìí ṣe àwọn wọnnì tí a yàn sí ipò oyèàlùfáà kan tàbí àwọn wọnnì tí wọ́n lo àṣẹ rẹ̀. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n di oyèàlùfáà mú kìí ṣe oyèàlùfáà náà. Nígbàtí a kò gbọ́dọ̀ tọ́kasí wọn bí oyèàlùfáà, ó ṣe déédé láti tọ́ka sí wọn bí àwọn olùdìmú ti oyèàlùfáà.

Agbára oyèàlùfáà wà nínú ìṣètò Ìjọ àti nínú ẹbí méjèèjì. Ṣùgbọ́n agbára àti iṣẹ́ àṣẹ oyèàlùfáà yàtọ̀ nínú Ìjọ ju bí wọ́n ti ṣe nínú ẹbí. Gbogbo èyí jẹ́ gẹ́gẹ́bí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí Olúwa ti gbé kalẹ̀. Èrò ètò Ọlọ́run ni láti darí àwọn ọmọ Rẹ̀ sí ìyè ayérayé. Àwọn ẹbí ayé ṣe pàtàkì sí ètò náà. Ìjọ wà láti pèsè ẹ̀kọ́, àṣẹ, àti àwọn ìlànà tó ṣeéṣe láti ṣe ìbáṣepọ̀ ẹbí lọ sí ayé àìlópin. Báyìí, ìṣètò ẹbí àti Ìjọ Jésù Krístì ní ìwọpọ̀ títúnṣe ìbáṣepò. Àwọn ìbùkún oyèàlùfáà—bíiti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àti àwọn ìlànà bí ìrìbọmi, ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, ìrónilágbára tẹ́mpìlì, àti ìgbeyàwó ayérayé—wà fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin bákannáà.1

Oyèàlùfáà tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí ni Oyèàlùfáà Mẹlkisédékì, tí a múpadàbọ̀sípò ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere. Joseph Smith àti Oliver Cowdery ni a yàn latọwọ Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù, tí wọ́n kéde arawọn “bí ẹni tó ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba, àti ti àkokò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìgbà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:20). Awọn Àpọ́stélì àgbà wọ̀nyí gba àṣẹ látọ̀dọ̀ Olùgbàlà Fúnrarẹ̀. Gbogbo àṣẹ tàbí ipò nínú oyèàlùfáà jẹ́ asomọ́ sí Oyèàlaùfáà Mẹlkisèdékì (Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:5), nítorí ó “di ẹ̀tọ́ àjọ ààrẹ mú, ó sì ní agbára àti àṣẹ lórí gbogbo ipò nínú ìjọ ní gbogbo ìgbà ti ayé” (Doctrine and Covenants 107:8).

Nínú Ìjọ àṣẹ ti oyèàlùfáà títóbi jùlọ, Oyèàlùfáà Mẹ́lkisédékì, àti kékeré jùlọ tàbí Oyèàlùfáà Áárọ́nì ni à nlò lábẹ́ ìdarí olórí oyèàlùfáà kan, bíi bíṣọ́ọ̀pù tàbí ààrẹ, tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà náà mú. Láti ní òye ìlò àṣẹ oyèàlùfáà nínú Ìjọ, a gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà.

Àwọn kọ́kọ́rọ́ Oyèàlùfáà Mẹ́lkisédékì ti ìjọba ni a gbà látọwọ́ Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhànnù, ṣùgbọ́n ìyẹn kò parí ìmúpadàbọ̀sípò ti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà. Àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà kan wá lẹ́hìnnáà. Títẹ̀lé ìyàsímímọ́ tẹ́mpìlì àkọ́kọ́ ti àkokò yí ní Kirtland, Ohio, àwọn wolíì mẹ́ta Mósé, Eliasu, àti Elijah, mú “àwọn kọ́kọ́rọ́ àkokò yí padábọ̀sípò,” pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ tó ní íṣe sí ìkójọ Ísráẹ́lì àti iṣẹ́ àwọn tẹ́mpìlì Olúwa (Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 110), bí Ààrẹ Eyring ti ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàpèjúwe nínú ìrọni gidi.

Àpẹrẹ iṣẹ́ àwọn kọ́kọ́rọ́ tó bániláramu jùlọ ni ó wà nínú ìṣe ti àwọn ìlànà oyèàlùfáà. Ìlànà kan jẹ́ ìṣe ọ̀wọ̀ tó nfi dídá májẹ̀mú hàn àti ìlérí àwọn ìbùkún. Nínú Ìjọ gbogbo àwọn ìlànà ni à nṣe lábẹ́ ìpàṣẹ olórí oyèàlùfáà ẹnití ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ mú fún ìlànà náà.

