2014
Iṣẹ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Alágbàwí
July 2014


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kéje Ọdún 2014

Iṣẹ Ìránṣẹ́ Àtọ̀runwá ti Jésù Krístì: Alágbàwí

Fi tàdúrà tàdúrà ka ohun èlò yĩ kí o sì wá lati mọ ohun ti õ ṣe àbápín. Báwo ni níní òye ìgbé ayé ati míṣọ̀n Olùgbàlà ṣe ńmú kí ìgbàgbọ́ yin ninu Rẹ̀ pọ̀si ati bùkún awọn tí ẹ nṣe olùṣọ́ lé lórí nipasẹ̀ Abẹniwò kíkọ́ni? iwifunni síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.

Ìgbàgbọ́, Ẹbí, Ìrànlọ́wọ́

Jésù ní alágbàwí wa pẹ̀lú Bàbá. Ọ̀rọ̀ náà alágbàwí ní Látìn gbòngbò tó túmọ̀ sí“ẹnìkan tí ó ńbẹ̀bẹ̀ fún ẹlòmíràn.”1 Olùgbàlà náà bẹ̀bẹ̀ fún wa, lílo òye, ìdájọ́, àti àánú. Mímọ èyí lè kún inú wa pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìmoore fún Ètùtù Rẹ̀

“Fetísílẹ̀ sí [Jésù Krístì] ẹnití ó jẹ́ alágbàwí pẹ̀lú Bàbá, ẹnití ó ńbẹ̀bẹ̀ èrò yín níwájú rẹ̀—

“Ó sọ pé: Bàbá, kíyèsí àwọn ìjìyà àti ikú rẹ̀ ẹni tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ rárá, nínú ẹnití inú mi dùn sí gidigidi, kíyèsí ẹ̀jẹ̀ ọmọkùnrin rẹ èyí tí a ta sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ èyí tí ìwọ fún wa kí ìwọ fúnrarẹ lè ṣelógo.

“Nítorínáà, Bàbá, dá àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí tí wọ́n gbàgbọ́ ní orúkọ mi sí, kí wọ́n lè wá sọ́dọ̀ mi kí wọ́n sì ní ìyè ayérayé” (D&C 45:3–5).

Ti Krístì bí Alágbàwí wa, Alàgbà D. Todd Christofferson ti Àpéjọpọ̀ Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ pé: “Ó jẹ́ nkan ńlá pàtàkì sí mi, pé mo lè dé ìtẹ́ oore ọ̀fẹ́ nígbàkugbà àti ní ìpòkípò nípa àdúrà, pé Bàbá Ọ̀run yíò gbọ́ ìbèèrè mi, pé Alágbàwí mi, ẹni tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ rárá, ẹnití a ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, yíò bẹ̀bẹ̀ fún èrò mi.”2

Látinú Àwọn ìwé Mímọ́

Mòsíàh 15:8–9; Mórónì 7:28; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 29:5; 110:4

Látinú Ìwé Ìtàn Wa

Kààkiri gbogbo ìwé ìtàn ti ìjọ Olúwa, àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ Jésù Krístì ti tẹ̀lé Àpẹrẹ Rẹ̀. Éstérì jẹ́ olódodo àti onígboyà alágbàwí. Cóùsìn rẹ̀ Mordecai fi ẹ̀dà ti àṣẹ ọba ránṣẹ́ si pé wọn ó pa àwọn Júù run, wọ́n sì filọ̀ọ́ “pé kí ó ṣe ìbèèrè níwájú [ọba náà] fún àwọn ènìyàn rẹ̀.” Ó ṣàfikún: “Àti pé ta ló mọ̀ bóyá ìwọ ti wá sí ìjọba náà fún irú àsìkò kan gẹ́gẹ́bí èyí?” (Éstérì 4:8, 14.)

Pẹ̀lú ewu ti jíjẹ́ alágbàwí kan fún àwọn ènìyàn rẹ̀, Éstérì gbà: “bẹ́ẹ̀ni èmi ó wọ ilé tọ ọba lọ, tí ó lòdì sí òfin: bí mo bá ṣègbé, mo ṣègbé” (Éstérì 4:16)

Éstérì nígbànáà sọ̀rọ̀ sí ọba tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ó sì “wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi omijé bẹ̀ẹ́ pé … kí ó dá àwọn lẹ́tà náà padà …láti pa àwọn Jùù run.” Ó ṣàfikún, “Báwo ni mo ṣe lè faradà láti rí ìparun àwọn ìbátan mi?” (rí Éstérì 8:3, 5–6). Ọ̀kàn ọba náà sì rọ̀, ó sì gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.3

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Rí Russell M. Nelson, “Jésù Krístì—Olùkọ́ wa àti jíjù bẹ́ẹ̀ lọ” (Brigham Young University fireside, Feb. 2, 1992), 4; speeches.byu.edu.

  2. D. Todd Christofferson, “Mo mọ ẹnití mo gbẹ́kẹ̀lé,” Ensign, May 1993, 83..

  3. Àwọn Ọmọbìnrin ní Ìjọba Mi: Ìwé Ìtàn àti Iṣẹ́ Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ (2011), 21.