Làìhónà
Ìmọ́lẹ̀ Wa nínú Aginjù
Oṣù Kínní 2024


“Ìmọ́lẹ̀ Wa nínú Aginjù,” Làìhónà, Oṣù Kínní 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kínní 2024

Ìmọ́lẹ̀ Wa nínú Aginjù

Àwọn wọnnì tí wọ́n fi òdodo ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tí wọ́n gbé àwọn ìlànà rẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà nípa òtítọ́ rẹ̀ yíò ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́ kí wọn sì ní àlékún ìgbàgbọ́ wọn nínu, àti ẹ̀rí ti, Olùgbàlà pọ̀.

Àwòrán
Arákùnrin Jared pẹ̀lú àwọn òkúta dídán

Àwòrán arákùnrin Jared pẹ̀lú àwọn òkúta dídán láti ọwọ́ Normandy Poulter

Àní bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, mo ní ẹ̀rí kan nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Nípàtàkì mo ní ìmọ́ sísúnmọ́ ìtàn arákùnrin Jared àti àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú ìrìnàjò wọn lọ sí “ilẹ̀ ìlérí” (Ẹ́térì 2:9).

Nígbàtí wọ́n dojúkọ ìfojúsọ́nà rírin ìrìnàjò nínú àwọn báàjì àìtanná sí, arákùnrin Jared bèèrè, “Kíyèsi, A Olúwa, njẹ́ ìwọ o ha jẹ́ kí àwa ó laagbami nlá yí kọjá nínú òkùnkùn bi?” Ní dídáhùn, Olúwa sì wípé, “Kíni ìwọ fẹ kí emí ó ṣe kí ìwọ́ o lè ní imọlẹ nínú àwọn ọkọ̀ rẹ?” (Ẹ́térì 2:22, 23).

Arákùnrin Jared mọ̀ pé Olúwa ní gbogbo agbára. Ó mọ̀ pé Olúwa ni orísun gbogbo ìmọ́lẹ̀. Ó mọ́ pé Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti pè É ní ìgbà àìní. Nítorínáà, ní lílo ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, arákùnrin Jared múra àwọn òkútà kékèké mẹ́rìndínlógún sílẹ̀. Ẹ rántí pé ó bèèrè lọ́wọ́ Olúwa nígbànáà láti fọwọ́kan àwọn òkúta náà pẹ̀lú àwọn ìka Rẹ̀, “kí wọn ó lè má tan ìmọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn” (Ẹ́térì 3:4).

Àwòrán Olúwa tí ó nfọwọ́kan àwọn òkúta náà ni a ti ha sí inú mi láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ ka ìtàn náà. Mo lè rí ìran náà bí ẹnipé ó nṣẹlẹ̀ ní ojú mi. Bóyá ìyẹn jẹ́ nítorí pé àwórán òkùnkùn tí ó nparẹ́ nípa ìmọ́lẹ̀ jẹ́ òdodo sí mi.

Nígbàtí tí èmi kò bá ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́, nígbàtí mo bá wà ní àìsí nínú Ẹ̀mí pẹ̀lú Olúwa, mò nní ìmọ̀lára òkùnkùn. Ṣùgbọ́n nígbàtí mo bá ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ìmọ́lẹ̀ a padà. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti jẹ́ bí òkútà títan ìmọ́lẹ̀ tí a fi ọwọ́kan nípasẹ̀ Olúwa Ó ti tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìrìnàjò mi nínú ayé.

Ìmọ́lẹ̀ Kan Titíláé

Bíiti àwọn wọnnì tí a mú wá nípasẹ̀ ọwọ́ Olúwa wá sí Amẹ́ríkà àtijọ́, gbogbo wa ó dojúkọ ìjì àti àwọn ọjọ́ dúdú nínú ìrìnàjò wa sí ilẹ̀ ìlérí ti ìgbéga. Ṣùgbọ́n Olúwa yíò ṣe ohun tí Ó ṣe fún àwọn ara Jared àti Néfì fún wa. Óun ó tọ́wasọ́nà yíò sì tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa—bí a bá gbọ́ràn sí I, tí a sì bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀.

Olúwa wí fún Néfì pé, “Èmi yíò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ yín ní aginjù pẹ̀lú; èmi yíò sì pèsè ọ̀nà níwájú yín, bí ó bá ṣe pé ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́; nítorí-èyi, níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó tọ́ yín síhà ilẹ̀ ìlérí; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé nípasẹ̀ mi ni a fi tọ́ yín” (1 Néfì 17:13).

Olúwa wí fún arákùnrin Jákọ́bù pé, “Èmi yíò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí wọn títíláé, tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi” (2 Néfì 10:14).

Nípa Olùgbàlà, wòlíì Ábínádì jẹri pé, “Òun ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé; bẹ́ẹ̀ni, ìmọ́lẹ̀ tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí a kò lè sọ di òkùnkùn” (Mosiah 16:9).

Nípa Ararẹ̀, Olùgbàlà jẹri pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé.” Ó fikun pé, “Ẹ kíyèsĩ èmi ni ìmọ́lẹ̀; èmi ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún yín” (3 Néfì 9:18; 18:16).