Ìlànà kan ló wọ́pọ̀ ní ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ẹni tí a ti yàn sí ipò kan nínú ṣíṣé iṣẹ́ lábẹ́ ìdarí ẹnìkan tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà mú. Fún àpẹrẹ, àwọn olùdìmú onìrurú ipò ti Oyèàlùfáà Áárọ́nì nṣe iṣẹ́ nínú ìlànà oúnjẹ Olúwa lábẹ́ àwọn kọ́kọ́rọ́ àti ìdarí bíṣọ́ọ̀pù, ẹnití ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà mú. Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kannáà wúlò sí àwọn ìlànà oyèàlùfáà nínú èyí tí àwọn obìnrin ti nṣe iṣẹ́ nínú tẹ́mpìlì. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn obìnrin kò di ipò kan mú nínú oyèàlùfáà, wọ́n nṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì mímọ́ lábẹ́ ìpàṣẹ ààrẹ tẹ́mpìlì, ẹnití ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ fún àwọn ìlànà tẹ́mpìlì mú.

Àpẹrẹ míràn ti àṣẹ oyèàlùfáà lábẹ́ ìdarí ẹnìkan tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ mú ni àwọn ìkọ́ni ọkùnrin àti obìrin tí a pè láti kọ́ni ní ìhìnrere, bóyá ní yàrá-ìkàwé nínú wọ́ọ̀dù ti arawọn tàbí ní pápá iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Àwọn àpẹrẹ míràn ni àwọn wọnnì ẹnití ó di àwọn ipò olórí mú nínú wọ́ọ̀dù tí wọ́n sì nlo àṣẹ oyèàlùfáà nínú ipò olórí wọn nípasẹ̀ èrèdí àwọn ipè wọn àti lábẹ́ ìgbọ́wọ́lélórí àti ìdarí olórí oyèàlùfáà tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ mú nínú wọ́ọ̀dù àti èèkàn. Báyìí ni a ṣe nlo tí a sì ngbádùn àṣẹ àti agbára oyèàlùfáà ní Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.2

Àṣẹ Oyèàlùfáà bákannáà nlo àti pé àwọn ìbùkún rẹ̀ wá nínú ẹbí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Nípa àwọn ẹbí mò ntúmọ̀ pé ọkùnrin olùdìmú-oyèàlùfáà kan àti obìrin tí wọ́n ṣègbeyàwó àti àwọn ọmọ wọn. Bákannáà mo fi pẹ̀lú àwọn oríṣiríṣi láti àwọn ìbáṣepọ̀ tótọ́ bí èyí tó ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ ikú tàbí ìkọni.

Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí àṣẹ oyèàlùfáà lè lò lábẹ́ ìdarí ẹnikan tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ mú fún iṣẹ́ náà jẹ́ ìpìlẹ̀ nínú Ìjọ, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nínú ẹbí. Fún àpẹrẹ, bàbá kan nṣàkóso àti lílo oyèàlùfáà nínú ẹbí rẹ̀ nípasẹ̀ àṣẹ oyèàlùfáà tó dìmú. Òun kò nílò láti ní ìdarí tàbí àṣẹ ẹnìkan tó di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà mú ní èrò láti ṣe onírurú iṣẹ́ ẹbí rẹ̀. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú dídámọ̀ràn ọmọ ẹbí rẹ̀, ṣíṣe ìpàdé ẹbí, fífúnni ní àwọn ìbùkún oyèàlùfáà sí ìyàwó àti ọmọ rẹ̀, tàbí fifi àwọn ìbùkún ìwòsàn fún ọmọ ẹbí tàbí àwọn ẹlòmíràn.3 Àwọn àṣẹ Ìjọ nkọ́ ọmọ ẹbí ṣùgbọ́n kò darí lílo àṣẹ oyèàlùfáà nínú ẹbí.

