2010–2019
Àwọn ìṣura ti Ẹ̀mí
Oṣù Ẹ̀kẹwá 2019


Àwọn ìṣura ti Ẹ̀mí

Bí ẹ ṣe nlo ìgbàgbọ́ yín nínú Olúwa àti agbára oyèàlùfáà Rẹ̀, okun yín láti fa agbára ìṣura ti ẹ̀mí tí Olúwa ti pèsèsílẹ̀ fún yín yíò pọ̀ si.

E ṣe fún orin alárinrin yẹn. Bí agbogbo wa ṣe dìde láti orin àárín, “A Dúpẹ́ lọ́wọ́ Yín, Óò Ọlọ́run, fún Wòlíì kan,” mo ní èrò ìbonimọ́lẹ̀ méjì tí ó wá sínú mi. Ọ̀kan ni nípa Wòlíì Joseph Smith, wòlíì àkokò yí. Ìfẹ́ mi àti ìwuni fún un ndàgbàsi ní ojoojúmọ́. Èrò kejì ṣẹlẹ̀ bí mo ti nwo ìyàwó mi, àwọn ọmọbìnrin mi, awọn ọmọ-ọmọ ọmọbìnrin, àti ọmọ-ọmọ-ọmọ ọmọbìnrin. Mo nímọ̀lára bíì ípé kí ngba gbogbo yín bí ara ẹbí mi.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù sẹ́hìn, ní ìparí abala ìfúnni lẹ́bùn agbára, mo wí fún ìyàwó mi Wendy pé, “Mo nírètí pé àwọn arábìnrin ó ní ìmọ̀ ìṣura ti ẹ̀mí tí ó jẹ́ tiwọn nínú tẹ́mpìlì.” Ẹ̀yin arábìnrin, nígbàkugbà mò nrí ara mi ní ríronú nípa yín, àti ní oṣù méjì sẹ́hìn nígbàtí Wendy àti èmi bẹ Harmony, Pennysylvania wò.

Àwòrán
Ìmúpadàbọ̀sípò Oyèàlùfáà Árọ́nì

Èyí ni ìrìnàjò ìkejì wa síbẹ̀. Ìgbà méjèèjì ni a ní ìjìnlẹ̀ ara bí a ti nrìn lórí ilẹ̀ mímọ́ náà. Nítòsí Harmony ni Jòhánnù onírìbọmi ti farahàn sí Joseph Smith tí ó sì mú Oyèàlùfáà Árọ́nì padàbọ̀sípò.

Àwòrán
Ìmúpadàbọ̀sípò Oyèàlùfáà Mẹ́lkìsédékì

Ibẹ̀ ni àwọn Àpọ́stélì Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù ti farahàn láti mú Oyèàlùfáà Mẹlkisédékì padàbọ̀sípò.

Ní Harmony ni Emma Hale Smith ti sìn bí akọ̀wé àkọ́kọ́ sí ọkọ rẹ̀ nígbàtí Wòlíì Joseph ṣe àyípadà-èdè tí Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Bákannáà Harmony náà ni Joseph ti gba ìfihàn tó fi ìfẹ́ Olúwa hàn sí Emma. Olúwa pàṣẹ fún Emma láti ṣàlàyé àwọn ìwé mímọ́, láti gba Ìjọ níyànjú, láti gba Ẹ̀mí Mímọ́, àti láti lo àkókò rẹ̀ láti “kẹkọ pupọ̀.” Bákannáà Emma gba àmọ̀ràn láti “gbé àwọn ohun ayé sẹgbẹ àti láti wá àwọn ohun dídara,” àti láti di àwọn májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run mú daindain. Olúwa parí àṣẹ Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ipá wọ̀nyí pé: “Èyí ni ohùn mi sí gbogbo ènìyàn.”1

