2022
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù
Oṣù Kejìlá 2022


“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù,” Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2022

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù”

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2022

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àwọn Orúkọ Jésù

Àwòrán
Ezekiel nkọ̀wé

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì kọ́ni nípa Jésù Krístì. Wọ́n wípé a ó bí I láti fi bí a ó ti gbé ìgbé ayé hàn wá. Wọ́n lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ láti kọ́ni nípa Rẹ̀.

Àwòrán
Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Nígbàmíràn nínú àwọn ìwé-mímọ́ a pe Jésù ní Ìmmánúẹ́lì. Orúkọ náà túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”

Àwòrán
Títẹ Bíbélì jáde ní ilé-iṣẹ́ àtẹ̀jáde ìtẹ̀wé àkọ́kọ́

Bákannáà Jésù ni a pè ní Mèssíàh. Mèssíàh túmọ̀ sí “ẹni-àmì-òróró.” Jésù kú fún wa kí a lè gbé pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kansi.

Àwòrán
Joseph Smith nṣe ìyírọ̀padà-èdè Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú Emma bí akọ̀wé

Jésù ni Olùgbàlà wa. Ó gbà wá là kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wa.

Àwòrán
Jésù Krístì
Àwòrán
ẹbí nka àwọn Ìwé-mímọ́

Orúkọ míràn fún Jésù ni Ọmọ Aládé Àláfíà. Nígbàtí ẹ̀rù bá bà wá tàbí a bínú, Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára àláfíà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

Àwòrán
Àwọn ọmọdé pẹ̀lú ọkùnrin nínú kẹ̀kẹ́-àyíká nka àwọn ìwé-mímọ́

Mo nifẹ Jésù Krístì. Mo lè kọ́ nípa ìgbé ayé àti ìfẹ́ Rẹ̀ nínú àwọn ìwé-mímọ́.

Kíkùn Ojú-ewé

Mo Nifẹ Jésù Krístì

Àwòrán
àwọn ọmọdé àti àwọn olùkọ́ nínú Alakọbẹrẹ

Tẹ̀ àwòrán náà láti ṣe ìgbàsílẹ̀.

Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

Báwo ni o ṣe le fi hàn pé o fẹ́ràn Jésù?