2014
Ìfẹ́ Ní Ilé
July 2014


Àwọn Ọmọdé

Ìfẹ́ Ní Ilé

Ọ̀run rere ńrẹ́rín lókè

Nígbàtí ìfẹ́ bá wà ní ilé

Gbogbo ayé kún pẹ̀lú ìfẹ́

Nígbàtí ìfẹ́ bá wà ní ilé

(“Ìfẹ́ Ní Ilé,” Àwọn orin, no. 294)

Bàbá Ọ̀run ńfẹ́ kí a nífẹ́ àwọn ẹbí wa kí inú wa lè dùn. Bí a bá ṣe ńsin àwọn ẹbí wa, náà ni a ṣe máa ní ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run síi àti àwọn ọmọ ẹbí wa.

Ya àwòrán ọkàn lórí ìwé kékeré kan kí o sì gé wọn jáde. Kọ àwọn àkọ̀sílẹ̀ ránpẹ́ tàbí ya àwọn àwòrán lórí wọn kí o sì gbe fún àwọn ọmọ ẹbí rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Wòó bí yíò ṣe múnú wọn dùn!