Irú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kannáà wúlò nígbàtí kò bá sí bàbá tí ìyá sì jẹ́ olórí ẹbí. Ó nṣàkóso nínú ilé rẹ̀ ó sì jẹ́ ẹni tó nmú agbára àti ìbùkún oyèàlùfáà wá sínú ẹbí rẹ̀ nípasẹ̀ ìronilágbára rẹ̀ àti ìsopọ̀ nínú tẹ́mpìlì. Nígbàtí a kò fun láṣẹ láti fúnni ní àwọn ìbúkún oyèàlùfáà tí a lè fúnni nìpasẹ̀ ẹnìkan tó di ipò kan pàtó mú nínú oyèàlùfáà, ó lè ṣe gbogbo àwọn iṣẹ́ míràn ti ipò olórí nínú ẹbí. Ní ṣiṣe bẹ́ẹ̀, ó nlo agbára oyèàlùfáà fún èrè àwọn ọmọ lórí àwọn ohun tí òun ti nṣàkóso ní ipò olórí rẹ̀ nínú ẹbí.4

Bí àwọn bàbá yíò bá gbé oyèàlùfáà wọn ga nínú ẹbí ara wọn, yíò mú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ìjọ lọ síwájú pupọ̀ bí ohunkóhun míràn tí wọ́n lè ṣe. Àwọn bàbá tí wọ́n di Oyèàlùfáà Mẹlkisédékì mú gbọ́dọ̀ lo àṣẹ wọn “nípasẹ̀ ìyínilọ́kànpadà, nípasẹ̀ ìpamọ́ra, nípasẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ àti ọkàn pẹ̀lẹ́, àti nípasẹ̀ ifẹ́ àìṣẹ̀tàn” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 121:41). Àṣíá gíga fún ìlò gbogbo àṣẹ oyèàlùfáà ni ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ẹbí. Àwọn olùdìmú oyèàlùfáà gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin mọ́ kí wọ́n lè ní agbára oyèàlùfáà láti fi àwọn ìbùkún fún ọmọ ẹbí wọn. Wọn gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí ìfẹ́ni kí àwọn ọmọ ẹbí wọn lè nifẹ láti bèèrè fún àwọn ìbùkún. Àti pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ gbani-níìyànjú si fún àwọn ìbùkún oyèàlùfáà nínú ẹbí.5

Nínú àwọn ìpàdé àpapọ̀ wọ̀nyí, bí a ti nwa ìborí ránpẹ́ látinú àwọn àníyàn ara wa pẹ̀lú ààrùn burùkú, a ti kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ nlá ti àìlópin. Mo gba ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níyànjú láti ní ojú “tààrà” láti gba àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nípa àìlópin kí ara wa “lè kún fún ìmọ́lẹ̀” (3 Néfì 13:22).

Nínú ìwààsù Rẹ̀ sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn tí a kọ sílẹ̀ nínú Bíbélì àti nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Olùgbàlà kọ́ni pé ara ikú le kún fún ìmọ́lẹ̀ tàbí kún fún òkuǹkùn. Àwa, bẹ́ẹ̀náà, nfẹ́ kún fún ìmọ́lẹ̀, àti pé Olùgbàlà kọ́ wa bi a ṣe le mú èyí ṣẹlẹ̀. A gbọ́dọ̀ fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ nípa àwọn òtítọ́ àìlópin. Ó lo àpẹrẹ ojú wa, nípa èyí tí à nmú ìmọ́lẹ̀ sínú ara wa. Bí ojú wa bá “jẹ́ tààrà”—ní ọ̀nà míràn bí a bá ngbáralé gbígba ìmọ́lẹ̀ àti níní ìmọ̀—Ó ṣàlàyé, “gbogbo ara yín yíò kún fún ìmọ́lẹ̀” (Matthew 6:22; 3 Nephi 13:22). Ṣùgbọ́n bí “ojú wa bá jẹ́ ibi”—ìyẹn ni bí a bá nwá ibi tí a sì ngba ìyẹn sínú ara wa—Ó kìlọ̀, “gbogbo ara yín yíò kún fún òkùnkùn” (ẹsẹ 23 Ní ọ̀nà míràn, ìmọ́lẹ̀ tàbí òkùnkùn nínú ara wa dá lórí bí a ṣe ri—tàbí gba— àwọn òtítọ́ ayérayé tí a kọ́ wa.

A gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìfipè Olùgbàlà láti wákiri kí a sì bèèrè láti ní ìmọ̀ àwọn òtítọ́ ti àìlópin. Òun ṣèlérí pé Bàbá wa ní Ọ̀run nfẹ́ láti kọ́ gbogbo ènìyàn ní àwọn òtítọ́ tí wọ́n nwá (wo 3 Néfì 14:8). Bí a bá fẹ́ èyí tí a sì ní ojú tààrà láti gba, Olùgbàlà nṣèlérí pé àwọn òtítọ́ àìlópín “yíò ṣí” sí wa (wo 3 Néfìi 14:7–8).

