2022
Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn
Oṣù Kejìlá 2022


“Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022

Lúkù 2:8-20.

Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn

Àwòrán
àwọn olùṣọ́-àgùtàn

Ní òru dídákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, àwọn olùṣọ́-àgùtàn nfi taratara ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn.

Àwòrán
àgùtàn

Àwọn olùṣọ́-àgùtàn ní iṣẹ́ kan pàtàkì. Àgùtàn nílò oúnjẹ, omi, àti ààbò kúrò nínú ewu.

Àwòrán
ángẹ́lì

Lójijì, ángẹ́lì kan farahàn!

“Má bẹ̀rù, nítorí kíyèsi, mo mú ihìnrere ayọ nlá wá fún yín. … Nítorí a bí Olùgbàlà … fún yín lóní, èyí tíí ṣe Krístì Olúwa.”

Àwòrán
ángẹ́lì

Ángẹ́lì náà wí fún àwọn olùṣọ́-àgùtàn náà pé wọn yíò rí ọmọ náà tí a fi ọ̀já wé, tí ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran ní Bẹ́tlẹ́hẹ́mù.

Àwòrán
àwọn akọrin bí ti-ángẹ́lì

àwọn akọrin kan bí ti-ángẹ́lì kún òfúrufú wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àngẹ́lì náà ní yíyin Ọlọ́run.

“Ògo fún Ọlọ́run lóke, àti àláfíà ní aye, ìfẹ́-inú rere sí ènìyàn.”

Àwòrán
àwọn olùṣọ́-àgùtàn

“Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù kí a sì rí ohun tí Olúwa ti sọ di mímọ̀ sí wa.”

Àwòrán
àwọn olùṣọ́-àgùtàn ntẹ̀lé ìràwọ̀

Àwọn olùṣọ-àgùtàn kò dúró. Èyí ṣe pàtàkì púpọ̀! Wọ́n “wá pẹ̀lú ìyára” sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù.

Àwòrán
àwọn olùṣọ́-àgùtàn ní ibùjẹ́ ẹran

Àwọn olùṣọ́-àgùtàn rí Jésù tí a fi ọ̀já wé, tí ó dùbúlẹ̀ sí ibùjẹ́ ẹran, gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì náà ti wí.

Àwòrán
Jésù ọmọ-ọwọ́

Èyí ni Mèssíàh tí a ṣe ìlérí ẹni tí ó wá láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé àti láti mú ayọ̀ òtítọ́ wá fún wa!

Àwòrán
àwọn olùṣọ́-àgùtàn

Inú àwọn olùṣọ́-àgùtàn dùn jọjọ! Wọ́n pín ohun tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí.

“A bí Olùgbàlà aráyé!”

“Mèssíàh ti wá ní ìgbẹ̀hìn!”

Àwòrán
Ọ̀dọ́mọdékùnrin nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́

Àwọn olùṣọ́-àgùtàn “wá pẹ̀lú ìyára” sọ́dọ̀ Jésù. Ẹ lè ṣeé bákannáà!

Ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀.

Àwòrán
Ọ̀dọ́mọkùnrin ngé oko

Ẹ lè sìn Ín nípa sísin àwọn ẹlòmíràn.

Àwòrán
Ọ̀dọ́mọbìnrin npín Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú ọ̀dọ́mọkùnrin

Ẹ lè jẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀.