Làìhónà
Mo Jẹ́ Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì
Oṣù Kínní 2024


“Mo Jẹ́ Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kínní 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Ọ̀rọ̀, Oṣù Kínní 2024.

Mo Jẹ́ Ọmọlẹ́hìn ti Jésú Krístì

Ẹ lè tẹ̀lé Olùgbàlà kí ẹ sì tan ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ká sí àwọn ẹlòmíràn.

Àwòrán
Lógò Àkórí àwọn Ọ̀dọ́ Fún 2024

Njẹ́ ó ti yà yín lẹ́nu rí ìdí, tí Jésù fi sọ fún àwọn kan lẹ́hìn tí Ó bá ti wò wọ́n sàn, kí wọ́n máṣe sọ fún ẹnikẹ́ni (wo Mark 7:36)? Èrèdí kan lè ní ṣe pẹ̀lú irú àwọn ọmọẹ̀hìn tí Òun nílò. Ẹ lè ronú pé bí àwọn ènìyàn bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwòsàn wọn yíò jẹ́ ọ̀ná dáradára fún Jésù láti ní àwọn ọmọẹ̀hìn. Ṣùgbọ́n, Jésù kò nílò àwọn ọmọẹ̀hìn lásán. Ó nílò àwọn ọmọlẹ́hìn.

Jésù wí fún Peter àti Andrew pé, “Ẹ tẹ̀lé mi” (Matteu 4:19). Ìyírọ̀padà-èdè ti Joseph Smith nípa ẹsẹ náà kà pé, “Èmi ni ẹni náà tí àwọn wòlíì ti kọ nípa rẹ̀; ẹ tẹ̀lé mi” (Ìyírọ̀padà-èdè Joseph Smith, Matteu 4:18 [ní Matteu 4:19, footnote a]). Ìfipè náà kìí ṣe láti jáde pẹ̀lú Rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó fẹ́ kí wọ́n di ọmọlẹ́hìn Òun títíláé.

Òun kò kàn fẹ́ kí wọ́n wò ó tí Òun nkọ́ àwọn ènìyàn, nifẹ àwọn ènìyàn, àti ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fẹ́ kí wọ́n ṣe ohun kannáà. Ó fẹ́ kí iṣẹ́ Rẹ ó di iṣẹ́ wọn. Yíyan Krístì túmọ̀ sí pé wọn yíò kọ́ láti sìn bí Òun ti sìn kí wọ́n sì ronú bí Òun ti ronú. Wọn yíò gbáradì fún gbígbé ìgbé ayé tí Òun gbé, àti pé Òun yíò sì kọ́ wọn yíò sì fún wọn ní ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò láti dà bíi Tirẹ̀ si.

Àwòrán
Jésù Krístì

Ọ̀rọ̀ náà Greek fún ọmọlẹ́hìn ni mathetes. Ó ní ìtúmọ̀ si ju ọmọẹ̀hìn tàbí akẹkọ. A máa nṣe ìyírọ̀padà rẹ̀ nígbàkugbà bí olùkọ́ṣẹ́. Ní ọjọ́ Krístì, àwọn ọmọlẹ́hìn nyàn olùkọ́ni gan ní ọ̀dọ̀ ẹnití wọ́n fẹ́ láti kọ́ṣẹ́ pẹ̀lú ojú kan síwájú dída àwọn olùkọ́ni fúnra wọn. Krístì kò tẹ̀lé ìṣẹ́ yí gan an. Ó yíi padà ó sì wá àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ dípò bẹ́ẹ̀. Ní òní, Krístì npè wá láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó npè wá láti jẹ́ àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀ kí a sì kéde ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn Rẹ̀ kí wọ́n lè ní ìyè ayérayé (wo 3 Néfì 5:13).

Ọ̀dọ́mọbìrin kan láti Haiti ní Caribbean fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn Krístì nípa pípe ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí kìí ṣe ọmọ Ìjọ láti wá pẹ̀lú rẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ FSY kan. Ní àkọ̀kọ́ baba ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò fẹ́ láti fún ọmọbìnrin rẹ̀ ní àyè láti lọ. Àwọn olórí Ìjọ ṣe àlàyé nípa àwọn ìrírí dídára tí ó ndúró fun àti àwọn olùdámọ̀ràn ọ̀dọ́ àgbà oníyanu tí wọn yíò máa ṣe ìṣọ́ lórí rẹ̀. Baba náà fi àyè fún ọmọbìnrin rẹ̀ láti lọ, àti pé lẹ́hìn rírí ìyàtọ̀ tí ó ṣe nínú ayé rẹ̀, bákannáà ó fun ní àyè láti lọ sí àwọn ìpàdé Ìjọ àti pé—oṣù mẹ́fà lẹ́hìnnáà—ó ṣe ìrìbọmi.

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti Argentina ní Gúsù Amẹ́ríkà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn Krístì kan nípa pípín díẹ̀ lára kándì rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan bí wọ́n ti wà nínú ọkọ̀ èrò lọ sí ilé-ìwé. Nígbàtí ó wá síbi èròjà kọ́fì kan, ó ṣe àlàyé pé òun kò ní ìtọ́wò fún èròjà náà nígbàtí ó jẹ́ pé kò sí ẹnìkankan nínú ẹbí rẹ̀ tí ó nmu kọ́fì. Èyí darí sí ìbárasọ̀rọ̀ kan nípa Ìjọ, èyítí ó darí sí ìfipè láti wá sí àwọn ìpàdé, èyí tí ó darí sí dídarapọ̀ mọ́ Ìjọ Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó sì sìn níbi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní Chile.

Kìí ṣe gbogbo àwọn tí ẹ bá bá sọ̀rọ̀ nípa Ìjọ tàbí pè sí ìṣe Ìjọ ni yíò fẹ láti darapọ̀. Èyí Dára. Kìí ṣe gbogbo àwọn tí Krístì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti-ayé Rẹ̀ ni ó darapọ̀ bẹ́ẹ̀ náà. Síbẹ̀, bí a ti yàn láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì tí a sì nkéde ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Òun yíò fún wa ní ìgboyà àti ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá. A ó kọ́ bí a ó ti dà bíi Tirẹ̀ si, àti pé ìyẹn ni ohun tí àwọn ọmọlẹ́hìn nṣe.