Ní ìlòdì, Sátánì nní ìtara láti da ríronú wa láàmú tàbí láti darí wa ṣìnà lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì bíi ti ṣíṣé oyèàlùfáà Ọlọ́run. Olùgbàlà kìlọ̀ “àwọn wòlĩ èkè, tí wọn ntọ̀ yín wá nínú awọ àgùtàn, ṣùgbọ́n apanijẹ ìkòkò ni wọ́n nínú” (3 Néfì 14:15). Ó fún wa ní ìdánwò yí láti rànwálọ́wọ́ lati yan òtítọ́ látinú àwọn onírurú ìkọ́ni tí ó lè dàrú mọ́ wa: “Nípa èso wọn ní a ó fi mọ̀ wọ́n,” Ó kọ́ni (3 Néfì 14:16). “Igi rere kan kò lè so èso búburú, bẹ̃ni igi búburú kò sì lè so èso rere” (ẹsẹ 18). Nítorínáà, a gbọ́dọ̀ wá àbájáde—“èso náà”—àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a kọ́ àti àwọn ẹni tí ó kọ́ wọn. Ìyẹn ni ìdáhùn tó darajùlọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòdìsí tí à ngbọ́ ní ìlòdì sí Ìjọ àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti àwọn ìṣètò àti ti olórí. Tẹ̀lé ìdánwò tí Olùgbàlà kọ́ni. Wo àbájáde—àwọn èso.

Nígbàtí a ronú nípa èso ìhìnrere àti ìmúpadabọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì, a yọ̀ nínú bí Ìjọ, ní ìgbàayé ti àwọn alààyè ọmọ ìjọ, ti gbòòrò láti gbogbo ìjọ ìbílẹ̀ ní orí òkè Ìwọ̀-oòrùn sí ibi tí ọ̀pọ̀ lára míllíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ọmọ ìjọ rẹ̀ ti ngbè ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn ju United States. Pẹ̀lú ìdàgbà náà, a ti ní àlékún nínú agbára Ìjọ láti ṣàtìlẹhìn àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀. À nṣàtìlẹhìn láti pa àwọn òfin mọ́, ní mímú àwọn ojúṣe láti wàásù ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ṣẹ, ní kíkó Ísráẹ́lì jọ, àti ní kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì káàkiri gbogbo ayé.

À ngba ìdarí látọwọ́ wòlíì kan, Ààrẹ Russell M. Nelson, ipò olórí ẹnití Olúwa ti lò láti ṣe àṣeyege ìlọsíwájú tí a ní ní ìgbà ìdarí ọdún méjì rẹ̀. Báyìí a ó di alábùkún láti gbọ́ ní ẹnu Ààrẹ Nelson, ẹnití yíò kọ́ wa bí a ó ṣe ní ìlọsíwájú si nínú Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Jésù Krístì ní àwọn ìgbà ípeniníjà wọ̀nyí.

Mo jẹ́ri nípa òtítọ́ àwọn ohun wọ̀nyí mo sì darapọ̀ mọ yín nínú àdúrà fún wòlíì wa látọ̀dọ̀ ẹnití à ó gbọ́ tẹ̀le, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ráńpẹ́

  1. Wo Dallin H. Oaks, “Àṣẹ Oyèàlùfáà nínú Ẹbí àti Ìjọ,”Priesthood Authority in the Family and the Church,” Liahona, Nov. 2005, 24–27.

  2. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣura ti Ẹ̀mí,” Liahona, Nov. 2019, 76–79; Dallin H. Oaks, “Àṣẹ Oyèàlùfáà nínú Ẹbí àti Ìjọ,” 24-27; Dallin H. Oaks,“Àwọn Kọ́kọ́rọ́ àti Àṣẹ Oyèàlùfáà,” Liahona, May. 2014, 49–52.

  3. Wo Dallin H. Oaks, “Àwọn Agbára Oyèàlùfáà,” Liahona, May 2018, 65–68.

  4. Russell M. Nelson, “Àwọn Ìṣúra ti ẹ̀mí,” 76-79.

  5. Wo Russell M. Nelson, “Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ pẹ̀lú Agbára àti Àṣẹ Ọlọ́run,” Liahona, May 2018, 68–75; Dallin H. Oaks, “agbára Oyèàlùfáà,“ 65–68.