Ohun gbogbo tó ṣẹlẹ̀ ní Harmony ní ìjìnlẹ̀ ìwémọ́ fún ìgbé ayé yín. Ìmúpadàbọ̀sípò oyèàlùfáà, lẹgbẹ pẹ̀lú ìmọ̀ràn Olúwa sí Emma, lè tọ́wásọ́nà kí ó sí ìbùkún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Bí mo ṣe nwá kí ẹ ní ìmọ̀ tó pé ìmúpadàbọ̀sípò oyèàlùfáà ṣe pátákì sí yín bí obìnrin bí ó ṣe jẹ́ sí ọ̀kùnrin kọ̀ọ̀kan. Nítorí Oyèàlùfáà Mẹ́lkìsédékì ti padàbọ̀sípò, gbogbo àwọn olùpamọ́-májẹ̀mú obìnrin àti ọkùnrin ní ààyè sí “gbogbo àwọn ìbùkún ti ẹ̀mí ìjọ,”2 tàbí, a lè wípé, sí gbogbo ìṣura tí ẹ̀mí tí Olúwa ní fún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Gbogbo obìnrin àti ọkùnrin tí wọ́n dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run tí wọ́n sì npa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́, tí wọ́n sì nkópa ní yíyẹ́ nínú àwọn ìlànà oyèàlùfáà, ni ààyè tààrà sí agbára Ọlọ́run. Àwọn wọnnì tí a ti fún lágbára ẹ̀bùn nínú ilé Olúwa ti gba ẹ̀bùn agbára oyèàlùfáà nípasẹ̀ ìwàrere májẹ̀mú wọn, lẹgbẹ́ pẹ̀lú ẹ̀bùn ìmọ̀ láti mọ bí wọ́n ṣe lè nípa lórí agbára náà.

Àwọn ọ̀run ṣí sí àwọn obìnrin tí wọ́n ti gba agbára ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára Ọlọ́run tó nsàn látinú àwọn májẹ̀mú oyèàlùfáà bí wọ́n ṣe wà sí àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní oyèàlùfáà. Mo gbàdúrà pé òtítọ́ yíò tẹ̀ mọ́ ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yín nítorí mo gbàgbọ́ pé yíò yí ayé yín padà. Ẹ̀yin arábìnrin, ẹ ti ní ẹ̀tọ́ láti gba agbára Olùgbàlà láti ràn ẹbí yín àti àwọn míràn tí ẹ fẹ́ràn lọ́wọ́.

Nísisìyí, ẹ lè máa sọ fúnara yín pé, “Èyí dàbí ìyàlẹ́nú, ṣùgbọ́n báwò ní èmi ó ti ṣe? Báwo ni èmi ó ti fa agbára Olùgbàlà wá sínú ayé mi?

Ẹ kò lè rí ètò yí ní kíkọ sílẹ̀ sínú ìwé kankan. Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́ olùkọ́ni araẹni yín bí ẹ ti nwá láti ní ìmọ̀ ohun tí Olúwa yíò fẹ́ kí ẹ mọ̀ àti kí ẹ ṣe. Ètò yí ko yára tàbí rọrùn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìmúlò ti ẹ̀mí. Kíni ó lè ṣeéṣe láti dùnmọ́ni ju láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí láti ní ìmọ̀ agbára oyèàlùfáà—agbára Ọlọ́run?

Ohun tí mo sọ fún yín ni pé wíwá agbàra Ọlọ́run nínú ayé yín nfẹ́ àwọn ohun kannáà tí Olúwa pàṣẹ fún Emma àti ẹnìkọ̀ọ̀kan yín láti ṣe.

Nítorínáà, mo pè yín láti ṣàṣàrò ìpín 25 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú tàdúràtàdúrà kí ẹ ṣàwárí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ yíò kọ́ọ yín. Ìṣe ti araẹni ti ẹ̀mí yíò mú ayọ̀ wá fún yín bí ẹ ti njèrè, ní ìmọ̀, àti lo agbára pẹ̀lú èyí tí a ti fún yín lagbára ẹ̀bùn.

Ara ìṣe yí yíò gba kí ẹ gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ayè sẹgbẹ. Nígbàmíràn a fẹ́rẹ̀ nsọ̀rọ̀ ṣákálá nípa rírìn kúró nínú ayé pẹ̀lú ìjà, àwọn ìlàkọjá àdánwò, àti àwọn ọgbọ́n ayé. Ṣùgbọ́n lotitọ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nfẹ́ kí ẹ yẹ ìgbé aye yín wò dáadáa àti léraléra. Bíẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò ṣíi yín létí nípa ohun tí kò wúlò mọ́, ohun tí kò yẹ fún àkokò yin àti okun.

