2018
Àwọn Ohun Mẹ́ta láti Rántí
February 2018


Ọdọ

Àwọn Ohun Mẹ́ta láti Rántí

Ọ̀rọ̀ náà rántí hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ninú Ìwé Mọ́mọ́nì Nífáì gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú láti rántí bí Ọlọ́run ṣe gba àwọn bàbá wọn ìṣíwájú là. Ọba Bẹ́njámínì ní kí àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí títóbi Ọlọ́run. Àti pé Mórónì pàṣẹ fún àwọn olùkàwé rẹ̀ láti rántí bí Olúwa ṣe jẹ́ alãnú tó.

Rírántí Olùgbàlà ṣe pàtàkì—àní a dá májẹ̀mú láti rántí Rẹ̀ ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bá nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Ààrẹ Eyring pè wá láti rántí àwọn ohun mẹ́ta wọ̀nyí nínú oúnjẹ Olúwa:

  1. Rántí Jésù Krístì: Ka àwọn ìwé mímọ́ nípa bí Olùgbálà ṣe sìn tí Ó sì fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Báwo ni ẹ ṣe nní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀? Báwo ni ẹ ṣe lè sìn kí ẹ sì fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti ṣe?

  2. Rántí ohun tí ẹ nílò láti dára si: Ronú lórí ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá pẹ̀lú ọkàn ìrònúpìwàdà kan. Yan ohun kan tí ẹ lè yípada, kí ẹ sì kọ sílẹ̀ bí ẹ o ṣe gbẹ̀rú si. Ẹ fi ìfojúsùn yín síbì kan tí ẹ ó ti máa ríi léraléra.

  3. Ẹ rántí ìlọsíwájú tí ẹ̀ nṣe: Ẹ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ràn yín lọ́wọ́ láti rí ìlọsíwájú rere tí ẹ̀ nṣe. Ẹ ṣe àkọsílẹ̀ ìmọ̀lára tí ẹ nní.

A kò pe, ṣùgbọ́n Olùgbàlà mọ èyí. Èyí ni ìdí tí Ó fi ní kí a rántí Òun . Rírántí Rẹ̀ nfún wa ní ìrètí àti ìrànlọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ láti gbèrú síi. Àní ní àwọn ìgbà míràn nígbàtí a bá kùnà láti rántí Rẹ̀, Ààrẹ Eyring sọ pé, “Òun nrántí yín nígbàgbogbo.”