Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 106


Ìpín 106

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 25 Oṣù Kọkànlá 1834. Ìfihàn yìí ni a dojú rẹ̀ kọ Warren A. Cowdery, ẹ̀gbọ́n àgbà kan ti Oliver Cowdery.

1–3, Warren A. Cowdery ni a pè bíi olórí òṣìṣẹ́ kan ní agbègbè rẹ̀; 4–5, Bíbọ̀ Ẹ̀kejì kì yíò bá àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ bíi olè; 6–8, Àwọn ìbùkún nlá ntẹ̀lé iṣẹ́ ìsìn tòótọ́ nínú Ìjọ.

1 Ó jẹ́ ìfẹ́ inú mi pé kí ìránṣẹ́ mi Warren A. Cowdery jẹ́ yíyàn kí á sì ṣe ìlànà fún un bíi olórí àlùfáà gíga ní orí ìjọ mi, ní ilẹ̀ Freedom àti ní àwọn agbègbè yíkáàkiri.

2 Kí òun sì kéde ìhìnrere àìlópin mi, kí ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè àti kí ó ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kìí ṣe ní ààyè tirẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fi ara tìí.

3 Kí ó sì ya gbogbo àkókò rẹ̀ sọ́tọ̀ sí ìpè gíga àti mímọ́ yìí, èyítí mo fi fún un nísisìyí, ní wíwá ìjọba ọ̀run àti òdodo rẹ̀ pẹ̀lú aápọn, àti pé ohun gbogbo tí ó nílò ni a ó fi kún; nítorí alágbàṣe yẹ fún owó iṣẹ́ rẹ̀.

4 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bíbọ̀ Olúwa súnmọ́ itòsí, yíò sì bá ayé bí olè lóru—

5 Nítorínáà, ẹ di àmùrè yín, kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀, ọjọ́ náà kì yíò sì bá yín bí olè.

6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ayọ̀ wà ní ọ̀run nígbàtí ìránṣẹ́ mi Warren tẹríba fún ọ̀pá aládé mi, tí ó sì ya ara rẹ̀ kúrò nínú àwọn àrékérekè àwọn ènìyàn;

7 Nítorínáà, ìbùkún ni fún ìránṣẹ́ mi Warren, nítorí èmi yíò ṣàánú fún un; àti, láìka asán ti ọkàn rẹ̀ sí, èmi yíò gbé é sókè níwọ̀nbí òun bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi.

8 Èmi yíò fún un ní ore ọ̀fẹ́ àti ìdánilójú nípa èyìtí òun yíó lè dúró; àti bí òun bá sì tẹ̀síwájú láti jẹ́ olõtọ́ ẹlérìí àti ìmọ́lẹ̀ kan sí ìjọ, èmi ti pèsè adé kan fún un nínú àwọn ilé ti Bàbá mi. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.