2014
Gbígbà láti Mọ Ìyá Mi àgbà
July 2014


Ọ̀dọ́

Gbígbà láti Mọ Ìyá Mi àgbà

Olùpilẹ̀ṣẹ̀ náà nísisìnyí ńgbé ní Virginia, USA.

Fún ìkan lára iṣẹ́ ṣíṣe àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin, mo yọ̀ọ̀da ara mi láti ran ìyá mi àgbà lọ́wọ́ láti wá àwọn bàbáńlá rẹ̀ nípa wíwo inú àwọn ìwé ti àwòrán kékeré níbí gbàgede ìwé ìtàn ẹbí ní Mesa, Arizona, USA. Bí a ṣe jókó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ara wa tí à ńṣàwárí fún ẹbí wa, mo bẹ̀rẹ̀sí ńjíròrò: “Njẹ́ mo mọ púpọ̀ dájúdájú nípa ìyá mi àgbà tó jókó lẹ́gbẹ́ mí nítòótọ́?”

A rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹbí, a múra ìwífúnni wọn sílẹ̀, wọ́n sì lọ sí tẹ́mpìlì Mesa arizona láti ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ wọn. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà ìyá mi àgbà fún mi ní àwọn àkójọ ìwé ìtàn ẹbí.

Nítorí ó jìyà lọ́wọ́ àrùn arunmọléegun, ó nira gan an fún ìyá mi àgbà láti tẹ̀wé. Mo gbádùn ríràn án lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọ̀ ayarabíàṣá. Lápapọ̀, a kọ àwọn ìtàn inú ayé rẹ̀ fún èrè ti ẹ̀mí ẹbí wa. Mo fẹ́ràn láti jẹ́ apákan ìgbé ayé rẹ̀ àti láti kọ́ púpọ̀ nípa ìwé ìtàn ìjọ bí a ṣe ńṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí papọ̀.