Àwòrán
Ààrẹ Russell M. Nelson nrìn

Níní Ìmọ̀lára Ìmọ́lẹ̀ náà

Mo fẹ́ràn wólíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson Mó di alábùkún fún nípa sísìn ní ẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbàtí ó bá wọnú yàrá kan, yàrá náà ó mọ́lẹ̀ sí lọ́gán. Ó ngbé Ìmọ́lẹ̀ Krístì pẹ̀lú rẹ̀.

Ìmọ́lẹ̀ Krístì jẹ́ òdodo. Ó “jẹ́ okun, agbára, tàbí ipa tí ó njáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Krístì Ó sì nfi ìyè àti ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo.” Ó jẹ́ ìṣìkẹ́ ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí tí ó lè darí àwọn ọmọ Ọlọ́run sí Ẹ̀mí Mímọ́ àti ìhìnrere Jésù Krístì.1 Kíka Ìwé ti Mọ́mọ́nì nfún Ìmọ́lẹ̀ náà lókun.

Nígbàmíràn a nílò láti wo ẹ̀hìn lórí ìgbé ayé wa láti rántí bí a ti gba ìrànlọ́wọ́ lórí ìrìnàjò wa. Bí a bá wo ẹ̀hìn, a ó lè ní ìmọ̀lára ipa Olùgbàlà lẹ́ẹ̀kansi. Nígbàtí àwọn ìwé-mímọ́ wípé, “Rántí, rántí” (Helaman 5:12), mo ró pé wọ́n nwí fún wa pé, “Ẹ máṣe rántí ohun tí ẹ ti mọ̀ tàbí ní ìmọ̀lára tẹ́lẹ̀ lásán, ṣùgbọ́n, ní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kansi.”

Fún àwọn kan, níní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ ti-ẹ̀mí lè wá ní ìrọ̀rùn. Fún àwọn míràn, ìmọ́lẹ̀ ti-ẹ̀mí lè jẹ́ ìṣòrò láti ní ìmọ̀lára rẹ̀ nítorí ti àwọn ìlàkàkà araẹni tàbí àwọn ìdíwọ́ ti-ayé. Ṣùgbọ́n bí a bá jẹ́ olotitọ, ìmọ́lẹ̀ yíò wa—ní àwọn ìgbà ní àwọn ọ̀nà tí a kò retí.

Ààrẹ Nelson, ẹni tí ó ti gbà wá lámọ̀ràn láti “fi àdúrà ṣe àṣàrò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lojojúmọ́,”2 ti pín onírurú àwọn ọ̀nà tí Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi lè mú wa súnmọ́ Olùgbàlà si kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere, di àwọn òtítọ́ ìhìnrere mú, kí a sì gbé ìgbé ayé àwọn ìkọ́ni ìhìnrere.

Bí a ti nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Ààrẹ Nelsòn wípé, òye wa nípa, àti ìmoore fún, Ètùtù Jésù Krístì yíò gbèrú si.

A ó ní ìfẹ́ láti di “àtúnbí” (Mosiah 27:25) bí ìwé náà ti nràn wá lọ́wọ́ láti ní ìrírí ìyípadà ọkàn (wo Mosiah 5:2).

Bí a ti nkà á tí a ṣi nṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa ìkórajọ Ísráẹ́lì, a ó ní ìmọ̀lára àlékún ìfẹ́ láti wá àwọn òkú wa kí a sì ṣe àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga fún wọn nínú tẹ́mpìlì.

A ó ní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ bí a ti ngba àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè wa, ìtọ́sọ́nà ní ṣíṣe ìpinnu, àti okun láti ronúpìwàdà kí a sì kojú ibi.

Bí a sì ti nka àwọn òtítọ́ tí a rí nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a ó ní ìmọ̀lára ìwòsàn, ìtùnú, ìmúpadàbọ̀sípò, ìtura, agbára, títunú, àti ìyárí sí ọkàn wa.3

“A báyĩ, njẹ́ èyí kò ha jẹ́ òdodo?” Álmà bèèrè nípa wíwúsókè, rírújáde èso òtítọ́, ìmọ̀, àti ẹ̀rí. Èmi wí fún nyín, Bẹ̃ni, nítorípé ìmọ́lẹ̀ ni íṣe; ohunkóhun tĩ bá sĩ ṣe ìmọ́lẹ̀, ó jẹ́ èyítí ó dára, nítorípé a mọ́ ìyàtọ̀ rẹ̀ lãrín àwọn yõkù, nítorínã ẹ̀yin níláti mọ̀ pé ó dára” (Álmà 32:35).

