2022
Yàn
Oṣù Kẹfà 2022


“Yàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́,Oṣù Kẹfà 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹfà 2022.

Yàn

Jóṣúà rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti yàn èyí tó tọ́, láti máa tẹ̀ lé Olúwa.

yàn

Agbára wa láti yàn àti ṣíṣe fún ara wa ni à npè ní yíyàn. Ó jẹ́ ipa pàtàkì kan ti ètò Bàbá Ọ̀run. Ète kan nínú ìgbésí ayé yìí ni láti fi hàn pé a máa yàn láti ṣègbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run kí a lè túbọ̀ dàbí Rẹ̀. A ó dá wa lẹ́jọ́ nípasẹ̀ ìwé ìyè wa. (Wo 3 Néfì 2:27; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101:78; Ábráhámù 3:25.)

èyí pẹ̀lú:

Jóṣhúà rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti yan “lọjọ́ òní,” tàbí nísisìyí. A lè ṣe àwọn yíyàn pàtàkì ní èèkàn àti lẹ́hìinnà gbìyànjú láti dúró ní ìfaramọ́ sí wọn. (Wo Orin Dáfídì 37:5.)

sìn

Nínú ẹsẹ yìí, láti sìn túmọ̀ sí láti jọ́sìn, ṣèrànwọ́, gbọràn, àti láti fi ara rẹ fún ẹnìkan. Ó yẹ kí a sin Olúwa Moses 1:15).

Àwọn òrìṣà

A ti pàṣẹ fún Ísráẹ́lì láti sin Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè nìkan, Jésù Krístì (wo Exodus 20:2–5). Jóshúà fún wa ní àpẹrẹ ti àwọn ọlọrun miran ti àwọn ènìyàn rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ sìn. Àwọn ọlọ́run miiràn nínú ìgbésí ayé wa lè pẹ̀lú àwọn ohun-ìní, àwọn èrò ti àwọn ẹlòmíràn, àwọn ire míràn—ohunkóhun tí ó mú wa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.

èmi àti ilé mi

Jóṣhúà sọ fún ara rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀. Ó ní àwon yíò sin Olúwa. Ó fẹ́ darí ìdílé rẹ̀ lọ́nà òdodo kó sì kọ́ wọn láti tẹ̀ lé Olúwa (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:40).