Bí ẹ̀ ṣe ngbé ojú kúrò nínú àwọn ìdàmú ayé, àwọn ohun tò dàbí ó ṣe pàtàkì sí yín nísisìyí yíò rẹlẹ̀ ní ìṣíwájú-ipò. Ẹ ó nílò láti wípé rárá sí àwọn ohunkan, àní tí wọ́n lè dàbí àìléwu. Bí ẹ ṣe nbẹ̀rẹ̀ lórí tí ẹ sì ntẹ̀síwájú nínú ètò ìgbé ayé pípẹ́ ti yíya ayé yín sọ́tọ̀ fún Olúwa, àwọn ìyípadà nínú ìgbìrò, ìmọ̀lára, àti okun ti ẹ̀mí yín yíò jọ yín lójú!

Nísisìyí ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ díẹ̀. Àwọn wọnnì wà tí wọ́n yíò mú okun yín láti képe agbára Ọlọ́run wálẹ̀. Àwọn kan tí yíò jẹ́ kí ẹ ṣiyèméjì ara yín àti kí ẹ dín okun ti ìràwọ̀ ẹ̀mí yín kù bí obìnrin olódodo kan.

Dájúdájú jùlọ, ọ̀tá kò fẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ májẹ̀mú tí ẹ ṣe ní ìrìbọmi tàbí ìjìnlẹ̀ agbára ẹ̀bùn ti òye àti agbára tí ẹ gbà tàbí yíò gbà nínú tẹ́mpìlì—ilé Olúwa. Àti pé dájúdájú Sàtánì kò fẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ pé gbogbo ìgbà tí ẹ bá fi yíyẹ sìn tí ẹ sì jọ́sìn nínú tẹ́mpìlì, ẹ nkúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìróni lágbára Ọlọ́run àti pẹ̀lú níní àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ láti “ṣè tọ́jú” yín.3

Sàtánì àti àwọn olùsọ́mgbe rẹ̀ yíò kó ìdènà wá láti dẹ́kùn yín ní níní ìmọ̀ àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí pẹ̀lú èyí tí ẹ ti jẹ́ àti tí ẹ lè fi gbà ìbùkún. Láìlóríre, àwọn ìdènà kan lè jẹ́ àbájáde ìṣìwàhù ẹlòmíràn. Ó nbà mí nínú jẹ́ láti rò pé ẹnìkẹ́ni lára yín ti nímọ̀lára ipatisẹgbẹ tàbí àìgbanigbọ́ látọ̀dọ̀ olórí oyèàlùfáà kan tàbí ìṣìlò tàbí dídalẹ̀ nípasẹ̀ ọkọ kan, bàbá, tàbí ẹnítí ó yẹ́ kójẹ́ ọ̀rẹ́. Mo ní ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ ìbànújẹ́ pé ẹnikẹ́ni lára yín tí ní ìmọ̀lára ìpatì, ìtàbùkù, tàbí àìdájọ́ ire. Irú àwọn àṣìṣe bẹ́ẹ̀ kò ní ipò nínú ìjọba Ọlọ́run.

Ní sísọ, ó ndùn mọ́ mi nígbàtí mo bá kọ́ nípa àwọn olórí oyèàlùfáà tí wọ́n nwá ìkópa àwọn obìnrin nínú wọ́ọ̀dù àti àwọn ìgbìmọ̀ èèkàn. Mo ti ní ìmísí nípa ọkọ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti fihàn pé ojúṣe oyèàlùfáà wọn pàtàkì jùlọ ni láti tọ́jú ìyàwó wọn.4 Mo fìyìn fún ọkùnrin náà tí ó nbọ̀wọ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀ fún okun ìyàwó rẹ̀ láti gba ìfihàn tí ó sì nbọlá fun gẹ́gẹ́bí ìbádọ́gba ẹnìkejì nínú ìgbeyàwó wọn.

Nígbàtí ọkùnrin kan bá ní ìmọ̀ ọlánlá àti agbára òdodo kan, ni wíwá, obìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn alágbára ẹ̀bùn, njẹ́ ó yanilẹ́nu pé òun nnímọ̀lára bíi kó dìdedúró nígbàtí ó bá nwọ yàrá bí?