Àwòrán
àwòrán ti Jésù Krístì

Àwòrán Krístì, nípasẹ̀ Heinrich Hofmann

Wá Olùgbàlà nínú Òkùnkùn

Nígbàtí ọ̀rẹ́ mi Kamryn jẹ́ ọmọ ọdún mẹwa, ó ní arùn ojú tó ṣọ̀wọ́n tó wà títí tí o pa kóníà ojú ọ̀tún rẹ̀ lára.4 Ní ìgbà míràn, nígbàtí ìrora tó ba wá bá di àìlè múmọ́ra lemọ́lemọ́, Kamryn kò lè farada ìmọ́lẹ̀ kankan. Àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n ndàmú pé ó lè fọ́ lójú, ó mú àwọn fèrèsé yàrá ibùsùn rẹ̀ dúdú láti gbìyànjú láti mu ní ìtura. Ìyá Kamryn, Janna, rántí:

“Ní bíi oṣù mẹ́rin lẹ́hìn àyẹ̀wò rẹ̀, mo wọ yàrá rẹ̀ dúdú lọ. Bí ojú mi ṣe yípo, mo lè rí Kamryn kápọ̀ nínú ipò inú-oyún lórí ibùsùn rẹ̀. Ó wà nínú ìrora púpọ̀ gan tí kò fi lè yíra tàbí kí ó ké nígbàtí ó gbọ́ tí mo wọlé. Ó kan sùn síbẹ̀ pẹ̀lú ojú méjèèjì tó wú ní pípadé.

“Mo kúnlẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ bùsùn rẹ̀, mú ọwọ́ rẹ̀ sínú tèmi, mo ra á pọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta—àmì àṣírí wa fún ‘Mo ní ìfẹ́ rẹ.’ Bí ìṣe òun ó ra á pọ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́rin fún ‘Mo ní ìfẹ́ rẹ jùlọ,’ ṣùgbọ́n kò dáhùn. Ó wà nínú ìrora púpọ̀ jù. Pẹ̀lú omijé tí ó nṣàn sílẹ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi, mo wo akọni ìgbàkan ọmọ ọdún mẹwa mi tí ó ṣúnjọ ní àyíká kan. Ọkàn mí rì.”

Janna sọ àdúrà, àtinúwá jẹ́jẹ́ kan.

“Mo wí fún Baba Ọ̀run pé mo mọ̀ pé Òun mọ ohun tó dárajùlọ, ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, ‘Jọ̀wọ́ ràn án lọ́wọ́.’ Bí mo ti joko síbẹ̀ tí mò ngbàdúrà, ìjì ìyárí wọ ara mi. Mo ní ìmọ̀lára rírọlẹ̀ bí ẹnipé èrò nípa Olùgbàlà Jésù Krístì wá sí inú mi: ‘Òun ni ìmọ́lẹ̀ náà. Wá A nínú òkùnkùn.’”

Janna gbé orí rẹ̀ sókè ó sì sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí etí Kamryn: “Ó níláti wá Olùgbàlà nínú òkùnkùn.”

Lẹ́hìnwá, Kamryn sùn lọ nífetísílẹ̀ sí àwọn orin àti ìwé-mímọ́ lórí áàpù yàra-ìkàwé Ìjọ.

Àwòrán
Ọmọdébìnrin nwọ àlẹ̀mọ́ ojú

Nígbàtí àkóràn ojú rẹ bá lọ sókè, Kamryn nwá Olùgbàlà nínú òkùnkùn.

Àwòrán láti ọwọ́ ẹbí Kamryn

Àìsàn Kamryn wà láìnira ní ìgbà púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbàtí ó bá njìyà lílọ sókè, Janna àti ọkọ rẹ̀, Darrin, ó tùú nínú wọn ó sì fi àwọn ìbora bo àwọn fèrèsé yàrá ibùsùn rẹ̀. Ní àwọn ìgbà ìrora wọnnì, Kamryn wípé, “Èmi kan nwá Olùgbàlà nínú òkùnkùn ni.”5

Nígbàtí ayé bá dàbí “aginjù ṣíṣókùnkùn tí ó sì binújẹ́ àti” (1 Néfì 8:4), a lè nílò láti wá Olùgbàlà nínú òkùnkùn pẹ̀lú. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì, pẹ̀lú ẹ̀rí rẹ̀ “pé Jésù ni Krístì, Ọlọ́run Ayérayé,”6 yíò darí wa lọ sọ́dọ̀ Rẹ̀. Mo mọ̀ pé àwọn wọnnì tí wọ́n fi òdodo ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tí wọ́n gbé àwọn ìlànà rẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà nípa òtítọ́ rẹ̀ yíò ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́ wọ́n ó ṣẹ àlékún ìgbàgbọ́ wọn nínu, àti ẹ̀rí ti, Olùgbàlà.

Njẹ́ kí a fi ìmoore hàn fún ìwé “títọ́ jùlọ” nípa7 kíkà á, ṣíṣe ikẹ́ rẹ̀, kí a sì lò ó láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun àti ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn nínú Ìmọ́lẹ̀ Ayé.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo àwọn Àkọlé àti Ìbèèrè, “Ìmọ́lẹ̀ Krístì,” topics.ChurchofJesusChrist.org.

  2. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2017, 62.

  3. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?,” 62, 63.

  4. Kòkoro àkóràn àrùn ara.

  5. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Janna Cannon àti ọmọbìnrin rẹ̀ Kamryn fún pípín ìtàn wọn.

  6. àkọlé ojú-ewé Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

  7. Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààre Ìjọ: Joseph Smith (2007), 64.