2018
Wá láti Mọ̀ Òun àti Ẹbí Rẹ̀
February 2018


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kejì 2018

Wá láti Mọ̀ Òun àti Ẹbí Rẹ̀

Ìbẹniwò kíkọ́ní jẹ́ nípa wíwá láti mọ̀ lódodo àti láti fẹ́ràn arábìnrin kọ̀ọ̀kan kí a lè ṣe ìrànwọ́ láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun àti láti fún un ní iṣẹ́ ìsìn.

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

Rita Jeppeson àti olùkọ́ ìbẹniwò rẹ̀ ti di ọ̀rẹ́ rere bí wọ́n ti nṣe ìbẹ̀wò àti ṣíṣe àbápín àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Ṣùgbọ́n àwọn ìbẹ̀wò wọn bákanáà máa nní ṣíṣe eré àwọn ìdárayá ọ̀rọ̀ papọ̀ nínú. Ó jẹ́ ohun alárinrin sí Rítà nipa olùkọ́ ìbẹniwò rẹ̀ nítorí ó mọ pé wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ àti pé ìbẹ̀wò náà kìí ṣe láti “fi àmì sí ” orúkọ nìkan. Àwọn ohun púpọ̀ wà tí àwọn arábìnrin lè ṣe nígbà àbẹ̀wò, bíi rírìn papọ̀ tàbí fífa àwọn koríko díẹ̀ tu nínú ọgbà nígbàtí àwọn ọmọ nṣeré.

Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ pé, “Ẹ wo ara yín bí aṣojú Olúwá sí àwọn ọmọ Rẹ̀. … A ó ní ìrètí … pé ẹ ó ṣe àgbékalẹ̀ ìgbà kan ti ojúlówó àníyàn láti inú ìhìnrere fún àwọn ọmọ ìjọ, ní ṣíṣe ìtọ́jú àti aájò fún ẹnìkejì , ní sísọ ọ̀rọ̀ nípa àìní ti ẹ̀mí àti ti ara ní ọ̀nàkọnà tí ó lè ranni lọ́wọ́.”1

Olúwa nípasẹ̀ Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì pé “Kí àlejò tí nba yín gbé kí ó jásí fun yín bí ìbílẹ̀, kí ìwọ kí ó fẹ́ [ẹ] bí ara rẹ” (Leviticus 19:34). Àwọn arábìnrin tí à nṣe ìbẹ̀wò-ìkọ́ni sí lè jẹ́ “àwọn àjèjì” bí a ṣe nbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wa, ṣùgbọ́n bí a ṣe nwá láti mọ̀ òun àti ẹbí rẹ, ìfẹ́ wa yíò pọ̀ síi láti bá ara wa “gbé àwọn àjàgà , kí wọ́n ó lè fúyẹ́” kí àwọn ọkán wa sì wà ní síso papọ̀ nínú ìrẹ́pọ̀ àti ìfẹ́ ẹnikan sí òmíràn” (Mosiah 18:8, 21)

Reynal I. Aburto, Olùdámọ̀ràn kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Gbogbogbò, rántí ìgbàtí ó jẹ́ ọmọ ìjọ titun tí ó ṣe kọ ọkọ sílẹ̀ láìpẹ́. “Àwọn olùkọ́ ìbẹniwò mi wá sí ilé mi,” ni ó sọ, wọ́n sì mú ìmọ̀lára ìwúrí ti wìwà pẹ̀lú ẹni àti ìfẹ́ sí ọkàn mi.”2

Gbèrò Èyí

Ní àárín àwọn ẹbí arábìnrin tí ẹ̀ nṣe ìbẹ̀wò-ikọ́ni sí, kíni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó nbọ̀wá tí ó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa rẹ̀ kí ẹ sì rántí?

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Jeffrey R. Holland, “Aṣojú sí Ìjọ,” Liahona, Nov. 2016, 62.

  2. Reyna I. Aburto, “Ohun Ti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ Ti Jẹ́ Fún Mi?” Ìpàdé Àpapọ̀ àwọn obìnrin Unifásítì Brigham Young, May 5, 2017, LDS.org.