Láti ìgbà táláye tidáyé, àwọn obìnrin ti di alábùkún pẹ̀lú atọ́nà ìwà tótayọ—okun láti mọ̀ ìyàtọ̀ nínú ẹ̀tọ́ kúro nínú àṣìṣe. Ẹ̀bùn yí gbòòrò nínú àwọn wọnnì tí wọ́n ndá tí wọ́n sì npa májẹ̀mú mọ́. Ó sì ndínkù nínú àwọn wọnnì tí wọ́n nfi ìfẹ́inú pa àwọn òfin Ọlọ́run tì.

Mo yára láti fi kun pé èmi kò mú àwọn ọkùnrin kúrò nínú ìbèèrè Ọlọ́run fún wọn bákannáà láti mọ ìyàtọ̀ nínú ẹ̀tọ́ àti àṣìṣe. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, okun yín láti lóye òtítọ́ kúrò nínú àìtọ́, láti jẹ́ ẹgbẹ́ olùtọ́ni ti ìwa, ṣe kókó ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí. A sì ngbọ́kàn lée yín láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ẹ jẹ́ kí nnatán kedere nípa èyí: tí ayé yí bá sọ ìwarere àwọn obìnrin rẹ̀ nù, ayé kò ní yípadà láéláé .

Àwa Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kìí ṣe ti ayé; àwọn jẹ́ ti májẹ̀mú Ísráẹ́lì. A pè wá láti múra àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa.

Nísisìyí. njẹ́ kí nṣàlàyé àwọn àfikún àmì pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí àwọn obìnrin àti oyèàlùfáà. Nígbàtí a bá fi àmì-òróró yàn yín láti sìn nínú ipò kan lábẹ́ ìdarí ẹnìkan tí ó di kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà mú—bíi irú bíṣọ́ọ̀pù yín tàbí ààrẹ èèkàn—a fún yín ní àṣẹ oyèàlùfáà láti ṣiṣẹ́ nínú ìpè náà.

Bẹ́ẹ̀náà, nínú tẹ́mpìlì mímọ́, a fún yín láṣẹ láti múṣe àti láti ṣiṣẹ́ nínú àwọn ìlànà oyèàlùfáà ní gbogbo ìgbà tí a bá lọ. Agbára ẹ̀bùn tẹ́mpìlì nmúra yín sílẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Tí ẹ bá ti gba agbára ẹ̀bùn ṣùgbọ́n tí ẹ kò fẹ́ ọkùnrun tó ní oyèàlùfáà tí ẹnìkan sì wí fún yín pé, “Ẹ má bínú pé ẹ kò ní oyèàlùfàà nínú ilé yín,” jọ̀wọ́ ní ìmọ̀ pé gbólóhùn náà kò tọ. Ẹ lè má ní olùdìmú oyèàlùfáà nínú ilé yín, ṣùgbọ́n ẹ ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nínú tẹ́mpìlì. Látinu àwọn májẹ̀mú wọnnì ni agbára ẹ̀bùn ti agbára oyèàlùfáà ti nṣàn sórí yín. Ẹ rántí, tí ọkọ yín bá kú, ó ṣàkóso nínú ilé yín.

Bí olódodo, alágbára ẹ̀bùn obìnrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ẹ nsọ̀rọ̀ ẹ sì nkọ́ni pẹ̀lú okun àti àṣẹ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bóyá nípa ìkìlọ̀ tàbí ìbánisọ̀rọ̀, a nílò ohùn yín ní kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Krístì. A nílò ìfọwọ́sí yín nínú ẹbí, wọ́ọ̀dù, àti àwọ ìgbìmọ́ èèkan. Kíkópa yín ṣe pàtàkì ó sì lọ́ọ̀ṣọ́.

Ẹ̀yin arábìnrin mi ọ̀wọ́n, agbára yín yíò pọ̀ si bí ẹ ṣe nsin àwọn ẹlòmíràn. Àwọn àdúrà yín, ààwẹ̀, àkokò nínú ìwé mímọ́, àti iṣẹ́ ìsìn tẹ́mpìlì, àti ìwé-ìtàn ẹbí yíò ṣí ọ̀run fún un yín.

