2022
Ìdí Tí A Fi Nsan Idamẹwa
Oṣù Kejìlá 2022


“Ìdí Tí A Fi Nsan Idamẹwa,” Làìhónà, Oṣù Kejìlá 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kejìlá 2022

Ìdí Tí A Fi Nsan Idamẹwa

Àwòrán
ẹyọ-owó tí a kójọ

Àwọn Ọmọ Ìjọ Eniyàn Mímọ́ Ojọ́-ìkẹhìn nfi ìdákan-nínú mẹwa owó tí ó wọlé fún wọn fún Ìjọ. Èyí ni à npè ní idamẹwa. Owó náà ni a nlò láti ṣe iṣẹ́ Ìjọ káàkiri ágbáyé.

Kíni Idamẹwa Jẹ́?

Ọ̀kan lára àwọn òfin Ọlọ́run ni láti san idamẹwa, èyí tí ó jẹ́ idakan-nínú mẹwa owó tí ó wọlé fún wa, sí Ìjọ Rẹ̀. Nígbàtí a bá san idamẹwa, à nfi ìmoore wa hàn sí Ọlọ́run fún àwọn ìbùkún wa. À nfi hàn pé a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa àti pé a ní ìfẹ́ láti gbọ́ràn sí I nínú ohun gbogbo.

Àwòrán
àwọn ènìyàn nmú àwọn ohun-elò wá fún Mẹlkisédékì bí dídá idamẹwa

Mẹlkisédékì—Olùṣọ́ Ilé-ìṣúra, láti ọwọ́ Clark Kelley Price

Àwọn Ìkọ́ni Májẹ̀mú Láéláé

Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti san idamẹwa láti àwọn ìgbà Májẹ̀mú Láéláé. Fún àpẹrẹ, Ábráhámù san àwọn idamẹwa (wo Gẹ́nẹ́sísì 14:18–20). Òfin idamẹwa ni a kọ́ni bákannáà nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́, ninú eyiti Mósè àti Málákì wa (wo Lẹfítíkù 27:30–34; Nehemíàh 10:35–37; Malachi 3:10).

Ìmúpadàpọ̀sípò Òfin Idamẹwa

Ní 1838, Wòlíì Joseph Smith bèèrè lọ́wọ́ Olúwa bí àwọn ọmọ ìjọ ṣe níláti san idamẹwa. Ìdáhùn Olúwa ni a kọsílẹ̀ nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 119, èyí tí ó wí pé àwọn ọmọ-ìjọ níláti fi ìdákan-nínú mẹwa ti èlé wọn wá sí Ìjọ (wo ẹsẹ 4). Àwọn olórí Ìjọ ti kọ́ni pé “èlé” túmọ̀sí owó tí ó wọlé.

Àwòrán
àwọn ènìyàn nbọ ọwọ́ nígbàtí ọ̀kan fi àpò-ìwé ṣọwọ́ sí ikeji

Àwòrán láti ọwọ́ Jamie Dale Johnson

Bí a Ṣe Nsan Idamẹwa

A lè san idamẹwa nípa kíkọ nkan sí àlàfo inú ìwé ìdáwó ti orí-ayélujára ní donations.ChurchofJesusChrist.org. Tàbí a lè kọ nkan sí àlàfo inú bébà kí a sì fi owó náà fún ọmọ àjọ bìṣọ́príkì tàbí àjọ ààrẹ ẹ̀ka kan. Gbogbo owó ni à nfi ránṣẹ́ sí olu-ilé iṣẹ́ Ìjọ, níbití àwọn olórí Ijọ (Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, áti Alákóso Bìṣọ́príkì) ti nfi àdúra gbèrò bí a ó ti lò ó.

Àwọn ìbùkún

Olúwa ti ṣe ìlérí pé àwọn tí wọ́n nsan idamẹwa yíò di alábùkún níti-ara àti níti-ẹ̀mí. Idamẹwa bakannáà nbùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run pẹ̀lú ànfàní láti kọ́ nípa Rẹ̀ àti láti dàgbà nínú ìhìnrere.

Àwòrán
Tẹ́mpìlì Salt Lake

Bi A Ti Nlo àwọn Owó Idamẹwa

Owó idamẹwa ni a nlò láti gbé Ìjọ Olúwa ga káàkiri ágbáyé. Nínu eyí ni kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì àti àwọn ilé Ìjọ míràn wa, títẹ àwọn ìwé-mímọ́ àti ohún-èlò míràn, nínáwó sí àwọn ilé-ìwé Ìjọ, àti ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìtàn ẹbí àti iṣẹ́́ ìránṣẹ́.

Kíkéde Idamẹwa

Ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún, àwọn ọmọ-ìjọ nní ìpàdé pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù wọn (tàbí ààrẹ ẹ̀ká) láti sọ fún un bí wọ́n bá jẹ́ olùsan idamẹwa ní kíkún.

Ohun tí Idamẹwa Nsanwó Fún

Àwòrán
Tẹ́mpìlì Oakland California

Àwòrán Tẹ́mpìlì Oakland California láti ọwọ́ Longin Lonczyna Jr.

Àwòrán
àwọn ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní onírurú àwọn èdè
Àwòrán
ilé-ìjọsìn