Làìhónà
Igi ìyè
Oṣù Kínní 2024


“Igi Ìyè,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2024, 26–27.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kínní 2024

Igi Ìyè

Àwòrán
Yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley

Léhì jẹ́ wòlíì kan. Ọlọ́run wí fun láti kó ẹbí rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ ìlérí. Nígbàtí wọ́n rin ìrìn àjò, ó lá àlá nípa igi ẹlẹ́wà. Igi ìyè ni a pè é.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Igi náà dàgbà nínú àdùn èsò funfun. Léhì nímọ̀lára ìdùnnú nígbàtí ó jẹ ẹ́! Ó nfẹ́ kí ẹbí òun gbìyànjú rẹ̀ bákannáà.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Léhì rí ọ̀pá irin tí ó darí lọ si ìdí igi náà pẹ̀lú. Àwọn ènìyàn di ọ̀pá náà mu láti dé idí igi náà àti láti jẹ èso náà.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Ìgi náà nínú àlá Léhì dàbí ifẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀pá náà dàbí àwọn ìwé mímọ́. Nígbàtí a bá ka àwọn ìwé mímọ́, a nsúnmọ́ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì si.

Kíkùn Ojú-ewé

Àwọn Ìwé Mímọ́ Kọ́ni nípa Jésù

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà níhin

Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford

Kíni ìtàn tí ẹ fẹ́ràn-jùlọ nípa Jésù Krístì?