Mo rọ̀ yín láti ṣàṣàrò gbogbo òtítọ́ tí ẹ lè rí nípa agbára oyèàlùfáà tàdúràtàdúrà. Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú àwọn ìpín 84 àti 107. Àwọn ìpín wọnnì yíò darí yín sí àwọn ẹsẹ òmíràn. Àwọn ìwé mímọ́ àti ìkọ́ni látọ̀dọ̀ àwọn wòlíì òde òní, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn kún fún àwọn òtítọ́ wọ̀nyí. Bí ìmọ̀ yín ṣe npọ̀ si àti bí ẹ ṣe nlo ìgbàgbọ́ yín nínú Olúwa àti agbára oyèàlùfáà Rẹ̀, okun yín láti fa agbára ìṣura ti ẹ̀mí tí Olúwa tí pèsèsílẹ̀ fún yín yíò pọ̀ si. Bí ẹ ṣe nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó rí ara yín ní lílè ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ẹbí ayérayé tí ó ní ìrẹ́pọ̀ sílẹ̀, ní èdidì nínú tẹ́mpìlì Olúwa, àti ìfẹ́ kíkún fún Bàbá wa Ọ̀run àti Jésù Krístì.

Gbogbo ìtiraka wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí arawa, npolongo ìhìnrere, Ènìyàn Mímọ́ pípé, àti ìràpadà okù nwápapọ̀ sínú tẹ́mpìlì mímọ́. Nísisìyí a ní tẹ́mpìlì mẹ́fàlélọ́gọ́jọ káàkiri aye, àti pé púpọ̀ ṣì nbọ̀.

Bí ẹ ti mọ̀, Tẹ́mpìlì Salt Lake, Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì, àti ilé ìsopọ̀ nítòsí Ilé Iṣẹ́ Ìjọ yíò di títúnṣe nínú iṣẹ́ tí yíò bẹ̀rẹ̀ ní òpin ọdún yí. Tẹ́mpìlì mímọ́ ni a gbọ́dọ tọ́jú kí ó sì múrasílẹ̀ láti mísí àwọn ìran ọjọ́ ọ̀la, gẹ́gẹ́bí ó ti fún àwa ìran yí lágbára..

Bí Ìjọ ṣe ndàgbà si, a ó kọ́ àwọn tẹ́mpìlì púpọ̀ si kí àwọn ẹbí lè ní ààyè sí àwọn ìbùkún títóbi jù ohun gbogbo lọ, ti ìyè ayérayé náà.5 A ka tẹ́mpìlì sí bíi ilé mímọ̀ jùlọ náà ní Ìjọ. Nígbàkugbà tí a bá kéde ètò láti kọ́ tẹ́mpìlì titun, ó di apákan pàtàkì ìwé ìtàn. Bí a ṣe sọ nihin lálẹ́yí, ẹ̀yin arábìnrin ṣe kókó sí iṣẹ́ tẹ́mpìlì, àti pé tẹ́mpìlì ni ibi tí ẹ ó ti gba àwọn ìṣúra ti ẹ̀mí gígajùlọ.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fetísílẹ̀ dáadáa àti tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bí èmi ó ṣe polongo àwọn ètò láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì mẹ́jọ titun. Tí a bá polongo ọ̀kan ní ibi tó nítumọ̀ síi yín, mo daba pé kí ẹ kan tẹ orí yín ba tàdúràtàdúrà pẹ̀lú ìmoore nínú ọkàn yín. Inú wa dùn láti polongo àwọn ètò láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì ní àwọn ibi wọ̀nyí: Freetown, Sierra Leone; Orem, Utah; Port Moresby, Papua New Guinea; Bentonville, Arkansas; Bacolod, Philippines; McAllen, Texas; Cobán, Guatemala; àti Taylorsville, Utah. Ẹ ṣé, ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n. A fi ìmoore tó jinlẹ̀ hà fún gbígba àwọn ètò wọ̀nyí àti ìfèsì ọ̀wọ̀ yín.

Nísisìyí, ní ìparí, mo fẹ́ láti fi ìbùkún kan sílẹ̀ lórí yín, kí ẹ lè ní ìmọ̀ agbára oyèàlùfáà pẹ̀lú èyí tí ẹ ti gba agbára ẹ̀bùn àti pé ẹ ó fikún agbára náà nípa lílo ìgbàgbọ́ yín nínúolúwa àti agbára Rẹ̀.

Ẹ̀yin arábìnrin ọ̀wọ́n, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tójinlẹ̀ àti ìmoore, mo fi ìfẹ́ mi hàn fún yín. Tìrẹ̀lẹ̀tirẹ̀lẹ̀, mo kéde pé Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì. Èyí ni Ìjọ Rẹ̀. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.